World Cup 2018: Croatia na Super Eagles pẹlu ami ayo 2 - 0

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ Croatia ti fagba han ikọ Super Eagles lẹyin ti wọn na wọn pẹlu ami ayo meji si odo.
Ọmọ ile Nigeria, Etebo lo gba bọọlu wọ inu awọn leyin ti ọmọ ile Croatia Mandzukic ati Luka Modric gba bọlu pẹlu ori rẹ
Ni isẹju mọkandinlaadọrin ni Luka Modric gba bọọlu kọjú-sími-gbáa-sílé wọ inu awọn leyin ti William Troost-Ekong ti Naijiria se asẹmase ni oju ile.
Ikọ Super Eagles to wa ni isọri Kerin pelu Argentina, Iceland ati Croatia yoo ma koju Iceland ni Ọjọ Ẹti, ọsẹ to n bọ.
Ifẹsẹwọnsẹ miran to waye ni Ọjọ Satide
Ni isọri kẹta, ikọ France na ikọ Australia pẹlu ami ayo meji si odo.
Nigbati ikọ orilẹede Denmark bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ alakọkọ pẹlu ikọ Peru ninu idije Ife Ẹyẹ Agbaye ti Russia 2018 pẹlu ami ayo eyokan si odo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
France yoo ma a fẹsẹwọnsẹ pẹlu orilẹ-ede Peru ni Ọjọbọ ọsẹ to n bọ, nigba ti Australia yoo ma a koju Denmark.Nni isori kerin, iko argentina ati iko iceland gba ami ayo eyokan si eyokan
Argentina ni ireti pe wọn a tun gbiyanju nigba ti wọn ba n fẹsẹwọnsẹ pẹlu orilẹ-ede Croatia ni Ọjọbọ ọsẹ to n bọ, nigba ti Iceland yoo ma a koju Nigeria.














