Naira Marley fi ìfẹ́ hàn sí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lójú pópó, àwọn méjì kó sẹ́nu tírélà

Oríṣun àwòrán, Naira Marley
Ori ko ọkan lara awọn ololufẹ gbajugbaja olorin takasufe, Naira Marley, yọ lọwọ iku ojiji lagbegbe Ajah, niluu Eko.
Fidio kan to n milẹ titi loju opo ikansiraẹni lori ayelujara lo ṣafihan bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Ninu fidio naa ni Naira Marley ti ṣi ferese ọkọ ayọkẹlẹ to wa ninu rẹ, to si n na owo jade si awọn ololufẹ rẹ lori popo.
- Àwọn alákòso BCOS tan ìmalẹ̀ sí ọ̀rọ̀ iléègbé àwọn òṣíṣẹ́ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo bẹ̀rẹ̀ sí ń wó
- Báyìí ni ètò ìsìnkú Aààrẹ Chad àná, Idris Deby ṣe ń lọ
- Kà nípa àìsàn tó dá gbajúmọ̀ òṣèré, Kemi Afolabi wólẹ̀ tí kò fi leè ṣe sinimá
- Màálù tí Ojo fẹ́ fi ṣègbeyàwó ló fẹ́ lọ rà tí wọ́n fi pà á, ti wọ́n gé ẹ̀yà ara rẹ̀ ní Kwara
Bo tilẹ jẹ pe ọkọ ti Naira Marley wa ninu rẹ wa lori ere, awọn ololufẹ rẹ ọhun n kii ni mẹsan an mẹwaa, ti wọn si n pariwo "Marley, o pọ, o pọ."
Awọn kan lara awọn eeyan naa wa lori alupupu, ti awọn alupuipu naa si n sare tete tẹle ọkọ Naira Marley lori ere.

Oríṣun àwòrán, NAira marley
Nigba ti Naira Marley na N500 jade si awọn meji kan lara awọn eeyan naa to wa lori alupupu, ti wọn si gba owo naa tan ni wọn ya bara sẹnu ọkọ ajagbe kan.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ni kete ti wọn ko si ẹnu ọkọ ajagbe naa tan ni Naira Marley ke gbajare si dẹrẹba ọkọ ajagba naa, to si n ke si pe ko rifaasi.
Gẹgẹ bii ohun to wa ninu fidio naa, awọn mejeji to wa lori alupupu naa ko farapa, ẹmi ẹnikẹni ko si ba iṣẹlẹ naa lọ.
Bo tilẹ jẹ pe ori ko awọn eeyan naa yọ, iṣeju aaya perete si iṣẹlẹ naa ni ẹlomiran tun n ki Naira mMarley ni mẹsan an mẹwa ki oun naa le ri owo gba lọwọ olorin ọhun.
Lasiko to fi fido ọhun soju opo Instagram rẹ, Naira Marley sọ pe "Diẹ lo ku ki arakunrin yẹn padanu ẹsẹ rẹ."
Ọpọ awọn to wo fidio naa lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iṣẹlẹ ọhun.
Bi awọn kan ṣe n kan sara si naira Marley fun aajo ololufẹ rẹ to ṣe, lawọn mii n sọ pe iṣẹ ati iya to wa lode le mu ki odidi gende fi ẹmi ara wewu nitori ₦500 pere.















