Fuel scarcity: Ọ̀nà mẹ́sàn án tí o lè fi dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ ewu epo bẹntiróòlù nínú ilé rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kò sí àníàní pé bí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù ṣe ń bá àwọn ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fínra ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń ra tàbí gbèrò láti ra epo bẹntiróòlù sílé.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé epo bẹntiróòlù léwu láti máa gbe pamọ́ sílé nítorí ewu tó rọ̀ mọ àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn le má rìí ọgbọ́n dá si lásìkò yìí.
Lọpọ igba ni ile maan jo nitori pe awọn to n gbe irufẹ ile bẹẹ ra epo bẹntirolu pamọ sinu ile wọn.
Àwọn ọ̀nà mẹ́sàn án tó le gbà láti fi ṣe epo bẹntiróòlù rẹ̀ lọ́jọ̀ nìwọ̀nyí
- Ri dájú pé inú kẹ́ẹ̀gì ló ra epo bẹntiróòlù sí, ko sì gbé e jìnà sí orun tàbí ibi tiòòrùn bá pọ̀ sí; ibi tí afẹ́fẹ́ bá wà ló dára jùlọ.
- Má jẹ̀ ẹ́ kí èpò bẹntiróòlù dà sí ara rẹ, tí bẹntiróòlù bá ṣèṣì dà sí ara rẹ, lo aṣọ láti fi nù ún dáradára.
- Má lo ẹnu láti fi fa bẹntiróòlù nítorí ó léwu láti gbé e mì. Tí ó bá ṣèṣì gbemì, má gbìyànjú láti bì ní tipátipá dípò bẹ́ẹ̀ kàn sí dókítà fún àyẹ̀wò.
- Lo àrọ láti fi fa bẹntiróòlù ní gbogbo ìgbà, hóòsì náà ò dára láti fi fa bẹntiróòlù.
- Ṣọ́ra fún kí bẹntiróòlù máa da sí ara rẹ ní gbogbo ìgbà, kí o sì fi ọṣẹ àti omi fọ ibi tí ó bá dà sí.
- Ṣóra fún fífa ooru bẹntiróòlù símú.
- Ri dájú pé o fọ aṣọ tí bẹntiróòlù bá dà sí dáradára kí o tó tún un lò.
- Má ṣe lo bẹntiróòlù gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti nu nǹkan.
- To bá ra epo bẹntiróòlù sínú kẹ́ẹ̀gì, fi àyè díẹ̀ sílẹ̀ nínú kẹ́ẹ̀gì náà.








