Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ adigunjalè, afipábánilòpọ̀ 15 l'Ondo

ole

Oríṣun àwòrán, others

Ọmọ ọdún méje ni mo ti ń digunjalè, ogun ìdílé ló fàá, afurasí ṣàlàyé l'Ondo

Ọwọ olopaa nipinlẹ Ondo ti tẹ awọn afurasi ọdaran marundinlogun lori ẹsun idigunjale, fifipa ja alipupu ọkada gba, ati ifipabanilopọ.

Gbenga Kikowo to jẹ ọkan lara awọn afurasi ti wọn mu naa ṣalaye pe lati ọmọ ọdun e loun ti bẹrẹ iwa idigunjale .

Gbenga tun ṣalaye pe ilu Igbaraoke ni oun ti bẹrẹ, bẹẹni ọpọlọpọ igba liun ti lọsi ẹwọn tori rẹ.

O fi kun un pe awọn agbara okunkun idile oun lo faa nitori kii wu oun ki oun jale.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Ọgbẹni Bọlaji Salami ṣalaye pe kaakiri ipinlẹ naa ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi naa.

Kọmiṣọnna ọlọpaa Salami ni agbegbe Oke aro ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ Gbenga Kikowo ati akẹgbẹ rẹ ninu iwa aitọ naa.

Ole

Oríṣun àwòrán, others