Baba Ijesha: Kò sí aṣẹ́wó lára àwọn òṣèré tíátà Yoruba, mi ò sì faramọ́ ìfipábánilòpọ̀ - Olofa Ina

Olofa Ina interview
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Agbaọjẹ oṣere tiata Yoruba, Deji Aderemi, ti ọpọ mọ si Olofa Ina ti tọrọ aforiji lọwọ awọn oṣere tiata obinrin fun ọrọ to sọ lasiko igbẹjọ Baba Ijesha nile ẹjọ giga ipinlẹ Eko.

O ni ki awọn obinrin naa darijin oun lori ọrọ ti oun sọ pe pupọ ninu wọn ni wọn maa n ba ni ibalopọ lagbo oṣere.

Olofa Ina lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Àkọlé fídíò, Loni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni wọn o tun gbe oṣerekunrin, Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha, lọ si ile ẹjọ.

Ṣaaju ni Olofa Ina ti kọkọ sọ pe ko jẹ tuntun pe ibalopọ n waye laarin awọn oṣere tiata ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba lasiko igbẹjọ naa laarin ọsẹ.

Lasiko ti akọroyin BBC bi Olofa Ina leere ohun to gbe wa sile ẹjọ naa, o ni ṣe ni awọn eeyan kan mọọmọ dẹ pakute fun Baba Ijesha lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan.

Lẹyin naa lo ni oun wa sile ẹjọ lati wa woye ibi ti ẹjọ naa yoo fi si, to si sọ pe ọrọ ibalopọ yii "Ko jẹ itumọ si awa... nitori gbogbo nnkan bayẹn lo n so wa pọ pẹlu awọn obinrin."

O ni "Ko si obinrin to ṣe pataki lode oni ninu iṣẹ tiata ti yoo sọ pe wọn ko ba oun lopọ ri ninu ẹgbẹ" niroti naa ko jẹ tuntun.

Ṣugbọn ọrọ naa ko dun mọ ọpọ awọn eeyan ninu, paapaa awọn obinrin to jẹ oṣere, eyii to mu ki wọn bẹrẹ si n bu ẹnu ẹtẹ lu lori ayelujara.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Wayi o, Olofa Ina ti wa tọrọ aforiji, to si tun sọ pe oun ko ṣegbe lẹyin ki wọn maa fi ipa fi ba obinrin tabi ọmọde lopọ.

Àkọlé fídíò, Ijaw Paternity test: Mọ́ síi nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ilaje nípa ọmọ ọkọ àti ọmọ àlè

O ni ọrọ ti oun sọ jabọ pẹlu itara, ati pe ohun ti oun gbiyanju lati sọ kọ ni awọn eeyan tumọ ọrọ naa si.

O fikun pe "Ẹmabinu ana, paapaa ẹyin obinrin ti ẹ jẹ iya wa nidi iṣẹ tiata."

Agba ọjẹ naa ṣo siwaju si pe kii ṣe aṣa awọn oni tiata ni lati maa fi ọwọ pa obinrin lara lọna aitọ nitori ẹṣẹ ni niwaju Ọlọrun.

Àkọlé fídíò, Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣisṣe- Bukola

O ni ko si aṣẹwo ninu awọn oni tiata, nitori naa ki wọn si fi ori jin oun lori ọrọ ti oun sọ ṣaaju fun awọn akọroyin nile ẹjọ naa.

Lẹyin naa lo ke si awọn to kundun obinrin, ti wọn si n fi ọwọ kan obinrin lọna aitọ lati jawọ ninu irufẹ iwa bẹẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Iyabo Ojo, mẹ́nu kúrò lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha ní báyìí tí ọ̀rọ̀ ti dé iwájú mi - Adájọ́ Toyin Taiwo

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Instagram

Adajọ ile ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹjọ lori ẹsun ifipabanilopọ ati iwa ipa ninu ile, Oluwatoyin Taiwo, ti kilọ fun Iyabo Ojo lati mẹnu kuro lori ọrọ Baba Ijesha.

Adajọ náà lo pàṣẹ ọhun lasiko to n gbọ ẹjọ lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan Baba Ijesha nile ẹjọ náà ni Ikeja, nílùú Eko.

O ni niwọn igba ti ẹjọ náà ti wà níwájú oun, oun ko fẹ kí ẹnikẹni máa sọrọ lórí rẹ mọ lórí ayelujara ki oun le r'oju ráàyè ṣiṣẹ oun gẹgẹ bíi adájọ.

