Bí ó bá ṣè ẹbọ ló gbà, ẹ fín-in kí àlááfíà lè j'ọba ní Oyo- Makinde sọ f'áwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé

Aworan Gomina Seyi Makinde ati awọn ẹlẹsin abalaye

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/SEYI MAKINDE

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ati apapọ ẹgbẹ awọn ẹlẹsin abalaye nipinlẹ naa ti fohunṣọkan lati ṣe amulo agbara iṣẹmbaye lojuna ati fopin si iṣoro eto aabo.Igbesẹ naa jẹ ọkan lara awọn abajade apẹro lori eto aabo ati ibaraẹni gbe ninu alafia to waye l'Ọjọru ni ẹka ileeṣẹ iroyin, aṣa ati irinajo igbafẹ nilu Ibadan.

Kọmisana fun iroyin, aṣa ati irinajo igbafẹ Ọmọwe Wasiu Ọlatunbọsun lo ṣe agbekale ipade naa lorukọ ijọba ipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò, Oba Sunday Oyediran ṣàlàyé kíkún nípa ìṣẹ̀ṣe, ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn tí kò dí ará wọn lọ́wọ́

Olatunbosun fi ayọ ijọba han lori atilẹyin ti awọn ẹlẹsin abalaye n ṣe fun Gomina ipinlẹ Ọyọ lati igba ti o ti gun ori aleefa.

Ọlatunbọsun kede rẹ pe ijọba Ṣeyi Makinde ti gbe igbesẹ lati fun awọn ẹlẹsin abalaye ni ọjọ ti wọn a maa gba isinmi lẹnu iṣẹ gẹgẹ bi awọn ẹlẹsin to ku lati ṣe ọdun wọn.

O ni ilana ofin ati awọn igbesẹ kọọkan lo n ṣe idaduro fun ikede ọjọ naa.

Kọmisana naa kesi awọn ẹlẹsin abalaye naa lati sa gbogbo ipa wọn tofimọ ẹbọ riru ki alafia le jọba nipinlẹ Ọyọ.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe "a ni lati pada si ilana ti awọn babanla wa fi n yanju iṣoro eto aabo nigba iwasẹ, ki ipinlẹ Ọyọ le tuba ki o si tuṣẹ".

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Oluranlọwọ pataki fun Gomina Ṣeyi Makinde lori iṣakoso, Ẹniọwọ Idowu Ogedengbe to ba wọn pejupesẹ sibi ipade naa kesi awọn ẹlẹsin abalaye lati tẹsiwaju ninu ṣiṣe atilẹyin fun ijọba to n bẹ lode ki iṣẹ idagbasoke le tẹsiwaju.

Aare Isẹṣẹ ipinlẹ Ọyọ, Aare Omikunmi Egbelade, Alaga Aṣa Oriṣa ilẹ Naijiria, Oloye Oke Adejare ati Oba Ela ipinlẹ Ọyọ, Oba Ojebode Awoniran ke si ijọba lati gbe owo kalẹ fun awọn ẹlẹsin mẹta gboogi to n bẹ nipinlẹ Ọyọ fun akanṣe eto adura ati irubọ.

Aworan awọn ẹlẹsin abalaye

Oríṣun àwòrán, facebook/seyi makinde

Ẹwẹ, bakan naa ni ijọba ṣe ipade pẹlu awọn aṣoju eleegun lori ibara ẹni gbe ninu alaafia ti ijọba Gomina Ṣeyi Makinde n fọn rere rẹ.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib