Usman Alkali Baba biography: Nígbà tí Adamu ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ní Owerri, Ààrẹ Buhari yan Alkali ní adélé Ọ̀gá Ọlọ́pàá tuntun

Usman Alkali Baba

Oríṣun àwòrán, The cable ng

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni wipe aar Muhammadu Buhari ti yan igbakeji ọga ọlọpaa Usman Alkali Baba gẹgẹ bi adele ọga ọlọpaa tuntun.

Eyi n waye gẹgẹ bi Muhammed Adamu to jẹ ọga awọn ọlọpaa ni Naijiria n mojuto iṣẹlẹ ikọlu to waye ni ọgba ẹwọn ipinlẹ Owerri.

Minisita foro olọpaa, Maigari Dingyadi lo kede igbesẹ tuntun ti aarẹ ṣẹṣẹ gbe naa.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa Alkali Baba Usman

Ọdun 1963 ni wọn bi Alkali Baba Usman ni ipinlẹ Yobe.

O kawe gboye ni Fasiti Bayero to wa nilu Kano, ati Fasiti ilu Maiduguri.

Ọdun 1988 lo darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa ti o si goke lati oye ASP di kọmiṣọna ọlọpaa mi ọjọ kẹtadinlọgbọn ọdun 2013.

Ṣaaju iyansipo rẹ gẹgẹ bi Adele Ọga Agba ọlọpaa, oun ni oludari ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ati iwadii iwa ọdaran..

Àkọlé fídíò, 'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'

Gbogbo awọn eto ẹkọṣẹ gbogbo ro yẹ fun oye kọọkan to gba lo ṣe lori awọn isẹ iwadii, igbesumọmi ati kikoju iwa ọdaran gbogbo to fi mọ amojuto lilọ bibọ ọkọ.

O jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ajọ ọlọpaa lagbayebeeni o tun jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ jade nileekọṣẹ omo-ogun lagbaye International War College.

O figba kan ri jẹ igbakeji kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Kaduna ati Abuja.

Alkali Usman yoo maa gbaṣẹ lẹyẹ-o-ṣọka lọwọ ọga agba olopaa, Mohammed Adamu to n fi ipo naa silẹ bayii.

Ni osu keji ọdun 2021 lo ti yẹ ki Mohammed Adamu o fi ipo naa silẹ, ṣugbọn Aarẹ Buhari fi kun iye ọjọ rẹ lori oye nigba naa

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin bo ba ṣe nlọ.