EKSU Ekiti workers crisis: Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ EKSU ti ní kí wọ́n gbé ilé ẹ̀kọ́ náà tì pa

Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ Eksu ti ní kí wọ́n gbé ilé ẹ̀kọ́ náà tì

Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ fasiti Ekiti, tí ní kí wọ́n gbé ilé ẹ̀kọ́ náà tì pa lóní wàràǹsesà.

Bákan náà ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ ọ̀hún tún ni òun kò fọ̀wọ́ sí ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kankan ni il'é ìwé náà tó fi mọ́, ASUU, NASU, SSANU, NAAT.

Àtéjáde tó jẹyọ láti ọwọ́ agbẹnusọ ilé ìwé náà Bode Olofinmaugun ló fẹ̀sùn kan pé òun fura pé àwọn kan dìde láti da ètò ẹ̀kọ́ rú ni ilé ìwé náà tí wọ́n sì ń fi ẹ̀mí àti dúkíà àwọn ènìyàn sínú ewu láti bi ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn.

Ẹ̀wẹ̀, ó rọ gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ láti kúrò nílé ẹ̀kọ́ ní kíákíá.

Sáájú ni ìpàdé laáárìn àwọn ìgbìms olórí ẹgbẹ́ òsìṣẹ́ ilé ẹ̀ka náà àti àwọn ìgbìmọ́ aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà forí sọ́pọ́n, bí àwọn asójú ẹgbẹ́ tó wá fún ìpàdé náà ṣe bínú jáde kúrò nínú ìpàdé ọ̀hún bí wọ́n ṣe kọ̀ látiṣe ǹkan tí wọ́n ń bèèrè fún.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ìròyìn tún fi yé ni pé, àwọn èèkàn mííràn tó tí bá gómìnà ṣe ìpàdé pẹ̀lú bínú jáde nínú ìpàdé náà nítórí bi gómìnà ṣe fi ààké kọ́rí lórí ọ̀rọ̀ náà tó sì ks láti ṣe ǹkan tí wọ́n ń fẹ́, lára rẹ̀ ní owó oṣù mẹ́tà tí wọ́n jẹ lọ́dún 2019, owó oṣù mẹ́rìnlá tí wọ́n yọ nínú owó oṣù ati owó ìfẹ̀yìn tì.

Àkọlé fídíò, Budo Ikoko water problem: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu

Àwọn olórí òṣìṣẹ́ ní ilé ìwé náà lásìkò tí wọ́n ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn kò ní sinmi ìfẹ̀hónú hàn títí tí ìjọba yóò fi ṣe ǹkan tí àwọ́n ń fẹ́.

Bákan náà ní wan bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbìmọ̀ aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà tí kò le san àwọn owó tí wọ́n yọ nínú owó oṣù pàda láti ọdún 2018.

Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ Eksu ti ní kí wọ́n gbé ilé ẹ̀kọ́ náà tì
Awọn oṣiṣẹ lẹnu iloro fasiti EKSU

Oríṣun àwòrán, Roundoffnews

Àwọn òṣìṣẹ́ fásitì EKSUK gbé iléèwé tì pa nítorí àjẹẹ́lẹ̀ owó oṣù, àjẹmọ́nú

Nnkan ko rọgbọ ni saa yii ni fasiti ipinlẹ Ekiti, EKSU pẹlu gbọnmọgbọnmọ wahala oṣiṣẹ nibẹ.

Lọwọ yii awọn oṣiṣẹ fasiti ipinlẹ Ekiti ko tii jami lori iyanṣẹlodi ati iwọde ti wọn n gunle nibẹ lati beere fun awọn ajẹẹlẹ owo oṣu wọn kan eyi ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ nibẹ ni awọn n beere fun.

Ẹnu iloro ọgba fasiti naa to yẹ ko jẹ abawọle sinu awujọ ikẹkọọ ni wọn ti sọ di ibudo igbafẹ nibi ti wọn ti gba awọn onilu ti wọn si n jo.

Oniruuru orin ọtẹ ati eebu lo n gbode nibẹ ti wọn n kọ tako ijọba ipinlẹ naa atawọn alaṣẹ fasiti ọhun, ti awọn oṣiṣẹ naa si n jo lati wọde fun ajẹẹlẹ owo oṣu ati ajẹmọnu gbogbo ti wọn n beere fun.

Iwọde wọn yii ko jẹ ki ohunkohun tabi ẹnikẹni wọle tabi jade lẹnu iloro ileewe naa to si ti mu ki ẹkọ kikọ.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ fasiti naa, Ọgbẹni Azeez Aguda to ba awọn oniroyin abẹle kan sọrọ ṣalaye pe ohun ti wọn n ja fun ni sisan ajẹẹlẹ owo oṣu wọn fun oṣu ikeje, ikẹjọ ati ikẹsan ọdun 2018.

Wọn tun n beere fun dida owo alajẹṣẹku kọpuretifu ati owo ifẹyinti wọn pada, igbayegbadun awọn oṣiṣẹ ati dida awọn oṣiṣẹ ti wọn ys niṣẹ pada.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa