ASUP gbé àgádágodo sẹ́nu ọ̀nà àwọn ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣde ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, @justeventsonlin
Ẹgbẹ awọn olukọ ile ẹkọ gbogboniṣe, ASUP, ti gunle iyanṣelodi ọlọjọ gbọọrọ lati bere fun atunto bi ijọba ṣe n san owo oṣu wọn.
Gẹgẹ bi ohun ti ẹgbẹ naa sọ, iyanṣelodi ọhun ti bẹrẹ lonii ọjọ Iṣegun, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2021.
ASUP kede iyanṣelodi naa lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba apapọ niluu Abuja.
- Asọtẹ́lẹ̀ ikú Yinka Odumakin ti jáde sí wa tẹ́lẹ̀, ẹbí gbàdúrà, àmọ́...- Jacob Odumakin
- Kò sí dókítà kankan tó yanṣẹ́lódì l'Oyo - Ìjọba; irọ́ ni o, a ti daṣẹ́sílẹ̀ - Àwọn dókítà
- Àwọn òbìnrin tó ń ya fọ́tò ìhòhò ara wọn níwájú ilé kó sí gbaga ọlọ́pàá!
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dóòlà ọmọ ọdún méjì tí wọ́n tìmọ́lé fún ọjọ́ mẹ́ta láì jẹun
Yatọ si atunto bi ijọba ṣe maa n san owo wọn ti wọn n bere fun, ASUP tun sọ pe ki ijọba san owo to jẹ awọn olukọ lawọn ile ẹkọ gbogboniṣe lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria.
Wọn tun fi ẹsun kan ijọba pe o kọ lati san owo oṣu mẹwaa to jẹ awọn oṣiṣẹ wọn lẹyin to buwọlu owo oṣu tuntun to kere ju fun awọn oṣiṣẹ.

Oríṣun àwòrán, @justeventsonlin
ASUP ni iyanṣelodi ọhun ṣe pataki lasiko yii, paapaa niwọn igba ti ijọba apapọ ti kọ lati mu awọn ileri to ṣe fun awọn ṣẹ.
Arẹ apapọ ẹgbẹ naa, Anderson Ezeibe ni, bo tilẹ jẹ pe awọn yoo ṣi maa ba ijọba apapọ jiroro, ko si ohun ti yoo da iyanṣelodi ọhun duro ayafi ti ijọba ba da awọn lohun.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ko pẹ ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti, ASUU, wọgile iyanṣẹlodi ti awọn naa gunle lẹyin oṣu mẹsan an gbako.
Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ, JUSUN, ati ẹgbẹ awọn dokita naa ti bẹrẹ iyanṣẹlodi.
- Ọlọ́pàá fọhùn pé ẹgbẹ́ IPOB ni àwọn agbébọn tú ẹlẹ́wọ̀n 1,844 sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Owerri
- Dáa padà! Àwọn alátìlẹ́yìn Buhari fàdúrà jagun lòdì sáwọn tó ń fẹ̀hẹ́nùhàn lé e kúrò ní London
- Ojú wa rí, a ṣe IVF, oyún ìbeji bàjẹ́ kí á tó di ọlọ́mọ láyé - Adesua àti Banky W
- Gbogbo ìbéèrè tóo ní lọ́kàn nípa dída omira obìnrin lásìkò ìbálòpọ̀, ìdáhùn rèé
- Vitamin D àti Covid-19: Òótọ́ nípa àṣírí tó wà níbi òògùn yìí fún ìwòsàn Covid














