Kaduna killings: Àwọn jàndùkú pa èèyàn mẹ́jọ, wọ́n tún jí ọ̀pọ̀ gbé lọ ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, Twitter/Kaduna Government
O kere tan, eeyan mẹjọ lawọn agbebọn ṣekupa lọjọ Iṣẹgun nigba tawọn eeyan mii si farapa yanyana ninu ikọlu tuntun to waye nipinlẹ Kaduna.
Kọmiṣọnna fun ọrọ abo abẹle nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan ṣalaye pe awọn agbebọn ọhun di oju ọna lẹba abule Kadanye lagbegbe Kajuru.
Ọgbẹni Aruwan sọ pe nibẹ ni wọn ti dabọn bo ọkọ bọọsi akero kan ati ọkọ akẹru to ko igi idanam wọn si yinbọn pa eeyan marun un lẹsẹ kẹsẹ.
- Tinubu ló lè ṣeé lọ́dún 2023, Pa Fasoranti àti Oba Osemawe Ondo sọ̀rọ̀ sókè
- Asọtẹ́lẹ̀ ikú Yinka Odumakin ti jáde sí wa tẹ́lẹ̀, ẹbí gbàdúrà, àmọ́...- Jacob Odumakin
- Ọlọ́pàá fọhùn pé ẹgbẹ́ IPOB ni àwọn agbébọn tú ẹlẹ́wọ̀n 1,844 sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Owerri
- Dáa padà! Àwọn alátìlẹ́yìn Buhari fàdúrà jagun lòdì sáwọn tó ń fẹ̀hẹ́nùhàn lé e kúrò ní London
- Àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa adelé Ọ̀gá Àgbà ọlọ́pàá ti Buhari ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn
- Àwọn òbìnrin tó ń ya fọ́tò ìhòhò ara wọn níwájú ilé kó sí gbaga ọlọ́pàá!
- Ìdí tí mo fi ṣe ìgbéyàwó ìdákọ́nkọ́ - Sotayo Gaga
Awọn kan tiẹ sọ pe wọn tun ji ọpọ eeyan gbe ninu iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni
Kọmiṣọnna fun ọrọ abo abẹle nipinlẹ Kaduna ṣalaye pe ni abule Akilbu ati Inlowo lagbegbe Kachia lawọn agbebọn ti yinbọn pa awọn eeyan mii.
Bakan naa lo sọ pe ọgọsan maalu ni wọn tun jigbe lọ ni gaa awọn darandaran to wa lagbegbe naa.
Ọgbẹni Aruwan tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa dena ikọlu mii ti ko ba tun waye loju ọna Kaduna si Birni Gwari lagbegbe Buruku.
Awọn ọlọpaa yabo ibi tawọn agbebọn ọhun ti fẹ ṣọṣẹ nibi ti wọn ti doju ija kọ ara wọn ti awọn janduku naa si fẹsẹ fẹ.
Eeyan meji, Fahad Lawal ati Usman Shehu ni wọn doola nibẹ, awọn mejeeji si n gba itọju nile iwosan bayii.













