NAF Killing: A ti gbé ìwàdìí dìde láti mọ òkodoro ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Oríṣun àwòrán, @NigAirForce
Baalu ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu, NAF, ti ṣeku pa ogun lara awọn ọmọ ologun to n doju ija kọ ikọ agbesumọmi Boko Haram ni ipinlẹ Borno.
Iroyin naa ni ọkọ ofurufu naa ṣeṣi sọ ado oloro lu awọn jagunjagun to wa ni iha rẹ, ti nnkan bii ogun lara awọn ṣọja naa si dagbere faye.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ ke si awọn ọmọ ogun naa lati doju ija kọ awọn ọmọ ogun agbesumọmi Boko Haram ti ikọ Islamic State n ṣatilẹyin fun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ó tún n rúgbó bọ̀! Ṣé lóòótọ́ ni Olori Damilọla ti sá kúrò ní ààfin Ọyọ?
- Yorùbá, ẹ má ṣùn o lórí ààbò tó mẹ́hẹ torí àìláṣọ lọ́rùn pààká... - ARG lọgun
- Ọjọ́ Ajé gba ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ̀ ọmọ Nàíjíríà láti ọwọ́ àwọn agbébọn
- Agbébọn yabo ilé Sunday Igboho ní òru mọ́jú
- Iyabo Ojo àti Foluke Daramola tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Ìrù ejò lẹ̀ ń fà pẹ̀lú ìkọlù lemọ́lemọ́ sílé Sunday Igboho - Àgbààgbà Yorùbá
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní Iyana Iba l‘Eko lọ́jọ́ Aje, ọlọ́pàá ní kíì ṣé ìjà ẹlẹ̀yàmẹ̀ya
- Keyamo dójú ti ara rẹ̀ àti ìjọba tó ń sìn bó ṣe kéde ìtàkurọ̀sọ rẹ̀ pẹ̀lú Eedris fáyé - Amofin
- Ọmọ Nàíjíríà kan kú lásìkò tó bẹ́ sí River Thames ní London torí ó fẹ́ dóòlá ẹ̀mí obìnrin kan
- Buhari ló ń ki àwọn agbésùnmọ̀mí láyà láti ṣe ìkọlù - Ajàfẹ́tọ̀ọ́ẹni
Igbesẹ naa waye lasiko ti wọn n ṣakọlu si agbegbe Mainok to jẹ olu ijọba ibilẹ Kaga, nipinlẹ naa.
Awọn agbesumọmi ọhun kọlu agbegbe naa pẹlu ọkọ ti wọn gbe ibọn le lori bii marundinlogun, wọn si tun dana sun ibi ti awọn ọmọ ogun tẹdo si.

Oríṣun àwòrán, @NigAirForce
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn ọmọ ogun to lọ ṣatilẹyin fun awọn akẹgbẹ wọn, ni NAF sọ ado oloro le lori.
Iṣẹlẹ naa ti mu ki ọpọ ọmọ Naijiria koro oju si ileeṣẹ ologun, ti wọn si n fi erongba wọn lede lori ayelujara lori iṣẹlẹ naa.
Lasiko ti ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu n da si ọrọ naa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sẹ pe iṣẹlẹ naa ko waye, ṣugbọn wọn ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori rẹ.
Wọn ni awọn yoo si bun gbogbo ọmọ Naijiria gbọ laipẹ lori abajade iwadii wọn.
Wọn ni "Ileeṣẹ NAF ti gbọ nipa iroyin to sọ pe ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ṣekupa ogun lara awọn ọmọ ogun rẹ, a ti gbe iwadii dide lori iroyin naa, a oo si jẹ ki gbogbo araalu mọ abajade iwadii wa."
Ẹwẹ, pupọ awọn ọmọ Naijiria lo n yọ suti ete si ileeṣẹ naa lori iṣẹlẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, @iamlordraiden
Bi awọn kan ṣe n sọ pe wọn mọọmọ pa awọn ọmọogun naa ni, lawọn kan n sọ pe yoo dara ki awọn ni suuru de abajade iwadii ti ileesẹ ologun ofurufu fẹ se.
Ẹ wo diẹ lara awọn nnkan mii ti awọn eeyan n sọ loju opo Twitter:

Oríṣun àwòrán, @seunoye04

Wọ́n ti sin òkú àwọn èèyàn tó lé ní àádọ́ta tí àwọn agbébọn pa ní Zamfara báyìí

Oríṣun àwòrán, AFC
Wọn ti sin oku awọn eeyan mọkanlelaadọta ti awọn agbebọn ṣekupa ni ipinlẹ Zamfara l'Ọjọbọ
Ẹnikan ti ọrọ ṣoju naa rẹ sọ fun BBC pe ẹkun Magami ni wọn ti ṣekupa awọn eeyan naa lawọn abule kan.
Awọn agbebọn ọhun dabọn bo awọn eeyan nigba ti awọn kan fẹ doola wọn.
- Dangote àti iléeṣẹ́ méjì ló ń ta símẹ́ntì, ìjọba gbọdọ̀ wá ńkan ṣe sí ọ̀wọ́n-gógó yìí- Aṣòfin
- Kò sí ọ̀wọ́n-gógó epo bẹntiró núlùú Abuja- NNPC
- Àwọn jàndùkú agbébọn pa èèyàn mẹ́jọ, wọ́n tún jí ọ̀pọ̀ gbé lọ ní Kaduna
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn àdúgbò tó ta lẹ́nu jùlọ nílùú Ibadan
- Wo àwọn nǹkan tí o lè má mọ̀ nípa apanilẹ́rìn, Ada Jesus tó jáde l'áyé
- Bobrisky sọ̀rọ̀ sókè lórí ìdí tí kò fi kópa nínú àwẹ̀ Ramadan tó ń lọ lọ́wọ́
Iroyin kan sọ pe awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn lẹkun Magami lẹyin iṣẹlẹ iṣekupani naa.
Awọn ti ọrọ ṣoju wọn ṣalaye pe ogun eeyan ni wọn pa ni abule Ruwan Dawa, mẹwaa ni Kangon Fari Mana.
Mẹfa ni wọn pa ni abule ni Madaba, mẹfa naa ni Wealth, ẹyọkan ni Kogo, ati ẹyọkan ni Ayaya ati ẹyọkan ni Rairai.
Ẹnikan sọ pe awọn janduku naa n yinbọn ni abule Kangon Fari Mana fun bii wakati meje.
Ọjọ keji lawọn eeyan abule Yar Doka to pada si ibugbe wọn lẹyin ikọlu awọn agbebọn naa.
Aarọ Ọjọbọ ni wọn sin eeyan mẹwa ti wọn sẹkupa ni abule Kangon Fari Mana.
Awọn eeyan abule naa ni aisi awọn ẹṣọ eleto abo n fi iya jẹ awọn.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara ti ṣalaye pe awọn ti ko awọn ẹṣọ ranṣẹ si ẹkun naa.
Awọn ara abule naa ni awọn ko le tun ara awọn oku eeyan awọn ṣe nitori awọn n bẹru pe awọn janduku naa le pada wa.
Eeyan mọkanla ni wọn gbe lọ si ile iwosan ijọba ni Magami nibi ti wọn ti n gba itọju.
















