Sunday Igboho: Àwọn èèkàn ọmọ Yorùbá fárígá lórí ìkọlù ìgbà gbogbo sílé ajìjàgbara

Oloye Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1

Awọn agbaagba nilẹ Yoruba, awọn lọbalọba, to fi mọ awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba, ti bẹrẹ si fesi lori ikọlu si ile ajijagbara fun ilẹ Yoruba, oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho.

Agbenusọ fun Sunday Igboho, Dapo Salami lo sọ fun BBC Yoruba pe ni oru Ọjọ Aje, ni nkan bii aago kan oru, ni awọn agbebọn wa si ile Sunday Igboho, ti wọn si bẹrẹ si ni yin ibọn.

Salami ni ọpẹlọpẹ awọn eniyan to wa ninu ile Igboho lo dojukọ awọn agbebọn naa, ti wọn si bori wọn.

Amọ, iṣẹlẹ naa ti mu ki awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba ati awọn ọba alaye kesi ijọba lati wa wọrọkọ fi ṣe ada lori ikọlu lemọlemọ si ile Sunday Igboho.

Ọmọ Yorùbá tó bá gbàbọ̀dé fún Sunday Igboho, ó ku òun àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀ - Yoruba Welfare Group

Ẹgbẹ Yoruba Welfare Group ti ni ọmọ ale ilẹ Yoruba ni yoo fi idunnu han si ikọlu ti awọn agbegbọn n ṣe si Sunday Igboho, ni ilu Ibadan ni lemọlemọ.

Yoruba Welfare Group

Oríṣun àwòrán, Yoruba Welfare Group

Alaga ẹgbẹ YWG naa, Comrade Abdulhakeem Adegoke Alawuje lo fi ero ẹgb naa han bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ pẹlu afikun pe ibatan ni Sunday Igboho jẹ si oun gẹgẹ bi ọmọ Yoruba.

Comrade Alawuje ni ijọba ko ni ere kankan nipa ṣiṣe ikọlu si ile Sunday Igboho, nitori naa, ki wọn ṣe iwadii ni ẹkunrẹrẹ nipa awọn to wa ni idi iṣẹlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ilẹ Yoruba kii ṣe ibi ti awọn eniyan ti le ma a digun abẹle si ara wọn.

''Ti ijọba ba ni ẹsun ti wọn fi kan Sunday Igboho, ki wọn tẹlẹ ofin orilẹede Naijiria, kii ṣe ikọlu sii ni oorekoore''

''Bakan naa, ti a ba ri ọmọ ale Yoruba to n gba abọde fun Sunday Igboho, o ku ẹni naa ati ẹlẹda rẹ.''

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

''Nitori ojulowo ọmọ Naijiria gbọdọ ṣe atilẹyin fun Sunday Igboho, nitori awọn ni oun ja fun un.''

Ẹgbẹ Yoruba Welfare Group naa ni ijọba ko ba ri iwadii naa ṣe ni kulẹkulẹ, awọn alalẹ ilẹ Yoruba ni yoo ṣe idajọ awọn to n ṣekọlu si Sunday Igboho.

Kii ṣe Sunday Igboho nikan ni wọn n ṣe ikọlu si, gbogbo ọmọ Naijiria ni - Ọkẹrẹ Saki

Ọkẹrẹ tilu Shaki ni agbegbe Okeogun, nipinlẹ Oyo, Oba Khalid Olabisi Oyeniyi ti ni eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria lo fa ikọlu lemọlemọ si ile Sunday Igboho.

Ọba Oyeniyi ni ko si ọkan ẹnikẹni to balẹ mọ ni Naijiria, nitori ikọlu ati ijinigbe to gbode kan ni Naijiria.

Oba Khalid Olabisi Ilugbemidepo, Oyedepo kẹta

Oríṣun àwòrán, H.R.M Oba Khalid Olabisi the Okere of Saki Land

Kabiyesi to n rin irinajo lọwọ ni, n ṣe ni ẹmi oun gbe soke, ti ko si le e sinmi bayii titi oun yoo fi de ibi ti oun n lọ.

O ni o ba ni lọkan jẹ nitori wi pe ko si ẹni to lero wi pe iru iṣẹlẹ bayii le ma a waye ni Naijiria.

Ọkẹrẹ wa parọwa si ijọba lati kesi Ajọ Isọkan agbaye lati wa ran wọn lọwọ lori eto aabo to dẹnukọlẹ tan ni Naijiria, nitori agbara ijọba orilẹede yii ko ka ohun to wa ni ilẹ mọ.

Ti eto aabo ba ti mẹhẹ, ko si nkan ti ko le ṣẹlẹ-Ọba Onilala

Onilala tilu Lanlate, Oba Sunday Oladejo, ni o ṣeni laanu wi pe wọn tun lọ ṣekọlu si ile Sunday Igboho.

Amọ, Kabiyesi Oladejo ni awọn lọbalọba ko i tii le sọ pupọ lori iṣẹlẹ naa nitori iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọba Sunday Oladejo

Oríṣun àwòrán, Ọba Sunday Oladejo, Onilala of Lanlate

Ọba Oladejọ ni eto aabo, paapaa ni ipinlẹ Oyo ti dẹnukọlẹ patapata, ti apa ijọba ko si ka a mọ.

O ni iru iṣẹlẹ to waye si Sunday Igboho ko ni ye ma a waye, nitori ti eto aabo ko ba ti gbe pẹẹli soke, oriṣiriṣi nkan ni yoo ma a ṣẹlẹ.

Iru ejo l n fa lọwọ pẹlu ikọlu lemọlemọ si Sunday Igboho- Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Odua

Akọwe Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Odua, Opeoluwa George Akinola ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ti awọn agbebọn kan ṣe si Sunday Igboho.

Opeoluwa George Akinola ni Sunday Igboho ko ṣe ibi kankan si ẹnikẹni, bẹẹ si ni ko ba ti eniyan jẹ.

O ni ilẹ Yoruba ati ominira awọn ọmọ Oodua ni Sunday Igboho n ja fun.

Egbe Ilana Omo Oodua

Oríṣun àwòrán, Facebook

Bakan naa ni o beere ni ọwọ ijọba wi pe, ki ni wọn n dun koko mọ Sunday Igboho si, ati wi pe ki ni wọn wa a fun?

O fikun wi pe awọn to n ṣekọlu si Sunday Igboho n fa ejo lẹsẹ ni o, ti wọn ko ba fẹ ri wahala ati rogbodiyan.