Sperm Implant: Gbígba àtọ̀ ọkùnrin ní ọ̀fẹ́ ń ṣèrànwọ́ fáwọn obìnrin láti dá oyún ní

Oríṣun àwòrán, Mam Issabre
Ni aye atijọ, igbagbọ awọn eeyan ni pe ko seese fun obinrin lati bi ọmọ lai jẹ pe o sun ti ọkunrin kan.
Iru ọkunrin bẹẹ le jẹ ọkọ rẹ to ba se igbeyawo tabi ọkunrin miran.
Amọ nibayii, ọpọn ti sun siwaju nitori ọpọ awọn ilana igbalode kan ti wa eyi to le mu ki obinrin yan lati bi ọmọ lai sun ti ọkunrin kankan.
- Ọmọ to n ko ọmọ alainile kuro lori titi
- Ileewosan gba ọmọ silẹ nitori airowo san
- Ọmọ ìyá méjì gé orí ọmọ ọdún mẹ́wàá l'Eko
- Ọkọ mi pa ọmọ wa mẹ́ta, o kó òkú wọn sínú fírísà - Milliscent Amadikwa
- Ìdí tí mo fi jú ọmọ mi ọmọ ọdún méjì látorí ilé gogoro sílẹ̀
- 'Orí ló kó ọmọ mi yọ'
- Ọ̀mùtí ọmọ Nàìjíríà kábàmọ̀ ní Russia
- Wo ohun tí Pasuma sọ nípa Opeyemi, ọmọ rẹ tó di ọmọ ogun orí omi l'Amẹrika
- Aworan aṣa ati iṣe awọn ọmọ Yoruba
Ilanaa naa si lo da lori fifi atọ ara ọkunrin sinu ẹyin ile ọmọ obinrin lai jẹ pe takọ tabo sun ti ara wọn lati bi ọmọ sile aye.
Bawo ni awọn obinrin se n ri atọ ti wọn n lo lati bimọ?
O le ni ida aadọta awọn obinrin jakejado agbaye bayii, ti wọn ko ni ọkọ amọ ti wọn gba lati jẹ ki wọn fi atọ ọkunrin si ile ọmọ awọn, eyi ti yoo di oyun.
Irufẹ awọn obinrin yii lo ti pinnu lookan aya wọn lati da oyun ni, da ọmọ bi, ki wọn si da ọmọ wo, lai ni ajọsepọ pẹlu ọkunrin kankan tabi gbe ara le wọn.
Gẹgẹ bii abọ iwadii kan ti ileesẹ to n fi atọ ọkunrin pamọ to tobi julọ ni agbaye, Cryos International se wi, awọn irufẹ obinrin naa ni ko ni ohunkohun se pẹlu ọkunrin, ki wọn to bimọ.
O le ni ọgọrun miliọnu obinrin ti ko ni ọkọ, to n da tọ ọmọ:
Akọsilẹ ileesẹ Cryos, to n pese atọ ọkunrin ati ẹyin obinrin to ti di bii yinyin sita fun ilo awọn orilẹede to le ni ọgọrun lagbaye lo sisọ loju eleyi.
Cryos safihan rẹ pe alekun ti ba iye awọn obinrin ti ko ni ọkọ to n gba atọ ọkunrin sara lati bi ọmọ.
Lati ọdun meje sẹyin, si ni ele ti ba iye awọn obinrin to n da beere fun atọ ọkunrin naa lọ si ida mẹrinlelaadọta ninu ọgọrun.
Gẹgẹ bi ajọ isọkan orilẹede agbaye, United Nations ti wi, alekun iye awọn obinrin naa bẹrẹ lati ọdun 2020.
Akọsilẹ si fihan pe o le ni ọgọrun awọn obinrin ti ko ni ọkọ, amọ ti wọn n da tọju awọn ọmọ ti wọn bi lai si iranwọ kankan lati ọdọ awọn ọkunrin.
Ẹ wo ero awọn obinrin to n da bi ọmọ lai si iranwọ ọkunrin:
Imọran to tii dara julọ ni aye mii niyi:
Obinrin kan lati orilẹede Faranse, Mam Issabre ni ala oun lati bimọ lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin ti oun ti n ronu nipa rẹ, lo wa si imusẹ.
O ni lọdun meji sẹyin ni oun pinnu lati loyun lai sun ti ọkunrin, ti oun si n da tọju ọmọ oun lai si iranwọ ọkunrin kankan.
"Mo ba iya mi jiroro nipa ọrọ yii, to si gba mi nimọran pe mo le ra atọ ọkunrin lati bimọ.
Ẹni ọdun mejidinlogoji ni mo wa nigba ti mo gbe igbesẹ naa, inu osu Kejila ni mo se ipinnu naa, ti mo si ni oyun ni osu Keji ọdun to tẹle."
Obinrin naa di iyalọmọ lẹyin osu mẹsan, to si sọ orukọ ọmọ rẹ ni Imany amọ o salaye pe o nira lootọ nibẹrẹ nitori awọn ofin kan to rọ mọ ọmọ bibi.
"Wọn kii fun awọn obinrin alaboyun ti ko ba ni ọkọ ni itọju lorilẹede Faranse lasiko naa, ti dokita mi si ni ki n lọ si orilẹede miran lati se ohun ti mo fẹ se."
Amọ lẹyin o rẹyin, o se alabapade dokita kan to ba gbe atọ ọkunrin to ra sinu ile ọmọ rẹ, eyi to di oyun ọmọ to bi.
Mo ta ile ti mo n gbe, mo si gba owo ifẹyinti mi ti gbogbo rẹ jẹ $95,000 lati da nikan bimọ:
Anne Marie Vasconcelos, tii se ẹni ọdun mẹrinlelogoji bayii ati ọmọ ijọ Katoliki tootọ, lo wa lati ipinlẹ New Jersey, lorilẹede Amẹrika.
O ni oun ni arun kan ni ọdun mẹwa sẹyin, eyi to se akoba fun ile ọmọ oun, ti isoro si wa lati bimọ, ti dokita si ni ko si ireti fun oun lati bimọ amọ oun le beere fun ọmọ.
Anne, tii se ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn nigba naa salaye pe ko wa si ero oun rara pe oun le bimọ lai lọwọ ọkunrin ninu rara.
"Mo ba alufa ijọ mi sọrọ naa, o si sọ fun mi pe mo si le jẹ Kristiẹni tootọ ti mo ba gbe igbesẹ naa bi o tilẹ jẹ pe ko fara mọ pe ki wọn gbe atọ ọkunrin sinu ile ọmọ mi.
Amọ o salaye pe oun ko le fi ẹsun kankan kan emi ati ẹbi mi, eyi si fi mi lọkan balẹ pupọ.
Igba marun ni wọn gbiyanju lati gbe akọ ọkunrin sinu ile ọmọ mi, ti wọn si tun se isẹ abẹ fun mi ni igba meji, ko to di pe mo bi akọbi mi.
Apapọ owo ti mo na lori igbesẹ naa jẹ ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrun Dọla nitori igbesẹ naa ko si lara ilana eto ilera adojutofo ti mo n lo.
Nitori naa ni mo se ta ile mi, gba owo ifẹyinti ti mo da pamọ, ti mo si tun ko gbogbo owo ajẹsẹku mi le lori pẹlu."

















