Boko Haram Geidam Attack: Gómìnà Mai Mala Buni ní inú ìpayínkeke ni èèyàn ìpínlẹ̀ Yobe wà

Geidam Boko Haram attack update: Inú ìpayínkeke ni a wà ní ìpínlẹ̀ Yobe- Mai Mala Buni

Oríṣun àwòrán, Mai Mala Buni

Gómìnà ìpínlẹ̀ Yobe Mai Mala Buni, ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ìpińlẹ̀ oun tí wà ní ipò tó níra lọ́wọ́ ikọ̀ ọmọ ogun Boko Haram, láti ọjọ́ Eti tó kọjá.

Mai Mala ni gbogbo ènìyàn ló mọ gbogbo ǹkan tó n ṣelẹ̀ ní apá ìlà-òòrùn àríwá, sùgbọ́n ó ní èyí tó ń wáyé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí nílò àbójútó.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú BBC, gómìnà náà sàlàyé pé, nǹkan ṣì sẹ́pẹ́rẹ́ lásìkò díẹ̀ sẹ́yìn, sùgbọ́n lẹ́nù ọjọ́ mẹ́ta yìí, nǹkan ti yíwọ́ nítori pé kò sí ẹni tó mọ nǹkan ti àwọn èniyàn tó wà nídi ìkọlù yìí ń fẹ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀rọ̀ gómìnà yìí wáyé nítorí ọ̀pọ̀ ló n ké gbàjarè pé, wọ́n kò gbọ́ òhunkóhun láti ẹnu gómìnà láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ ìpàniyàn àwọn Boko Haram ti bẹ́ sílẹ̀, tí ọ̀pọ̀ sì ti sá kúrò ní ibùgbé wọn.

Awọn eeyan miran ló ni àwọn ti sá kúrò ni ibùgbé àwọn nítorí wọn kò fẹ́ kí ọwọ́ja igbésùmọ̀mí náà kan awọn, nígbà ti Boko Haram àti àwọn ọmọ ogun bá nkojú ara wọn.

Geidam Boko Haram attack update: Inú ìpayínkeke ni a wà ní ìpínlẹ̀ Yobe- Mai Mala Buni

Oríṣun àwòrán, HQNigeriaArmy

Ẹ̀wẹ̀, Gómìnà Buni sọ fún BBC pé, kìí ṣe pé òun jòkó káwọ́ gbera, sùgbọ́n òun ń bá àwọn ọmọọgun sọ̀rọ̀ ní Abuja láti ìgbà dé ìgbà, lójúnà à ti rí ojúùtú sí ìsòrò tó wà nílẹ̀.

Gómìnà ní sáájú àsìkò yìí, àwọn agbésùmọ̀mí yìí máa n wá láti jí oúnjẹ àti nǹkan ìní àwọn ènìyàn sùgbọ́n lásìkò yìí, wọ́n jòkó pa sínú ìlú ni, fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.

Inú hilàhílò ni ọ̀pọ̀ ará ìlú wà, tí ọ̀pọ̀ sí fi ìlú sílẹ̀ láti farapamọ́ láwọn ìlú tó wà ni tòsí wọn.

"Mó sì n bá ọga agba awọn ológun l'Abuja sọ̀rọ̀ láti wá ọ̀nà abáyọ sí ọ̀rọ̀ yìí àti lati mú kí nǹkan bọ́ sípò ní ìpińlẹ̀ wa," Mai Mala Buni sọ èyí.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

"Sùgbọ́n gómìnà fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn pé ní ìpínlẹ̀ naa, àwọn yóò ṣapa láti mú nǹkan padà bọ̀ sípò, kí Abuja to gbe ìgbésẹ̀.

ló ǹ ṣẹlẹ̀ gan

Láti bi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni ìkọ alákatakítí Boko Haram ti tún tẹra mọ́ ìkọlu Geidam àti àwọn ìpińlẹ̀ mííràn, ni àgbégbé ilà-òòrùn àríwá Nàìjíríà.

