Idriss Déby Itno funeral pictures: Wo bí ètò ìsìnkú Aàrẹ Chad àná, Idris Deby ṣe ń lọ

Oríṣun àwòrán, AFP
Eto isinku Aarẹ orilẹ-ede Chad ana, Idris Deby ti n lọ lọwọ.
Ṣaaju ni awọn olori ẹgbẹgun ọlọtẹ ti kọkọ dukoko mọ awọn adari ijọba ilẹ okeere to fẹ peju sibi eto isinku naa lati maṣe yọju.
Ogunjo, oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ni Deby jade laye lẹyin to fara gbọta ibọn loju ija pẹlu awọn ọmọ ogun ọlotẹ.
Ẹni ọdun mejidinlaadọrin ni Deby ko to jade laye.
Wo awọn aworan eti isinku Aarẹ Idriss Déby Itno

Oríṣun àwòrán, AFP
Aarẹ mali ati Guinea ti kalẹ sibi ti eto isinku naa yoo ti waye.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ orilẹ-ede France, Emmanuel Macro ti ṣetan lati tẹkọ leti lọ si Ndjamena bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ogun ọlọtẹ ti kilọ fun awọn adari orilẹ-ede miran lati maṣe yọju sibi eto isinkun ọhun.

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, EPA
Ọdun 2016 ni Deby jawe olubori ninu eto idibo to gbe wọle fun saa karun un.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun 2018 ni ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede naa ṣe agbeyẹwo ofun wọn, eyii to faye gba Deby lati dije fun saa kẹfa.













