Gómìnà Zulum ṣe ìkìlọ̀ lórí ìdúnkookò ikọ̀ agbéṣumọ̀mí ISWAP sí Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @Gov Zulum
Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum tí ṣèkìlọ̀ pé ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Islamic State's West Afica Province (ISWAP) jẹ́ ìdúnkookò ńlá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Zulum pè fún ríró àwọn ọmọ ogun lágbára dáadáa kí wọ́n le dènà ikọ̀ yìí lati hùyẹ́ ju bí wọ́n ti wà lọ.
Ó wòye pé bí ISWAP pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ìjà tí wọ́n ní bá rí ààyè wọ àárín gbùngún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò kó ìnira tó pọ̀ bá àwọn ènìyàn ju ti ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram lọ.
Zulum sọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé kan ní ilé Ààrẹ ní Abuja.
- Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil
- Àwọn tọ́ọ̀gì Aregbesola ló da wàhálà sílẹ̀ l'Osun - Ọlọ́pàá
- Wo ohun méjé tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abba Kyari, ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn
- Afurasí tọkọtaya ta ẹ̀yà ara ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà- Ọlọ́pàá
- Ki lo ṣokunfa ikọlu to n waye si ẹni to ba wọ aṣọ Sunday Igboho tabi Yoruba Nation n'Ibadan?
- A ṣì lè yanjú ọ̀rọ̀ Ukraine ní ìtùbí-ìnùbí - Russia
- Àgbáríjọpọ̀ èèyàn sẹkúpa ọkùnrin kan lórí ẹ̀sùn pé ó dáná sun Kurani
- Wọ́n ti fi orúkọ Sadio MAne sọ pápá ìṣeré kan ní Senegal
Awọn ami wo lo bi ipe yii lati ọdọ Gomina Zulum?
Bákan náà ní àná, ni ẹ̀ka Nigeria Financial Intelligence (NFIU), ṣàwárí àwọn mẹ́rìndínlọ́gọ̀rún tó ń ṣàtìlẹyìn owó fún àwọn agbéṣùmọ̀mí ní orílẹ̀ èdè yìí pàápàá àwọn tó ń ṣàtìlẹyìn fún ikọ̀ Boko Haram ISWAP.
NFIU tún ṣàwárí àwọn 424 tó jẹ́ àwọn alátìlẹyìn wọn, àwọn ilé isẹ́ 123 àti àwọn tó ń ṣe owó 33 tó ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn agbéṣùmọ̀mí náà.
Zulum wá rọ Ààrẹ Muhammadu Buhari láti tété wá àtìlẹyìn àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ òkèrè láti kojú ikọ̀ àwọn agbéṣùmọ̀mí náà.
Zulum ní ìjọba ń ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fa lórí ètò ààbò ṣùgbọ́n omi ṣì pọ̀ lámù, ìpèníjà ṣì pọ̀ fún ìjọba.
Ó tẹ̀síwájú ìkìlọ̀ yìí ṣe pàtàkì lójúnà à ti má gba ISWAP láàyè láti rídìí jòkòó ní Nàìjíríà.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní àjọ ọmọ ogun gbọ́dọ̀ tún ìgò wọn fọ̀, kí wọ́n wá ọ̀nà tí wọ́n yóò fi kojú ISWAP.
Bákan náà ló tẹpẹlẹmọ́ ìdí tí Nàìjíríà láti wá àtìlẹyìn ilẹ̀ òkèrè, bó ṣe ní àwọn orílẹ̀ èdè bíi America, Britain àti àwọn mìíràn tí wọ́n lágbára ju Nàìjíríà lọ gan ṣì máa ń bèèrè fún àtìlẹyìn orílẹ̀ èdè mìíràn tí wọ́n bá ní ìpèníjà.
Zulum tún pè fún àyípadà àti àtúnṣe sí ètò ìgbanisíṣẹ́ àjọ ọmọ ogun.
- Oríṣìíríṣìí aṣọ aláràǹbarà láwọn òṣèré tíátà fi ṣe àyájọ́ ọjọ́ olólùfẹ́
- Ẹgbẹ́ Olùkọ́ Fásitì ASUU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì olóṣù kan lónìí
- Tí o bá ń pẹ́ jẹun alẹ́, o lè ní àrùn jẹjẹrẹ ọyàn àti asétọ̀
- Àjà ilé ọtí dàwó ní London, mẹ́tàlá nínú àwọn oníbàárà farapa
- Ilé alájà mẹ́ta dàwó ní Yaba nílùú Eko, àwọn èèyàn há sábẹ́ rẹ̀
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
















