Oyo security: Àwọn agbébọn pa ìyàwò èèkàn olóṣèlú ní Ibadan, ọlọ́pàá ní adigunjalè ní wọ́n

Ọlayẹmi ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, @whatsupibadan

Awọn agbebọn kan ti ṣeku pa arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ọlayẹmi iyawo eekan oloṣelu kan nilu Ibadan, Ọgbẹni Peter Ọdẹtomi lọjọ Ẹti.

Ọgbẹni Ọdẹtomi ti figba kan ri ṣe kọmiṣọnna fun amojuto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ni ipinlẹ Ọyọ lasiko iṣejọba gomina ana nibẹ,

Oloogbe Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi to si tun ti figbakan ri jẹ alaga kansu gusu Ogbomọṣọ pẹlu.

Bakan naa ni o tun ti fi igbakanri jẹ oludije fun igbakeji gomina pẹlu Sẹnetọ Ajimọbi lasiko to fi kọkọ du ipo gomina ipinlẹ Ọyọ lọdun 2007.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Ninu ile rẹ to wa lagbegbe Akobọ nilu Ibadan ni wọn pa oloogbenaa si.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣugbọn wọn ni awọn adigunjale lo pa iyawo oloṣelu naa lasiko ti wọn fi lọ digun jale nile rẹ lọjọ Ẹti, ọjọ karundinlọgbọn.

Àkọlé fídíò, Ijaw Paternity test: Mọ́ síi nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ilaje nípa ọmọ ọkọ àti ọmọ àlè