Hackney Wick bar floor collapse: Àjà ilé ọtí dàwó ní Hackney Wick, mẹ́tàlá nínú àwọn oníbàárà farapa

Aja ile ọti to dawo

Oríṣun àwòrán, HAL

Ori ko ọpọ eeyan yọ nigba ti awọn mẹtala farapa lẹyin ti aja ile ọti tawọn eeyan ti n ṣe faaji dawo ni Hackney Wick niluu London.

Ni nkan bi ago marun un ku iṣẹju mẹwaa ni wọn ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ pajawiri nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ lọjọ Abamẹta.

Awọn oṣiṣẹ panpana doola eeyan meje ti wọn ha sibi aja ile ọti to dawo naa.

Ohun ti awọn oṣiṣẹ panapana sọ nipa iṣẹlẹ naa ree

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawari ṣalaye pe eeyan mẹta lo farapa yanayana nibi iṣẹlẹ ọhun nigba tawọn mẹwaa ṣeṣe diẹ.

Ajọ naa sọ pe eeyan mẹrin ninu wọn ti wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ bayii.

Ẹwẹ, ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ile kikọ ti sọ pe oun n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ to n ri si ọrọ pajawiri lati ṣe iwadii iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, OLota

Awọn ti iṣẹlẹ ọhunṣoju wọn sọrọ nipa ohun to ṣẹlẹ

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn, Amelia, sọ pe oun wa nibẹ nigba ti aja ile ọti naa dawo.

Amelia ṣalaye wi pe oun tiẹ ṣe iranwọ lati ko pangulutu aja to wo naa kuro.

''BI iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ loju mi ni mo ti ro pe awọn eeyan kan maa ku nibẹ.

Nitori naa, mo dupẹ pe a ṣi wa laaye.

Aja ile ọti to dawo

Oríṣun àwòrán, PA Media

Iṣẹlẹ yii ti jẹ ki n maa kọminu lori awọn ile ọti miran bo ya iru nkan bayii le ṣẹlẹ sawọn naa,'' Amelie lo sọ bẹẹ.

Hal to jẹ oṣiṣẹ eleto ilera naa wa nibẹ nigba ti aja ile ọti naa dawo, ṣugbọn o moribọ pẹlu ipalara diẹ.

Hal ni ''niṣe ni a kan gbọ gbau lẹkan naa bi ilẹ riri, ko si bi eeyan ti le gbaradi fun iru iṣẹlẹ bayii.

Àkọlé fídíò, Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì

Mo n wo ere bọọlu laarin ẹgbẹ agbabọọlu Clapton CFC ati Stonewall FC lọwọ ni nigba ti aja naa dawo.

Ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Eledua pe ori ko mi yọ, gbogbo wa ni a ran ara wa lọwọ lati jade.''

Harriet McMahon ni tiẹ n ṣ faaji lọwọ labẹ aja to dawo pẹlu ọrẹkunrin rẹ.

O ni kiki eruku ni oun n ri lẹyin ti aja naa wo lu wọn mọlẹ, bakan naa ni oun n gbọ tawọn eeyan n pariwo.

Aja ile ọti to dawo

Oríṣun àwòrán, PA Media

Adari ijọba ilu London Sadiq Khan sọrọ lori iṣẹlẹ naa

Sadiq Khan to jẹ olori ijọba ilu London dupẹ lọeọ awọn oṣisẹ pajawiri atawọn to n wa ọkọ anbulansi fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ panapana atawọn ọlọpaa.

Ọgbẹni Khan ko gbagbe lati ki awọn to farapa ninu iṣẹlẹ naa.

O gbadura iwosan kiakia gbogbo awọn to fara kaasa nibi iṣẹlẹ naa.