Channels TV: SERAP ní òun yóò wọ́ NBC relé ẹjọ́ torí pàṣán tó fi na iléeṣẹ́ ìròyìn

Ami idamọ ileesẹ Channels

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ awọn olootu iwe iroyin ni Naijiria, NGE, ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan, SERAP ati ẹgbẹ oṣelu PDP ti bu ẹnu atẹ lu ileeṣẹ to n ri si eto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria, NBC, lẹyin to fofin de ileeṣẹ Iroyin Channels.

NGE sọ pe awọn ko fọwọ si bi NBC ṣe n dunkoko mọ ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels lẹyin to ṣe ifọrọwerọ pẹlu agbẹnusọ ẹgbẹ IPOB, iyẹn ọgbẹni Emmanuel Powerful lọjọ Aiku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eto naa to waye lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ lori amohunmaworan Channels ko dun mọ ijọba ninu tori awọn ọrọ kan ti alejo naa sọ lori eto "Politics Today."

Eyi si lo mu ki ileesẹ NBC fi iwe ranṣẹ si ileeṣẹ tẹlifiṣan naa, to si ni ki wọn da eto naa duro fun igba diẹ.

Ami idamọ ileesẹ NBC

Oríṣun àwòrán, nbcgovng

Ijọba n se ojusaaju ninu ipinnu rẹ - NGE

Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin, ẹgbẹ NGE sọ pe awọn ileeṣẹ iroyin ko ni le ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ, ti ijọba to wa lode ba n dunkoko mọ wọn.

Ẹgbẹ naa ni digbi ni awọn wa lẹyin Channels bi ike, awọn ko si ni gba ki ijọba to wa lode yii gbin ẹru si ọkan awọn ileeṣẹ iroyin ni Naijiria.

Lẹyin naa lo ṣalaye pe, ijọba to wa lode yii n se oju ṣaaju nitori ko na awọn ileeṣẹ iroyin kan to gbe iroyin nipa ifọrọwerọ ati ipade ẹlẹsin Musulumi, Sheikh Gumi pẹlu awọn janduku to n da alaafia Naijiria ru ni paṣan.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Iya ti ijọba fi jẹ ileesẹ Channels tako ofin - SERAP

Ni ti SERAP, wọn ni ki ijọba apapọ ati NBC yi ipinnu wọn pada lori igbesẹ ti wọn gbe lati fi iya jẹ ileeṣẹ iroyin Channels, ati owo itanran miliọnu marun un naira ti wọn ni ki ileeṣẹ naa san.

Ninu atẹjade kan ti adari rẹ, Kolawole Oluwadare buwọlu, SERAP ni "Idaduro ileeṣẹ iroyin Channels lodi si ofin, ko si lẹsẹ nilẹ.

A fẹ ki ijọba ati NBC pa igbesẹ naa da ni kankan, bi bẹẹ kọ a o lọ sile ẹjọ lẹyin wakati mejidinlaadọta."

O ni igbesẹ yii n ṣafihan pe, ijọba to wa lode ko fẹ ki awọn ileeṣẹ iroyin ṣe iṣẹ wọn gẹgẹ bii ofin ṣe gba wọn laaye.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Kọ́ ẹ̀kọ́ si nípa ààlọ́ nílẹ̀ Yorùbá

Pasan tijọba fi na ileesẹ Channels yoo da kun isoro Naijiria - PDP

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP ti juwe igbesẹ ti ajọ NBC gbe lori ileeṣẹ iroyin Channels gẹgẹ bii eyii to bani lọkan jẹ.

PDP sọ ninu atẹjade kan pe "Igbesẹ yii jẹ eyii to le da kun wahala to wa nilẹ ni Naijiria, paapaa lasiko ti a wa yii, nitori naa a rọ ijọba lati tun ọrọ naa gbe yẹwo."

Lori eto ileesẹ Channels ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ IPOB ti ijọba ti fofin de, fẹsun kan ileeṣẹ ologun pe wọn pa ọkan lara awọn adari ẹgbẹ ọhun lọna aitọ loju ọna abule rẹ, ti wọn si parọ fun awọn araalu bi ọrọ iku ọhun ṣe jẹ.

Igbesẹ ileeṣẹ naa, paapaa ọrọ ti Emmanuel Powerful sọ lori eto naa, si ni ko dun mọ ijọba apapọ ninu.

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ fi n fi erongba wọn lede lori bi NBC ṣe na ileeṣẹ iroyin naa ni paṣan, lẹyin ifọrọwerọ ọhun.

Amin iyasọtọ kan

Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní Iyana Iba l'Eko lọ́jọ́ Aje, ọlọ́pàá ní kíì ṣé ìjà ẹlẹ̀yàmẹ̀ya

Aworan araalu to n sa asala fẹ mi wọn

Oríṣun àwòrán, Punch Newspapers

Ariwo yago fadugbo Iyana Iba ati Volks lo gba ori Twitter kan lọsan ọjọ Aje.

Eyi ko si sẹyin wahala to bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW ati awọn ọlọkada lagbegbe Iyana Iba.

Gẹgẹ bi iroyin ta gbọ, ija yii ko sẹyin bi awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkọ ṣe fẹ ja iwe fawọn ọlọkada kan ni agbegbe iyana Iba ni Ojoo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O soju mi koro kan ti o pe rorukọ ara rẹ ni Ibrahim sọ fun akọroyin pe nkan bi ago mẹjọ aarọ ni wahala yii ti bẹrẹ.

''Ikọlu laarin awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ati awọn ọlọkada lo da ki ni yii silẹ. O ti tan de Alkaba Rago to fi mọ ibudo iwọkọ Volks''

Àkọlé fídíò, Akure okada attack: Ọlọ́kadà tí àwọn afunrasí darandaran ṣá ní

O ṣalaye pe awọn eeyan to wa nibẹ n sa asala fẹmi ara wọn nigba ti awọn ọlọkada naa doju ija kọ awọn ẹgbẹ NURTW .

Loju opo Twitter, n ṣe ni orisirisi fọnran fidio gbode nibi tawọn eeyan ti n sare asala kuro nibi wahala naa.

Ninu awọn fidio naa si ni wn ti ni ẹmi kan ti bọ sinu wahala naa.

Àkọlé fídíò, Ekiti Election: Ẹgbẹ́ awakọ̀ Ekiti pa ìjọba dà lẹ́yìn tí wọ́n kéde Fayẹmi

Ọlọpaa ni alaafia ti pada lẹyin rogbodiyan

Ninu ọrọ rẹ, alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko, Muyiwa Adejobi ni alaafia ti pada si agbegbe naa lẹyin rogbodiyan ọhun.

O ni awọn agbofinro ti wa nibẹ ṣugbọn ija to waye ko ni se pẹlu ẹlẹyamẹya rara gẹgẹ bi awọn eeyan kan se n gbe ahesọ ọrọ yii kiri.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ni ki araalu maṣe jaya ati pe laipẹ awọn yoo sọrọ lẹkunrẹrẹ nipa ohun to waye, eyi to bi laasigbo naa.