NDLEA mú dókítà àti sọ́jà lórí ẹ̀sùn títà egbòogi olóró

NDLEA

Oríṣun àwòrán, others

Ọwọ ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria , NDLEA, ti tẹ dokita kan, Jane Chioma Ofoma, ti wọn fẹsun kan pe o n ta egboogi oloro lori ayeujara.

Wọn fẹsun kan oniṣegun oyinbo naa pe o n lo ṣọọbu rẹ lori ayelujara, Omachi's Kitchen, nibi to ti dibọn pe onjẹ ni oun n ta lati maa ta egboogi naa eyii to ti po mọ suiti ati bisikiti.

NDLEA tun fi ṣikun ofin mu ọkunrin kan to ti fi igba kan jẹ jagunjagun ri, Sgt Ibrahim Musa, lẹyin ti wọn ka nnkan bii kilo mẹtala igbo mọ lọwọ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi fi sọwọ si awọn akọroroyin, o ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa ni ipinlẹ Edo lẹyin iwadii awọn ọtẹlẹmuyẹ awọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọtẹlẹmuyẹ naa ya bo agbegbe ti awọn afurasi ọhun wa ni No 1 Winners Way, Auchi, nibi ti wọn ti ka nnkan bii ọgọrun bisikiti ti wọn fi egboogi igbo po mọ dokita naa lọwọ.

Àkọlé fídíò, Ijaw Paternity test: Mọ́ síi nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ilaje nípa ọmọ ọkọ àti ọmọ àlè

O ni "Chioma, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kẹkọọ jade nile ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Nsukka, o si lọ sin ni ile iwosan fasiti Benin."

Babafemi sọ pe afurasi ọhun ti jẹwọ fun awọn pe lootọ ni oun maa n po egboogi "skunk" mọ bisikiti ti oun n ta lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣisṣe- Bukola

O sọ siwaju si pe awọn mu jagunjagun tẹlẹri, Musa, ni Oke-Odo, iyẹn lagbegbe Tanke, niluu Ilorin lọjọ kẹtadinlogun, oṣu ti a wa yii.

Alukoro NDLEA naa ṣalaye pe "Sgt Musa ti fi igba kan ṣiṣẹ ni barake Abati to wa niluu Eko ri, ko to lọ ṣiṣẹ pẹlu 17 battalion niluu Chibok, nipinlẹ Bornu, lẹyin naa lo salọ kuro nidii iṣẹ Ologun lọ siluu Ilorin."

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

O ni Musa jẹwọ fun awọn pe asiko ti oun wa ni Chibok ni oun pade ẹni to n ko egboogi igbo "Arizona" fun oun lati maa ta."

Atẹjade naa tẹsiwaju pe NDLEA tun fi ṣikun ofin mu ọkunrinẹni ọgbọn ọdun kan, Emmanuel Ehiramhen, to n ta egboogi kokeni niluu Ekpoma, nipinlẹ Edo yii kan naa.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Nigba to n da si ọrọ naa, ọga agba ajọ NDLEA, ajagunfẹyinti Brig. Gen. Mohamed Buba Marwa sọ pe afojusun awọn ni lati ri daju pe awọn kasẹ gbogbo ohun to jọ mọ titi ati lilo egboogo oloro ni Naijiria.