Couple death: Ó ṣe! tọkọtaya yìí papòdà láàrín oṣù mẹ́sàn-án síra wọn

Tokotaya to doloogbe

Oríṣun àwòrán, @Odunukwe

Awayé kan kò sí, kò sí ẹni tí kò ní kú, kò sí ẹni tí ìta baba rẹ̀ kò ní dìgboro ṣùgbọ́n ọkàn ẹni a máa gbọgbẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́ tàbí ẹni tó bá súnmọ́ ni bá fi ayé sílẹ̀.

Omijé gbojú àwọn mọ̀lẹ́bí tí ọkàn wọn sì gbọgbẹ́ bí àwọn tọkọtaya Chukwuemeka Odunukwe àti Chineye tó papòdà láàárín oṣù mẹ́sàn-án síra wọn ní ìpínlẹ̀ Anambra.

Àwọn tọkọtaya náà ló ti ṣe ìgbéyàwó ní ìlànà ìbílẹ̀, tí wọ́n sì ń palẹ̀mọ́ fún ìgbéyàwó ní ìlànà ìgbàlódé kí ọlọ́jọ́ tó dé.

Bawo ni ọrọ ṣe jẹ?

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní Nnobi, ìpínlẹ̀ Anambra tó jẹ́ ìlú àwọn méjéèjì.

Àwọn mọ̀lẹ́bí tí ń gbèrò láti ṣe ayẹyẹ ìkẹyìn fún àwọn méjéèjì papọ̀ báyìí.

Àkọlé fídíò, Oyetola, Aregbesola àti Tinubu ni ọ̀rọ̀ náà wa láàrin wọn

Súfèsúfè ló pa ọmọ m- Iya Chukuemeka

Mary Odunukwe, ìyá Chukwuemeka nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀ ní ṣàdédé ni ọmọ òun bẹ̀rẹ̀ sí ní súfèsúfè lọ́jọ́ kan nígbà tó ń tajà lọ́wọ́, tí àwọn sì rò pé bóyá nítorí pé ọmọ òun kìí mu omi dada ló fàá.

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn

Mary ní kìí ṣe pé àìsàn yìí dá ọmọ òun gúnlẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ nítorí kò dáa dúró láti ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n tó búrẹ́kẹ́ sí i lẹ́yìn tí ó ṣe ìgbéyàwó tán.

Ó ní nígbà tí àìsàn náà pọ̀ ju agbára lọ, kò sí ilé ìwòsàn tí àwọn kò gbé Chukwuemeka lọ ṣùgbọ́n kò sí ìyípadà kankan à fi ìgbà tí àwọn ti ẹsẹ̀ ilé bọ̀ọ́.

Àkọlé fídíò, Segun iberu

Ó fi kun orí àárẹ̀ náà ni ó kú sí ní oṣù kejì ọdún tó kọjá tí àwọn sì sín lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nítorí ọ̀nà tó gbà kú àmọ́ àwọn kò ì tíì ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún un.

Mary ṣàlàyé pé Chukwuemeka tó kú ní ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni àkọ́bí òun, ọmọ mẹ́rin sìni òun bí.

Àkọlé fídíò, Aeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n

Ọkàn Chinenye gbọgbé nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú - ìyá Chukwuemeka

Ìyá Emeka ní nínú oṣù kẹjọ, ọdún 2020 ní Chinenye àti Chukwuemeka fẹ́ ara wọn ṣùgbọ́n tí ọmọ òun kú nínú ọṣù kéjì, ọdún 2021.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Ninu ọrọ iya rẹ: "Ikú Chukwuemeka dùn Chinenye púpọ̀ kódà ó dá àárẹ̀ si lára."

"Lẹ́yìn ọsù mẹ́sàn-án tí ọmọ mí kú náà ni Chinenye náà fò ṣánlẹ́ tó rọ̀run alákeji."

"Orí fífọ́ ló ń pariwo fún ọ̀sẹ̀ méjì kó tó jáde láyé."

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'

Nínú oṣù keji ọdún 2022 ní wọ́n fẹ́ ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún wọn

Mary ní láti ìgbà tí Chinenye ti kú lọ́dún tó kọjá, wọn ò tí ì sín ṣùgbọ́n àwọn ti sin Chukwuemeka.

Àkọlé fídíò, Agbẹdẹ Adodo

Bákan náà ló ní nínú oṣù keji, ọdún 2022 ní wọ́n fẹ́ sin Chinenye tí àwọn yóò sì ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún wọn papọ̀.

Ọmọ ọdún kan ló gbẹ̀yìn àwọn méjéèjì.