Uloho Othuko: Mi ò kábàmọ̀ pé mo fẹ́ ìyàwò méjì lọ́jọ́ kan ṣoṣo

Uloho

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan ti sọ pe oun fẹ iyawo meji lẹẹkan ṣoṣo lati ṣe ju ohun ti baba oun gbe sẹ nile aye.

Nigba to n ba BBC sọrọ lori idi to ṣe gbe obinrin meji ni iyawo lọjọ kan naa, Uloho Othuko sọ pe ori meji san ju ẹyọ kan lọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan n sọ pe ọkunrin naa ti ko ara rẹ sinu wahala ti ko ni le gbọ tan bo ṣe fẹ obinrin meji papọ, ṣugbọn o ti fesi pe ko si ewu kankan ninu ẹgbẹrun ẹkọ, ayafi aidun ọbẹ.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Othuko ni lootọ ni baba oun fẹ iyawo kan ṣoṣo, ṣugbọn baba naa maa n gbadura fun oun pe oun yoo ṣe ju ohun gbogbo ti ṣe laye lo jẹ ki oun gbe iyawo meji lọjọ kan naa.

Yatọ eyii, o ni oun fẹran awọn obinrin meji ọhun denu ọkan.

Ọkan lara awọn iyawo rẹ naa, Ikpama Evelyn, to jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn ṣalaye fun BBC pe o ti to nnkan bii ọdun meje ti oun ati ọkunrin naa ti n ba ere ifẹ wọn bọ ki wọn to ṣe igbeyawo.

O ṣalaye pe inu oun dun nigba to ni oun fẹ gbe ẹlomiran niyawo lọjọ kan naa, ati pe ko jẹ ohun iyalẹnu fu oun nitori oun ti mọ tẹlẹ pe ọkunrion naa fẹran obinrin.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ kan naa lo gbe awọn obinrin mejeji niyawo, kii ṣẹ ile kan naa ni wọn n gbe.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Evelyn ni "kii ṣe ile kan naa ni gbogbo wa n gbe, nigba miran ọkọ wa le lo ọsẹ kan lọdọ mi, lẹyin naa ni yoo lọ lo ọsẹ kan miran pẹlu iyawo keji."

"Ko fi iya kankan jẹ mi, gbogbo ohun ti a fẹ lo n ṣe fun wa, idi ree ti ko fi si ija laarin awa iyawo mejeji."

O sọ siwaju si pe eeyan daadaa ni ọkunrin ọkọ awọn, ati pe oun ko ni binu to ba sọ pe oun tun fẹ gbe ẹlomiran ni iyawo lọjọ iwaju.

Ni ti iyawo keji, Famous Faith, to jẹ ẹni ọdun mẹrindilọgbọn, o ni ọkọ oun n tọju oun daadaa, oun ko si binu pe o ni obinrin miran nitori ohun to wu lati ṣe ni.

Ọkunrin oniyawo meji naa sọ pe N120,000 ni oun san gẹgẹ bii owo ori iyawo fun ẹbi awọn iyawo oun mejeji.

Àkọlé fídíò, Ikorodu cult crisis:A máa gbé Orò síta lọ́jọ́kọ́jọ́ tí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn bá tún ṣẹlẹ̀- Àwọ

O pari ọrọ rẹ pe ọwọ kan naa ni oun fi mu awọn mejeji, oun ko si ṣe ojuṣaju laarin wọn.

Lẹyin naa lo ni ko si ẹnikẹni to kan an nipa fun oun lati fẹ iyawo meji, o wu oun lati ṣe bẹẹ ni, o si dun mọ oun ninu.