9th Assembly: Àwọn ohùn tó yẹ kí ẹ mọ nípa Femi Gbajabiamila tó di Olórí Ilé Asojú-sòfin Nàìjíríà tuntun

Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, @femigbaja

Ọjọ ti pẹ ti Femi Gbajabiamila ti n wa ipo olori ile aṣoju-ṣofin orileede Naijiria, ala naa si ti wa di ohun bayi.

Fun awọn ti wọn ba n gbọ orukọ rẹ fun igba akọkọ nigba ti wọn kede rẹ pe o fidi akẹgbẹ rẹ, Umar Bago janlẹ, anfaani ree lati mọ nipa ẹni ti Fẹmi Gbajabiamila jẹ.

Ki a kọkọ bẹrẹ pe oun ni o gba ipo olori ile aṣoju-ṣofin lọwọ Yakubu Dogara gẹgẹ bi olori ile kẹẹdogun lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kii ṣe akọkọ ree ti Gbajabiamila yoo du ipo olori ile

Lọdun 2015,Femi Gbajabiamila koju Yakubu Dogara fun ipo olori ile amọ Dogara lo jawe olubori.

Saaju ki o to di aṣoju nile aṣofin, Femi Gbajabiamila ti a bi ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 1962, bẹrẹ iṣẹ agbẹjọro lọdun 1984 lẹyin to gboye nile Ẹkọ imọ ofin Naijiria.

aworan Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Femi Gbajabiamila/Facebook

Àkọlé àwòrán, Femi Gbajabiamila

Laarin igba naa titi di ọdun 2003 ti o kọkọ di aṣoju fun ẹkun Surulere nilu Eko nile aṣoju-ṣofin Naijiria, Femi Gbajabiamila da ile iṣẹ agbẹjọro tirẹ silẹ, ti o si tun bẹrẹ si ni kopa diẹ diẹ ninu oṣelu.

Labẹ asia ẹgbẹ Alliance for Democracy, AD, lo ti bẹrẹ irinajo oṣelu rẹ, ti o si sun lọ si ACN ki o to pada kangun sinu ẹgbẹ oselu APC, nibi to ti wa jẹ olori ile lọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kọkanla oṣu Kẹfa ọdun 2019.

Ki lawọn ipa to ti ko lagbo oṣelu?

Laarin awọn akẹgbẹ rẹ nile aṣofin, ọpọ lo ma n fi oju ọlọgbọn wo Gbajabiamila, ti wọn a si ma bọwọ fun, nipa bo ti ṣe ma n se agbekalẹ ọrọ rẹ.

Aworan Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, FemiGbajabiamila/FACEBOOK

Àkọlé àwòrán, Femi Gbajabiamila ati Ahmad Lawan aarẹ ile aṣofin Naijiria ti wọn ṣẹṣẹ yan

Femi Gbajabiamila ni aṣofin to da ọrọ ofin pajawiri kan silẹ, eyi to faye gba ki igbakeji aarẹ laṣẹ lati dari ijọba, nigba ti aarẹ ko ba lagbara lati dari ijọba.

Abadofin yii ni wọn gbe kalẹ labẹ ilana ''Doctrine of Necessity''

Femi Gabjabiamila ni wọn yan gẹgẹ bi olori ọmọ ẹgbẹ to pọju lọ, ni ile aṣofin kẹjọ ni Naijiria.

Amọ ṣa...

Toun ti bi Gbajabiamila ti ṣe jẹ ilumọka oloṣelu, o ni awọn iṣẹlẹ kan to ṣe bi ẹni tapo saṣọ ala rẹ.

Akọkọ ni iroyin ti awọn alatako rẹ n gbe ka pe, o lọwọ ninu aṣemase kan nigba ti o n ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹjọro nilẹ Amẹrika.

Ninu esi ọrọ yi, Gbajabiamila ni oun ṣẹ labẹ ofin awọn to n ṣe akoso eto amofin ni, ti oun si ti gba ijiya to tọ.

aworan iwe idahun ẹsun Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Femi Gbajabiamila/Facebook

Ọrọ yii to tun jẹyọ lasiko to n du ipo olori ile, eleyi ti awọn alatako rẹ fi n sọ pe ko tọ ni ẹni to n di ipo olori ile asofin mu.

Isẹlẹ miran ni i ṣe pẹlu bo ti ṣe na owo ribiribi lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi iyawo rẹ.

aworan Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, ebalstv/facebook

Àkọlé àwòrán, Owo ribiribi ti Gbajabiamila fi ra ọkọ ayọkẹlẹ ati aṣọ lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi iyawo rẹ bi awọn eeyan ninu

Ọrọ yii bi awọn eeyan ninu, ti Gbajabiamila si pada tọrọ aforijin pe oun ko ko iyan awọn ara ilu kere pẹlu rira ẹbun olowo iyebiye fun iyawo oun.

Awọn ohun to yan laayo

Eto ẹkọ ati ọrọ awọn oṣisẹ wa lara awọn ohun ti Gbajabiamila gbajumọ, to si ma n sọrọ nipa mimu idẹrun ba ara ilu.

Gbajabiamila tun nifẹ si mimu idagbasoke ba ere idaraya ni Naijiria.