Akanṣe awọn aworan aṣa ati iṣe awọn ọmọ Yoruba

Awọn ọmọ Yoruba fẹran wiwọ Asọ oke fun ayẹyẹ, bẹẹsi ni ọja alẹ wọpọ lawọn agbegbe ti wọn ti n sọ ede Yoruba:

Awon eleyo n jo larin ilu - 3/12/2017

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọdọọdun ni wọn ma n sọdun Eyo ni ipinle Eko
Aworan ere to wani ojubo Osun-osogbo ni ipinle Osun - 19/8/2016

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọdun Ọsun-Osogbo jẹ gbajugbaja ni ipinlẹ Ọsun, to ma n waye losu kẹjo ọdun
Ọmọkunrin n fọ ọri rẹ sinu odo Ọsun-Osogbo - 19/8/2016

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọgọọrọ eniyan lo ma n wa si ojubọ naa lati bere ẹdun ọkan wọn lọwọ yeye Ọsun
Omokunrin hun Aso-Oke - 1/2/2018
Àkọlé àwòrán, Lorilẹede Naijiria, Ilu isẹyin loni Aso-Oke. Ati ọmọde ati agba lo mu u bi iṣẹ nilu naa
Okunrin kan joko pelu ilu gangan lowo re ati awo ilu yii ka - 1/2/2018
Àkọlé àwòrán, Ilu Ọyọ ni ojulowo Ilu gangan nilẹ Yoruba. Ọkan lara awọn onilu Alafin Ọyọ loun bẹ ninu aworan yi.
Ọja ti won ti n ta elubo pelu awon eniyan nunu oja - 31/1/2018
Àkọlé àwòrán, Oja bẹrẹ nibi ti wọn ti n ta elubọ - ojulowo ọmọ ilẹ Ibadan kii fi ọka ati gbẹgiri pẹlu eweedu ṣere
Oja ale ni lu Ibaban - 31/1/2018
Àkọlé àwòrán, Ọja alẹ wọpọ nilẹ Yoruba gẹgẹ bi o ṣe wa laye atijọ - ero witiwiti lo maa n yọju sibi ọja alẹ lati ra nkan ọbẹ
Ijapa to ti le ni odun 343 lafin Soun tilu Ogbomoso - 2/2/2018
Àkọlé àwòrán, Ijapa yi ni wọn n pe ni Alagba. O tiwa ni aafin Ọba Soun tilu Ogbomọṣọ lati ọọdunrun ole mẹtalelogoji ọdun (343years old)
Aworan arakunrin kan l'ẹgbẹ ere kan to sun mọ odo Ọsun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Arakunrin kan duro si ẹgbẹ ere kan to sun mọ odo Ọsun. Ẹgbegberun eeyan lo man se ayeye ọdun Ọsun ti wọn si man sure fun ọmọ bibi ati orire.
Aworan obo kan soso to wa nibi igbafe Ikogosi - 3/2/2018
Àkọlé àwòrán, Ọbọ yi lo ṣeku sibi igbafẹ ilu Ikogosi, lẹyin ti ijọba ologun paṣe pipa awọn ẹranko to wa nibẹ, lẹyin ti kiniun ṣe'kupa arinrinajo to wa gbafẹ.
Aworan igi to wa ni ona igbafe Ikogosi - 3/2/2018
Àkọlé àwòrán, Ikogosi ni ipinlẹ Ekiti jẹ ọkan lara awọn ibudo igbafẹ towa nilẹ Yoruba nibiti ọpọlọpọ awọn arinrinajo maa n ṣe abẹwo si lojoojumọ
Ere okunrin kan ton fo okuta ni oju ona adugbo Oke Aregba ni igboro Abeokuta, ni ipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ere okunrin kan ton fo okuta ni oju ona adugbo Oke Aregba ni igboro Abeokuta, ni ipinlẹ Ogun
Aworan odo ti won ko ti ki n pa eja ni Erijiyan Ekiti - 3/2/2018
Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan kii pa ẹja ni Odo Erin nilu Ẹrijiyan Ekiti nitori igbagbọ wipe ẹja inu odo yi, kii jina bi o tile wu ki wọn se e to
Omi onipele meje(waterfall) ni llu Ikogosi - 4/2/2018
Àkọlé àwòrán, Omi arinta oni ipele meje wa nilu Ipọle-iIoro-Ekiti. Amọ ipele ikeji sikẹta ni awọn arinrinajo ti o ba ṣe abẹwo sibẹ tin pada.

Aworan yi wa lati ile-isẹ iroyin BBC.