Gbajúgbajà akọrin takasúfè nílẹ̀ America, DMX ti jáde l'áyé lẹ́ni ọdún 50

Oríṣun àwòrán, EPA
Gbajugbaja akọrin takasufe nilẹ America, DMX ti ku lẹni aadọta ọdun.
Iku rẹ waye lẹyin ọjọ karun ti ọkan rẹ ti da isẹ silẹ.
Akọrin naa, ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Earl Simmons, ti n lo ẹrọ to n ṣe iranlọwọ fun eemi lati igba naa ko to o di pe ku loju ẹbi rẹ.
Ninu atẹjade kan, mọlẹbi rẹ sọ pe akikanju eniyan ni, to ja fitafita titi de opin.
"Awọn orin Earl ni ipa lara awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye, tiit lai si ni iranti rẹ yoo wa."
Lara awọn akọrin to n leke ni DMX wa, to si kọrin papọ pẹlu awọn olorin bi i Jay-Z, Ja Rule ati LL Cool J.
Bakan naa lo tun kopa ninu awọn sinima bi i Cradle 2 the Grave, Romeo Must Die ati Exit Wounds.
Ọpọlọpọ ọdun lo fi ni ipenija pẹlu aṣilo egboogi oloro, to si lo ọpọlọpọ akoko ni ibudo itọju awọn to n lo eegbogi oloro.












