Fidelis Nweze: Ìjọba ìpínlẹ̀ Ebonyi ní kó sí ootọ nínú ìròyìn pé Kọmísọ̀nàa jíndé

Oríṣun àwòrán, Francis Nwaze
Kọmisana ti awọn eeyan ipinlẹ Ebonyi n yọ pe o ji dide, ijọba ipinlẹ naa sọ pe ko ri bẹẹ.
Niṣe ni ero pọ pitimu ni ile Kọmisana Fidelis Nweze l'Ọjọbọ tawọn eeyan si n fi orin ọpẹ bẹnu pe o ti jinde.
Lọjọ Abamẹta ni ijọba kede pe o jade laye lẹyin ijamba ọkọ kan lọjọ Kọkandinlogun oṣu Kẹfa.
Ṣaaju iku rẹ, oun ni Kọmisana feto idagbasoke ilu.
Nigba ti akọroyin wa yoo fi de ile rẹ loni, niṣe lawọn eeyan n jo ti wọn si n yọ pe ko ku mọ.
Amọ Fidelis ti wọn gbe digbadigba lọ si ile iwosan Turkish Hospital ni Abuja lọjọ to kan agbako ijamba ọkọ ko si ni ile rẹ bayi.
Laarin oru Ọjọbọ lawọn eeyan gbọ pe o ti jinde ti wọn si fi ijo ati orin ọpẹ bẹnu.
Titi di baa ṣe n sọrọ yii ko sẹni to le sọ pe awọn rii laaye.

Ijọba ipinlẹ Ebonyi ti fesi si iṣẹlẹ yi lasiko ti BBC ba wọn sọrọ.
Agbẹnusọ Gomina David Umahi ṣapejuwe Kọmisana naa gẹgẹ bi ọkan lara awọn Kọmisana to kaju osunwọn ninu ijọba.
O ni awọn ti ṣaaju fi atẹjade kan sita lori iku rẹ koda awọn kede isinmi lẹnu iṣẹ lọjọ Kẹtalelogun oṣu yii lati fi ṣe ayẹsi rẹ.
''Nkan ibanujẹ ni iroyin to tẹ wa lọwọ pe a padanu onimọ ẹrọ wa Fidelis Nweze''
Lalẹ Ọjọru, Gomina David Umahi ṣabẹwo si mọlbi r lati ba wọn kẹdun iku rẹ

Oṣe ipinu lati ṣagbatẹru eto ẹkọ awọn ọmọ Kọmisana naa bẹrẹ lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de ile iwe Girama.













