Marcus the Pig: Kini ẹlẹ́dẹ̀ aríran fi ṣẹ Naijiria?

Ibikíbi tí àwọn olówó ẹlẹ́dẹ̀ arríran tí a mọ̀ sí Marcus the Pig bá wà, wọn ni láti forípamọ́ bayìí nítori àwọn ọmọ Naijiria ń wá ẹlẹ́dẹ̀ nàá lẹ́yin ifẹsẹ̀wọn ti alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Ní orí Twitter, àwọn eniyan kò mẹ́nu kúrò lórí ọ̀rọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ nàá nítóri wọ́n ní oun ni ó ríran pé Naijiria wà lára orílẹ̀ede mẹ́rin tí yóò wọ ipele kejì sí àsekágbá ife ẹ̀yẹ̀ àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́ ní Russia.
Àwọn kan tilẹ̀ ní àwọn fẹ́ pá a jẹ bi àwọn kan ṣe ní àwọn fẹ́ fi ṣe àsun lẹ́yìn tí àwọ agbábọ́ọ̀lù Croatia fi ojú ikọ̀ Super Eagles gbolẹ̀ pẹ̀lú àmì ayo mẹ́jì sí òdo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3

End of X post, 4
Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si:
Sugbọn báwo ni ẹlẹ́dẹ̀ ṣe ń ríran?
Wọ́n kó èso méjìlélọ́gbọ̀n sílẹ̀ tí ó dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀èdè tó ń díje nínú ife ẹ̀yẹ̀ àgbáyé.
Ẹlẹ́dẹ̀ náà jẹ méjìdínlọ́gbọ̀n nínú èso náà, ó sì fi mẹ́rin sílẹ̀ nínú èyí tí orílẹ̀èdè Naijria wà lára wọn.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ti ṣe sẹ́yìn
Wọ́n ní òun ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Àarẹ orílẹ̀èdè Amerika, Donald Trump yóò borí nígba ìdìbò 2016.
Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Brexit ati àwọn èsi ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ mìíran tẹ́lẹ̀.
Ẹlẹ́dẹ̀ nàá tó jẹ́ ọdun mẹ́jọ wà ní Derbyshire ní Ìlẹ̀ Gẹ̀ẹ́si. Olówo rẹ̀ ni arábinrin kan ti orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Juliette Stevens.