Láàrín àwọn ti wọ́n pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ Eti ni obìnrin kan ti rọ́kẹ́ẹ̀tì tí wọn jù mọ́ ilé ìyá ọkọ́ rẹ̀ ti báa, lásìkò tó ṣàbẹ̀wò sí Geidam.

Ìròyìn sọ pé, àwọn agbésùnmọ̀mí tún já ilé àti sọ́ọ̀bù, tí wọn sí kó ọ̀pọ̀ ounjẹ lọ.

Ìjà tún bẹ́ sílẹ̀ láàrín àwọn agbésùnmọ̀mí àti àwọn ọmọogun Nàìjíríà, ní ìlú Mainok ni ìpínlẹ̀ Borno, tí ìròyìn sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ náà kan àwọn ọmọogun.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

A gbọ́ pé àwọn ọmọogun dá ààrin àwọn ikọ agbésùmọ̀mí rú nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní yìbọ́n ni Mainok.

Ìròyìn mííràn tún sọ pé, wọ́n jí irínṣẹ́ àwọn ọmọogun lọ, tí wọ́n sì pá àwọn mííràn.

Ẹ̀wẹ̀, gbogbo ìgbìyànjú láti bá agbẹnusọ ologun Brigadier General Muhammad Yerima sọ̀rọ̀ ló já sí pàbó.

Ètò ààbò ń búru sí lójoojúmọ ni lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí sì tí mú kí àwọn òǹwòye sọ pé ẹ̀rù ń ba àwọn fún ọjọ́ iwájú Nàìjíríà.

Eyi ri bẹẹ ni pàápàá jùlọ nítorí ìròyìn tó sọ pé ǹkan ìjà ogun kò tó mọ́ fún àwọn ọmọogun Nàìjíríà lati fi sisẹ.

Amin iyasọtọ kan

Boko Haram sígun bo ìpínlẹ̀ Yobe, ikọ̀ ọmọogun òfurufú dojú ìbọn kọ wọ́n

Gaidam Boko Haram

Oríṣun àwòrán, NAF

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ikọ ọmọogun Naijiria ni awọn ti bori ikọ agbesunmọmi Boko Haram to ṣigun bo agbegbe Geidem nipinlẹ Yobe.

Ikọ ọmọogun ni awọn ọmọogun ofurufu to gbe ọkọ ofurufu lo bori wọn ninu atẹjade ti wọn fi lede.

Iroyin ni ikọ ọmọogun Boko Haram wọ ọkọ ologun wo agbegbe naa ni iha ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Boko Haram ṣekọlu naa si awọn eniyan ti wọn n jẹun lati ṣinu awẹ Ramadan ti wọn n gba lọwọ.

Boko Haram

Oríṣun àwòrán, NAF

Awọn ti iroyin naa ṣe oju wọn ni o le ni ogun awọn ikọ Boko Haram ti wọn ṣekọlu si agbegbe Geidam ọhun, ko to di wi pe ọkọ ija ti ofurufu de lati koju wọn.

Agbegbe Geidem ni ipinlẹ Yobe ọhun ni Adele Ọga Ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba ti wa.

Gaidam Boko Haram

Ikọ ọmọogun ni awọn koju lara awọn ikọ Boko Haram nibi ti wọn ti n salọ lẹyin ti wọn jawọ atako naa.

Amọ ko tii si ẹni to le e sọ iye eniyan ti ẹmi wọn ti ba iṣẹlẹ naa lọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Yobe, ASP Dungus Abdulkarim ni ikọ Boko Haram naa ti wa saaju lati wa pin iwe fun awọn eniyan lati ma a reti awọn, nitori awọn nbọ lati wa sọ ipinlẹ Yobe da ipinlẹ awọn musulumi (Islamic State).

Àkọlé fídíò, Ikorodu cult crisis:A máa gbé Orò síta lọ́jọ́kọ́jọ́ tí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn bá tún ṣẹlẹ̀- Àwọ