Seyi Makinde: Ìjọba Oyo ní ètò fún àwọn òṣíṣẹ́ BCOS kó tó bẹ̀rẹ̀ sí ń wó iiléègbé wọn - Alága iléeṣẹ́ náà

Ọpọlọpọ awuyewuye lo rọ mọ ileigbe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ipinlẹ Ọyọ, BCOS, lẹnu ọjọ melo kan si asiko yii.
Bi iroyin kan ṣe n sọ wi pe Gomina Ṣeyi Makinde dede ko awọn katakata wọn inu ọgba ileeṣẹ naa lai sọ fun wọn tẹlẹ ni iroyin mi i tun sọ wi pe awọn alakoso ileeṣẹ naa mọ si igbesẹ naa.
BBC Yoruba ṣe abẹwo si ileeṣẹ naa ni owuro ọjọ Ẹti, a si ri i daju wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ si ni wo awọn ile kan to jẹ ileegbe awọn oṣiṣẹ BCOS.
Alaga ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ipinlẹ Ọyọ, BCOS, Alagba Dọtun Oyelade ṣe alaye fun akọroyin wa pe, o to bi i ipade mẹrin ọtọọtọ ti wọn ba awọn olori oṣiṣẹ labẹ aburada RATTAWU ati NUJ ṣe, lẹyin eleyii ti ijọba ipinlẹ Ọyọ tun ba wọn ṣe ipade pọ bi i ẹmeeji si ẹmẹẹta lori ọrọ naa.

Oyelade ni, "Eyii to jẹ okodoro ọrọ ni wi pe ijọba fẹ lo awọn aye to ṣẹku lẹyin ọdọ wa ni."
"Ijọba naa lo kuku ni ilẹ, wọn fẹ lo o lati fi ṣe agbekalẹ ile akọta ti Oyinbo n pe ni Estate, ijọba wa pa idi apo pọ pẹlu ẹnikan ti yoo gbe owo silẹ ti yoo si kọ ọ."
O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo fi ọwọsọwọpọ pẹlu ile iṣẹ adani naa ti akanṣe iṣẹ naa yoo fi yọri ti wọn a si ta a.
Alaga ileeṣẹ naa tẹsiwaju pe pupọ ninu awọn ileigbe awọn oṣiṣẹ naa lo ti di ile atijọ ti ko si dun un wo lọju mọ.

O ni, "Wọn ti gbo si ara, igbo ti bo wọn, paanu mii ti ja, ferese omii ko si nibẹ mọ, ẹ o le mọ pe eeyan n gbe ibẹ."
O ni awọn ti parọwa si ijọba lati ma wo gbogbo ileigbe naa nitori pupọ ninu awọn oṣiṣẹ naa lo n ṣiṣẹ mọju.
- Ẹlẹ́wọ̀n tó pẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n jùlọ ní Amerika gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn ọdún 68 lẹ́wọ̀n
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ibi ọmọ níí ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ ọmọ láyé? Kínni pàtàkì ibi ọmọ?
- Wo àwọn 'App' tó ń ba fóònù jẹ́ ní Nàìjíríà
- Baba Ijesha kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lòpọ̀
- Àwọn olórí orílè-èdè ilẹ̀ Áfíríkà mẹ́fà tó rọ́pò òbí wọn gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.
Oyelade ni ijọba ti yọnda awọn aaye kan fun iru awọn oṣiṣẹ bẹẹ, bakan naa ni wọn yọnda mọṣalaṣi ati ṣọọṣi to fi mọ gbọngan awọn oṣiṣẹ fẹyinti.

O tẹsiwaju pe ijọba to wa lode ki i ṣe ijọba ika, eyii lo mu ki wọn fun awọn oṣiṣẹ to n gbe ile naa ni oṣu mẹta lati wa ile mii, bẹẹ sini ijọba yoo fun gbogbo wọn ni owo ile ọdun kan.
Oyelade ni ko si olugbe kankan ninu awọn ile ti ijọba ti bẹrẹ sini wo bayii.
O pari ọrọ rẹ pe awọn ile ti ko si ẹnikẹni ninu rẹ ni ijọba kọkọ bẹrẹ sini wo l'Ọjọbọ.














