Herbalist: Babaláwo rí ẹ̀wọ̀n he! lẹ́yìn tó ṣe ìwòsàn fún obìnrin pẹ̀lu tábà fífí, ló bá kú lójijì!

Oríṣun àwòrán, Nottinghamshire Police
Babalawo kan lati orilẹede Zimbabwe, Lyndon Nindi ti ri ẹwọn ọdun meji he lẹyin to ṣekupa obinrin to fẹ ṣe iwosan arun inu rirun fun.
Lyndon Nindi lo rin irinajo wa si Nothingham in Ọjọ Kẹrindinlogun, Oṣu Keji, ọdun to kọja lati ṣe iwosan fun arabinrin Jekecha to ni aisan inu rirun.
Ileẹjọ Nothingham Crown Court ni babalawo, ẹni ọdun mọkandinlaadọta naa lo ọna abalaye ti awọn eniyan ara ilẹ Zimbabwe n lo lati fi ṣe iwosan, amọ taba fifi lo mu ki obinrin naa fo sanlẹ ku.
- Adunni Olorisa, obìnrin òyìnbó tó di ìyàwó òrìṣà nílẹ̀ Yorùbá títí di ọjọ́ ogbó
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Osun ṣe bẹbẹ lórí ètò Akomọlede àti Aṣa lórí BBC
- Àtẹ̀jádé ìjọba apapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pantami fihàn pé wọ́n ń káànú ìgbésùnmọ̀nmí- PDP
- Mo fẹ́ ìyàwó méjì lọ́jọ́ kan ṣoṣo láti ṣe ju ohun tí bàbá mi gbé ṣe - Uloho Othuko
Adajọ Gregory Dickinson QC ni babalawo naa kọja aye rẹ nitori o ṣe ju agbara rẹ lọ lori iwosan aisan inu.
Nindi to wa lati agbegbe Newscastle lo jẹwọ wi pe oun jẹbi ẹsun ipaniyan nipa lilo ogun oloro nicotine.
Bawo ni o ṣe ṣẹlẹ ti babalawo fi taba to pa obinrin to ni aisan inu rirun
Ọdun meji gbako ni yoo lo ni ọgba ẹwọn fun ẹsun ipaniyan yii.
Ileẹjọ ni bo tilẹ jẹ pe lilo taba wọpọ ni orilẹ-ede Zimbabwe lati fi ṣe iwosan abẹle, babalawo naa fẹ fi taba ọun pe awọn baba-nla rẹ lati wa ṣe iwosan oun.
Arabinrin Jekecha lo ti lọ si ileewosan lati fun aisan inu rirun, amọ nigba ti inu ọhun to kọ bọọrọ ni iya rẹ pe babalawo lati wa ṣe iwosan fun un, ti wọn yoo si san iye owo ilẹ okeere to to, £150 pẹlu owo ọkọ rẹ.
Ileẹjọ ni ọjọ ti babalawo naa de si ile wọn, ti o si fi taba naa si imu arabinrin Jekecha, ẹnu rẹ ati ara rẹ, to si gbodi ni ara rẹ, to fi ku.

Bi o tilẹjẹpe awọn eleto ilera pajawiri gbiyanju lati doola ẹmi rẹ, amọ ẹpa ko boro mọ, ti o si gbabẹ lọ.
- Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?
- ‘Jí foonu ọkọ rẹ̀ wò, kóo fi ẹ̀wọ̀n jura’
- Àwọn agbébọn ti pa mẹ́ta nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Greenfield tí wọ́n jí gbé ní Kaduna
- Olólùfẹ́ Naira Marley kọ sẹ́nu tírélà nítorí ₦500 tó fẹ́ gbà lọ́wọ́ rẹ̀
- Àwọn alákòso BCOS tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ iléègbé àwọn òṣíṣẹ́ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo bẹ̀rẹ̀ sí ń wó
- Báyìí ni ètò ìsìnkú Aàrẹ Chad àná, Idris Deby ṣe ń lọ
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti fihan pe nicotine onimajele lo pa arabinrin Jekecha.
Bakan naa ni wọn fikun pe Jekecha ni aisan ọkan ti ko i tii farahan, eleyii to jẹ ko lera fun un lati ji pada lẹyin to lo taba finfin.















