Baby Placenta: Ṣé lóòtọ́ọ́ làwọn kan máa ń fi ibi ọmọ ṣe oògùn?

Olubi ọmọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoruba ni tibi-tire la wale aye, tibi-tire la se ẹda eeyan, bi aye ire se wa, naa ni aye ibi se wa.

Ni ọjọ ti obinrin ba ti kunlẹ bimọ, ti ọmọ jade eyi tii se ire, naa ni olubi ọmọ yoo jade, eyi ti wọn tun n pe ni ibi ọmọ tabi Placenta ni ede oyinbo.

Ni aye atijọ, olubi ọmọ yii se pataki fun ibi ọmọ, baba to ba si gba olubi ọmọ tabi sin bo se yẹ, ni asa Yoruba mọ bii baba ọmọ.

Baba ọmọ lo maa n gbe olubi ọmọ ni kere ti ọmọ ba ti bọ lara iya ọmọ tan.

Olubi ọmọ tawọn kan maa n pe ni ibi ọmọ jẹ ohun to ṣe pataki laarin oriṣiiriṣii ẹya lorilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Ki ni pataki Olubi ọmọ?

Ko si ọmọ ti kii ni olubi, nitori ohun gan ni atẹle to n ba ọmọ wa sile aye.

Sugbọn oniruuru ọrọ ni awọn eeyan maa n sọ nipa pataki olubi ọmọ, eyi to yẹ ki olukaluku mọ boya o tọ abi ko tọ.

Dokita Joseph Akinde, to jẹ onimọ nipa itọju awọn alaboyun ṣalaye pe igbagbọ wa ninu aṣa ibilẹ lasan, ni ohun ti ọpọ eeyan maa n sọ nipa olubi ọmọ.

Dokita Akinde sọ pe awọn kan tiẹ ni igbagbọ awọn eeyan kan wipe ibi ọmọ ni ohun ṣe pẹlu ayanmọ ọmọ naa laye.

Se lootọ ni ayanmọ ọmọ ni nnkan se pẹlu olubi ọmọ?

Akinde salaye pe ''Igbagbọ awọn eeyan ni pe ohunkohun ti ẹnikẹni ba ṣe pẹlu ibi ọmọ ni nnkan ṣe pẹlu ohun ti ọmọ naa yoo da laye.

Ṣugbọn a ko le fidi eleyi mulẹ ninu iṣẹ iṣegun tabi ninu imọ ijinlẹ sayẹnsi, igbagbọ ninu aṣa lasan ni,'' Dokita Akinde ṣalaye.

Amọ dokita onimọ nipa itọju obinrin naa sọ pe, dokita ti ko ri ibi ọmọ gbe fun baba ọmọ ti wọ gau.

Wọn ni ọpọ awọn dokita ni wọn ti dunkoko mọ lori ibi ọmọ, koda wọn sọ pe awọn eeyan maa n gbe dokita lọ si ileẹjọ lori órọ ibi ọmọ.

Amọ, Dokita Akinde ṣalaye pe aṣa lasan an ni gbogbo rẹ, ko ni ohun kan ṣe pẹlu sayẹnsi.

Àkọlé fídíò, Segun iberu

Wo igbagbọ awọn eeyan lori olubi ọmọ, ti wọn se maa n fẹ gba a nile iwosan:

Nigba to n salaye oniruuru ọna ti awọn eeyan fi ni igbagbọ ọtọọtọ si pataki ohun ti ibi ọmọ jẹ, Dokita Oyede tun sọ iriri rẹ lori bi awn obi se n lakaka lati gba ibi ọmọ kuro nile iwosan.

''Awọn eeyan kan maa n bo olubi ọmọ mọlẹ, igbagbọ wọn ni pe ibikibi ti ọmọ naa ba wa, o gbọdọ de ibi ti wọn ri ibi rẹ mọ lọjọ kan.

Awọn mii tun gbagbọ pe wọn maa n fi olubi ọmọ ṣe oogun, idi niyii ti wọn maa fi n gbaa lati ile iwosan.

Mo ranti ni bii ọdun diẹ sẹyin bi ẹbi obinrin kan to bimọ si ile iwosan ijọba ṣe dunkoko mọ dotika to gbẹbi fun obinrin naa nitori ko mọ ibi ti ibi ọmọ wa.

Niṣe lawọn ẹbi naa lọ sọ fawọn akọroyin pe dokita naa ti ta olubi ọmọ awọn, o si ti ta ayanmọ rẹ laye,'' Dokita Akinde lo sọ bẹẹ.

Alaga ẹgbẹ awọn dokita oniṣegun oyinbo nipinlẹ Cross River, Dokita Innocent Abang naa kin ọrọ Ọgbẹni Akinde lẹyin.

Dokita Abang ni ọpọ lo gbagbọ pe ibi ti wọn ba ri ibi ọmọ si ni ayanmọ rẹ wa.

Dokita sọ pe awọn tiẹ maa n gbin igi agbọn sori ibi ti wọn ba ri ibi ọmọ si, ''wọn gbagbọ pe bi igi naa ṣe n dagba ni ọmọ naa yoo maa dagba.''