Ọrọ naa jẹyọ lasiko ti agbẹjọro Princess Damilola, to fi ẹsun kan Baba Ijesha n fesi sí beeli ti adajọ náà fún Baba Ijesha ṣaaju.

Agbẹjọro Princess sọ pe ọpọ àwọn èèyàn lò ti bẹrẹ sí n dukoko mọ onibara oun lori ẹjọ náà, ati pe o ṣeéṣe kí ẹmi rẹ ti wa ninu ewu.

Ṣugbọn agbẹjọro Baba Ijesha fesi pe awọn alatilẹyin Princess ti ba orukọ onibara oun jẹ lori ayelujara nígbà ti adajọ kò tíì ṣe ìdájọ lori ọrọ ọhun.

O ni awọn eeyan bíi Princess fúnra rẹ àti Iyabo Ojo n gbe ìgbésẹ láti dá ojú ẹjọ náà rú bi wọn ṣe n sọ oríṣiríṣi ọrọ kobakungbe nipa Baba Ijesha loju opo Instagram wọn.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Eyii lo mú kí adajọ Oluwatoyin Taiwo pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tí wọn n fi ẹnu wọn wà rọọfu lori igbẹjọ náà lọ gbẹnu dakẹ, to fi mọ Princess, Iyabo Ojo, Yomi Fabiyi atawọn oṣere tiata Yorùbá mìíràn.

O ni "Mi o fẹ ki ẹnikẹni máa sọrọ lórí ẹjọ yìí mọ lori ayelujara."

"Ọrọ yòówù tí àwọn èèyàn ba n sọ lori ayelujara ko kan mi, ko si ni ṣàpèjúwe irufẹ ẹjọ ti n o da."

Adajọ Oluwatoyin Taiwo pari ọrọ rẹ pe awọn ẹri to wa níwájú oun ni yóò sọ ibi ti ọrọ naa yóò já sí, kii ṣe ọrọ ti awọn eeyan kan n sọ nigboro, ṣugbọn oun ko fẹ kí wọn sọrọ lórí ẹjọ náà mọ.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Wayi o, adajọ Oluwatoyin Taiwo ti fún Baba Ijesha ni beeli pẹlu mílíọ̀nù méjì naira ati oniduuro meji.

O sí ti sun igbẹjọ ọhun sí ọjọ kẹrindinlọgbọn, ọjọ kẹtadinlogbon ati ọjọ kejidinlọgbọn ọdun yìí.

Aworan Baba Ijesha

Ilé ẹjọ́ gba béèlì Baba Ijesha N2Miliọ̀nù ní wọ́n fún

Adajọ ti kede pe miliọnu meji Naira ni ki Baba Ijesha san gẹgẹ bi owo beeli.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Akọroyin BBC to n jabọ lati ile ẹjọ giga to wa ni Ikeja sọ pe awọn agbẹjọro ogun lo wa ṣoju Baba Ijesha lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Ṣaaju ni agbẹjọro rẹ ati ti ijọba ti ṣe atotonu wọn tan niwaju adajọ lori idi ti awọn fi f tabi tako ki ileẹjọ gba oniduro rẹ.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo si ti gbọ lati ẹnu wọn to wa si ni oun gbe iye owo yi kalẹ pẹlu pe o ni lati mu oniduro meji wa ti ọkan ninu wọn gbọdọ maa gbe nilu Eko.

Agbẹjọro agba SAN, Babatunde Ogala pẹlu Dada Awosika SAN ati awọn agbẹjọro mi ti apapọ wọn jẹ ogun lo wa duro fun Baba Ijesha.

Ninu ọrọ rẹ Baba Ijesha sọ fun adajọ pe oun ko jẹbi ẹsun onigun mẹfa ti wọn fi kan an.

Aworan Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Daily Trust

Ni bayi, agbẹjọro ijọba sọ pe awn kan n dunkoko mọ Princess amọ agbẹjọro baba Ijẹsha fesi pada pe Iyabo Ojo ati awọn miran ti ba orukọ Baba Ijesha jẹ lori ayelujara.

Adajọ ti sun igbẹjọ di ọjọ Kẹrindinlọgbọn, Mẹtadinlọgbọn ati Mejidinlọgbọn Oṣu Keje.

Ninu awọn to kọwọrin wa wo bi ẹjọ naa ṣe n lọ lati ri Yomi Fabiyi, Princess ati Baba Olofaina ti gbogbo wọn si jẹ oṣere tiata.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Daily Trust

Iyabo Ojo, eléyìí tẹ ṣe lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha tó, tó bá ṣẹ̀yín kí ẹ dáríjì - Ọlọfaina bú sẹ́kún

Gbajugbaja Oṣere ni Naijiria, Deji Aderemi ti ọpọ eniyan mọ si Ọlọfaina ti bẹ Iyabo Ojo ati awọn miran ti ọrọ kan pe ki wọn dariji Baba Ijesha lori ọrọ ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.

Olofaina sọ bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ileẹjọ ti igbẹjọ Baba Ijesha tio waye ni Ọjọbọ.

O ni iru eyi ko ṣẹlẹ ri ni agbo oṣere ki wọn ma a gbe ara wọn lọ si ileẹjọ.

Gbajugbaja oṣere naa fikun wi pe igbiyanju oun lati ba Iyabo Ojo sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo jasi pabo, to si sọ fun oun pe ki oun bọ silẹ nibẹ gẹgẹ bi esi to fun oun, ko to di wi pe o pa foonu mọ oun lẹnu.

Bakan naa ni lo fikun pe oun wa lati ilu Ede,nipinlẹ Osun wa si ileẹjọ lati le wo bi ọrọ naa ma jasi.

Ati wi pe ẹgbẹ ti ṣetan lati ba awọn ti ọrọ naa kan wi, amọ ki wọn parapọ jẹ ọkan.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

Mo nírètí pé Baba Ijẹsha yóò gba béèlì ní iléẹjọ́ tí yóò tí farahàn lónì - Yomi Fabiyi

Gbajugbaja oṣere tiata to n ja fun Baba Ijesha, Yomi Fabiyi ti ni oun ni ireti pe Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha yoo ri beeli rẹ gba loni ni ileẹjọ.

Yomi Fabiyi sọ eyi lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin Bbc Yoruba sọrọ lori afojusun rẹ nigba igbẹjọ ti yoo waye ni ileẹjọ to wa ni Ikeja, nipinlẹ Eko.

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Instagram

O ni oun gbagbọ wi pe ko ni si ojusaaju lasiko igbẹjọ naa loni, ti Baba Ijẹsha yoo si gba beeli to tọ si.

''A mọ ilu Eko fun ile ọgbọn, ilu ti wọn fẹran lati ma a fun eniyan ni ẹtọ wọn, ti wọn ki n sii fi ẹt eniyan dun wọn.''

''Beeli to jẹ ti Baba Ijẹsha, mo ni ireti pe yoo ri gba lagbara Ọlọrun''.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Bakan naa ni Yomi Fabiyi fikun pe oun gbagbọ wi pe awọn to lo ọmọbinrin ti ọrọ kan laitọ yoo gba idajọ ti wọn naa loni.

''Awọn ti wọn lo ọmọde naa gbọdọ kọ ẹkọ ki iru rẹ maṣe ṣẹlẹ mọ si awọn ọmọ wa mọ lorilẹede Naijiria''

Yomi Fabiyi ni gbagbaagba ni oun wa lẹyin Baba Ijẹsha, ti oun yoo si wa ni ileẹjọ pẹlu rẹ loni.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Baba Ijesha yóò tún farahàn nílé ẹjọ́ mìí lónìí lórí ẹ̀sùn fífi ipá bá ọmọdé lòpọ̀

Loni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni wọn o tun gbe oṣerekunrin, Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha, lọ si ile ẹjọ.

Aworan Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha/Twitter

Ẹsun fifi ipa ba ọmọdebinrin ni ibalopọ aitọ ni wọn fi kan Baba Ijesha, eyi ti yoo mu ko farahan niwaju ile ẹjọ to ngbọ awọn akanṣe ẹsun ni Ikeja.

Gbajugbaja apanilẹrin, Princess Comedian si lo gbe lọ si agọ ọlọpaa lẹyin to fi ẹsun kan an pe o ba ikan lara awọn ọmọ to n gbe pẹlu oun lopọ.

Lati ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ni Baba Ijesha ti wa ni ahamọ ọlọpaa.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa ni wọn kọkọ gbe e lọ sile ẹjọ Majisireeti to wa ni adugbo Yaba.

Awọn ẹsun ti wọn si ka si lẹsẹ ni pe o ṣe ọmọde bi ko ṣe tọ, o ba ọmọde ni ibalopọ, o ki nkan ọmọkunrin rẹ si oju ara ọmọdebinrin, ati ifipabanilopọ.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha