When can I get the Covid vaccine: Ó ṣeéṣe kí ìjọba Naijiria dáwọ́ gbígbà abẹrẹ Covid-19 dúró kí abala kejì tó dé

Buhari

Oríṣun àwòrán, @naijapremiumgst

Awọn alaṣẹ eto ilera ni Naijiria ti sọ pe awọn yoo dawọ fifun awọn eeyan labẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti Osford-Astrazeneca ṣe duro ti awọn eeyan ba ti gba idaji abẹrẹ to wa ni ikawọ wọn.

Minisita abẹlẹ fun eto ilera, Olurunnimbe Mamora sọ fun awọn akọroyin pe awọn ko le sọ ni pato akoko ti abala keji abẹrẹ naa yoo de.

Nitori naa ni wọn yoo ṣe da gbiba rẹ duro ki awọn to ti gba abẹrẹ naa ṣaaju le gba nigba keji.

Ti ẹ ko ba gbagbe, igba meji ọtọtọ ni awọn eeyan yoo ni lati gba abẹrẹ naa fun abo to peye.

Gẹgẹ bi ohun ti Mamora sọ, ijọba yoo dawọ gbiga rẹ duro ki abẹrẹ naa ma baa tan nilẹ ki awọn to ti gba abala kinni le ri gba lẹẹkan si, paapaa ni bayii ti wọn ko mọ akoko ti abala keji rẹ yoo de.

Vaccine

Oríṣun àwòrán, @MowliidHaji

Atẹjade kan lati ileeṣẹ to n ri si eto ilera alabọde fi han pe nnkan bii miliọnu kan eeyan lo ti gba abẹrẹ naa ni Naijiria fun igba akọkọ.

Àkọlé fídíò, 'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'

Awọn eleto ilera ni wọn kọkọ fun labẹrẹ ọhun nigba ti wọn ko wọ Naijiria loṣu Keji ọdun yii.

Ẹwẹ, ijọba Naijiria ti bẹrẹ si n ṣayẹwo abẹrẹ ajẹsara meji miran ti awọn onimọ ijinlẹ rẹ ṣe.

Nnkan bii 162,000 eeyan lo ti fara kasa Coronavirus ni Naijiria, ẹgbẹrun meji eeyan o le diẹ si ti ba arun naa lọ.

Àkọlé fídíò, Jimoh Ológì déé! Ọ̀mọ̀wé ní kílàsì fásitì, ológì nílé