Domestic Accidents and Death: Àwọn èròjà inú ilé kan rèé tó le rán èèyàn sí ọ̀run láìròtẹ́lẹ̀

Aworan obinrin to ba ọkan jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ eeyan lo ti padanu ẹbi wọn lati ipasẹ iku ojiji ti eroja inu ile se okunfa rẹ

Yoruba bọ, wọn ni a kii joko sile ka fi ẹsẹ rọ. Amọ ṣa, ti ọrọ ba kan awọn nnkan elo kan ninu ile, ọpọ ni nnkan to ju fifi ẹsẹ rọ lọ ti sẹlẹ si.

Koda ẹmi ti bọ latara lilo awọn nnkan wọnyii, ti ọpọ eeyan si ti di alaabọ ara pẹlu.

Eyi si lo n fi ye wa pe aarin ewu la n gbe, inu ewu gan la si wa, ko si di igba ta ba jade sita ka to bọ sinu ewu, ewu n ba wa sun, koda, o tun n ba wa ji ni pẹlu.

Awọn isẹlẹ iku ti eefin ẹrọ amunawa lasan ninu ile sokunfa bo se mu ẹmi wọn lọ:

Ni ọpọlọpọ igba la maa n gbọ iroyin nipa awọn eeyan ti wọn dero ọrun latara bi eefin ẹrọ amunawa ṣe ṣeku pa wọn.

Wọn si n ṣe aajo ki wọn ri ina tan lẹyin igba ti ina ọba lọ, lọrọ ba di mo ha mọ.

Ajalu kanna tun waye nipinlẹ Osogbo lọjọ kọkandinlọgbọn Osu kọkanla ọdun 2018, nibi ti eniyan mẹta ninu idile kan to n gbe ni agbole Olorisaoko ni Osogbo ni Ipinlẹ Osun ti gbẹmii mi.

Eefin ẹrọ amunawa lo pa sajẹnti ọlọpaa to jẹ́ olori ẹbi naa ati awọn ẹbi rẹ.

Lọdun 2014, ajọ aladani kan ti orukọ rẹ n jẹ 'Good Governance Initiative' so pe o to ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to salabapade iku ojiji lọwọ eefin.

Ṣugbọn o wa yẹ ko ye wa pe kii ṣe eefin ẹrọ amunawa nikan lo n ṣe ijamba fun ẹmi ninu ile.

Akọṣemọṣẹ oniṣegun kan to mọ nipa iṣẹlẹ pajawiri Dokita Anthony Mgbolu sọ pe ti afẹfẹ buruku ba wọ inu ọna ọfun lọ, yoo sẹ akoba fun ọpọlọ eroja ara, ti eleyii yoo si mu ki ẹni naa ma le mi mọ.

Mgbolu wa salaye awọn nnkan maarun to yẹ ki a maa sọra fun, bi a ti ṣe n lo awọn eroja naa ninu ile.

Àkọlé fídíò, Oyetola, Aregbesola àti Tinubu ni ọ̀rọ̀ náà wa láàrin wọn

Eroja inu ile marun to le se okunfa iku ojiji:

Ogun apakokoro (Insecticide)

Aworan ogun apakokoro ẹfọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Fifin oorun awọn ogun apakoro paapa ju ti ẹfọn ninu ile le sakoba fun ara

Laipẹ yii la gbọ iroyin bi awọn ọmọ mẹta kan ṣe di ero ọrun lẹyin ti iya wọn fin ogun apẹfọn sile.

Eefin ti awọn ọmọ naa fin si imu lo ṣeku pa wọn.

Dokita Mgbolu ṣalaye pe kẹmika to wa ninu ogun apẹfọn ti orukọ rẹ n njẹ "Organophosphate" buru pupọ, ti o si ma n ṣe akoba fun ẹni to ba ṣe alabapade rẹ.

O sọ pe "Ọpọlọpọ awọn ogun apakokoro ti wọn n ta ni ọja kọ lo yẹ ki a maa lo ninu ile. Wọn ṣe awọn miiran fun lilo ninu oko ni''

Eefin ẹrọ amunawa:

Aworan ẹrọ amunawa ni ṣọọbu aranṣọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Efin to n jade latara ẹrọ amunawa ti ran ọpọ lọ si ọrun

Carbon monoxide lorukọ ti awọn oloyinbo n pe eefin ti o ma n jade lati inu ẹrọ amunawa.

''Bi ẹni wi pe ara ran bọmbu lọwọ ni ti eeyan ba fin in si imu''

Dokita Anthony tun sọ wi pe ''ti eeyan ba mi afẹfẹ yii, eyi to yẹ ki a ma mi sita sinu, a maa ṣokunfa iku''

Ọpọ eeyan si lo ti gba oju oorun de oju iku nitori pe wọn mi eefin ẹrọ amunawa yii si imu lasiko ti wọn n sun, nibi ti afẹfẹ gidi ko ti ri aaye wọle si imu wọn.

Afẹfẹ Idana gaasi:

Aworan afẹfẹ gaasi idana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Afẹfẹ gaasi idana le mu ina dida ya amọ o le yara pa eeyan

O ṣeeṣe ki eefin gaasi naa ṣe iku pa eniyan ninu ile.

Ọna ti o le gba se eleyi kii se ki o gbana ṣugbọn ti eeyan ba fin in si imu, Dokita Anthony wi pe ''o le fa iku ti eeyan ko ba tete ri atẹgun aafin-simu lasiko.''

Ọda ikunle(Paint):

Aworan ile ti wọn n kun lọda

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi eeyan ba wọ inu iyara ti wọn ṣẹṣẹ kun lọda lewu

Igbiyanju eeyan lati fi ọda pa oju ile naa a maa ṣokunfa ijamba ninu ille gẹgẹ bi alaye Dokita Anthony.

''Eyi a maa jẹ aburu ti a ba joko sinu ile ti wọn ṣẹṣẹ kun tan, ti a si n fin eefin rẹ simu''

Kẹmika kan wa ninu ọda tuntun to jẹ wi pe o le fa iku ti eeyan ba fa si imu.

Epo ti a ba gba lori ina:

aworan epo pupa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Epo pupa

Iru efin epo ti a ba gba lori ina ni ile idana, ti eefin rẹ si gbalẹ kan, le ṣe akoba fun ẹmi.

''Iru awọn to ba ni aisan ''asthma'' ko gbọdọ fin eefin yii simu, bi bẹẹ kọ, o le ṣe akoba fun wọn''

Koda, iru epo gbigbona yii gan le gbana, ko si jo ile kanlẹ, ko si tun mu ẹmi lọ pẹlu.