America Travel Advisory: Zamfara, Rivers àti ìpínlẹ̀ méjìlá tí ilẹ̀ Amẹrika kilọ̀ fáwọn ọmọ orile-ede rẹ láti má dé ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @Joe Biden
Láti ọjọ́ isẹgun ogúnjọ́ oṣù kẹrin ọdún 2020 ni ilẹ̀ Amẹrika ti rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti ròó ní ẹ̀ẹ̀mejì kí wọ́n tó rìnrìn àjò wá sí Nàìjíríà.
Ìdí ni pé orile-ede Nàìjíríà kún fún, ìwà jàndùkú, ìgbésùmọ̀mí, ìpànìyàn, ìjínigbé ati ole jíjà lórí omi, wọ́n fi kun pé àwọn àgbègbè kan tilẹ̀ ni ewu púpọ̀.
US wá rọ àwọn ọmọ ìlú rẹ̀ pe kí wọ́n ma dé àwọn ìpínlẹ̀ wọ̀nyí ni Nàìjíríà.
Borno, Yobe àti ìhà àríwá Adamawa nítorí ìwà ìgbésùmọ̀mí àti ìjínigbé tó n wáyé níbẹ̀.
Bauchi, Gombe, Kaduna Kano, Katsina àti Zamfara nítorí ìjínigbé.
Àwọn ìhà omi bi Akwa Ibom, Bayelsa, Cross River, Delta ati Rivers yàtọ̀ sí ìlú Port Harcourt nítorí ìwà ọ̀daràn, ìjínigbé ati ìwà ọ̀daràn lórí omi.
Àtẹ̀jáde lórí ibi tí àwọn arìnrìn-àjò le rin si lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà sọ pé ìwà jàndùkú to burú bí ìdigunjalè, ìfìyàjẹni, jíjâ ọkọ gbà, ìjínigbé, olè jíjâ lójú pópó, ifipábánilòpọ̀ pọ̀ jántì rẹrẹ ní orílè-èdè yii.
" Ìjínigbé fún owó gbígbà máa n ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ẹni tíì kii ṣe ará ìlú ni wọ́n n jí gbé pàápàá julọ ẹni tó wá fún àbẹ̀wò láti orílè-èdè mìíràn nítorí pé wọ́n wòye pé olówó ni wọ́n."
"Àwọn ajínigbé a máa dá ọkọ̀ tó n rírìn àjò láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíràn tí wọ́n yóò sì jí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ gbé.
Àwọn agbésùmọ̀mí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ lójoojúmọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, pàápàá julọ níhà ìlà-oòrùn ariwa.
Ni ìgbà mìíràn àwọn agbésùmọ̀mí kìí ṣe ìkìlọ̀ ṣáájú ìkọlù wọn, wọ́n sì sábà máa fojú Sun ilé ìtajá ìgbàlódé ńlá, ọjà, ilé ìgbáfẹ̀, ilé ìjọsìn ilé ọtí, ilé ìwé, àwọn ǹkan ìní ìjọba, ibùdókọ̀ àti àwọn ibi tí àwọn ènìyàn péjọ sí.
Ni ọ̀pọ̀ ìgbà wọ́n máa n bá àwọn ọ̀daràn abẹ́lẹ́ ṣe láti le gbòòrò si.
Àìní ifọkanbalẹ àti ìwà àwọn alakatakiti kan ni ìhà Gúúsù pàápàá jùlọ̀ ẹkùn tó n pèsè epo rọ̀ọ̀bì, àwọn ògbójú ọ̀daràn tó fi mọ́ ìjínigbé àti àwọn olè orí omi ló pọ̀ jántì rẹrẹ lágbègbè náà bi ilẹ̀ Amẹrika ṣe sọ
- Kíni ìdí ti àwọn ọmọ ogun fi n ṣọ́ àwọn Imaam ni Mecca?
- Àwọn olórí orílè-èdè ilẹ̀ Áfíríkà mẹ́fà tó rọ́pò òbí wọn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.
- Irọ́ lásán ni pé èèyàn 25 bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé ní òpópónà Igboọra sí Eruwa - Ọlọ́pàá Ọyọ
- Kíni ìdí ti àwọn ọmọ ogun fi n ṣọ́ àwọn Imaam ni Mecca?
- Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi dúró gìdìgbà lẹ́yìn Pantami t'áráàlú ní kó fipò sílẹ̀
Láìpẹ́ yìí ìròyìn ìjà láàrin àwọn àgbẹ̀ àti darandaran tí wàhálà sì n bẹ silẹ láàárín ìlú kan sí òmíràn ni Nàìjíríà .
Nítorí àìní ifọkanbalẹ ará ìlú lórí wàhálà ojoojumo nítorí ọ̀rọ̀ àbò, ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà àti àwọn ẹgbẹ́ lorisirisi ló ti ké sí ààrẹ Buhari láti sọ fún àwọn olórí ẹ̀sọ́ ààbò láti lọ rọ́kún nílé.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ààrẹ rọ gbogbo àwọn olórí ètò àbò lóye tó sì yan tuntun mìíràn, ọ̀pọ̀ sì rí èyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti wa ojútùú sí ọ̀rọ̀ ètò ààbò tó mẹhẹ.
Ẹ̀wẹ̀, kò sí ìkìlọ̀ ìrìnàjò fún Nàìjíríà nítorí ọ̀rọ̀ Covid-19 gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ka àwọn orílè-èdè tí o léwu láti lọ Nítorí Coronavirus.
Bákan náà ni àjọ tó n gbógun ti àjàkálẹ̀ ààrùn ni Nàìjíríà NCDC tí fi Nàìjíríà sí ipele àkọ́kọ́ (Level 1) lórí ọ̀rọ̀ Covid-19, èyí túmọ̀ sí pé àjàkálẹ̀ ààrùn náà kò lágbára ni orile èdè yìí.


















