Aládúgbò ti ọmọ Nàìjíríà jábọ́ látorí ilé alájà méjì

Àwọn olùgbé ilé kan ní àgbègbè Brusilov ní orilẹ̀èdè Russia kó sínú ìdàrúdàpọ̀ lọ́jọ́ àbámẹ́ta lẹ́yìn tí ẹnì kan ti ọmọ Nàìjíríà tó mu ọtí yó bọ́lẹ̀ láti orí ilé alájà méjì.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn eré ìdáraya orílẹ̀èdè Russia se sọ ọ́, arákùnrin náà, Tolulọpẹ Akindi ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n wá sí Russia láti wá wó ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ife ẹ̀yẹ àgbáyé ni.
Ìwé àtẹ̀jáde mìí, Telegram channel Mash sọ pé ọmọ Nàíjíríà ọ̀ún ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí láti mu tó sì mu ú yó kẹrí, ó bọ́ sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin sókè tantan pẹ̀lú ijó níwájú ilé tirẹ̀ tó wà ní àjà kejì.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ sọ pé àwọn alábágbé rẹ̀ rọ̀ ọ́ pé kó fara balẹ̀ sùgbọ́n ó kọ etí ikún sí wọn. Èyí ló fà á tí ọ̀kan nínú wọn tì í síta látojú fèrèsé àjà kejì náà.
Akindi jábọ́ ó sì fara pa sùgbọ́n ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí tí ó sì ṣèse ní ẹsẹ̀ méjèèjì.








