Dead Body in Oyo Uncomplited Building: Wọ́n rí egungun èèyàn àti aṣọ akẹ́kọ̀ọ́ nínú ilé àkọ́kù náà

Oríṣun àwòrán, Amotekun Oyo
Awọn olugbe ilu Ọyọ ti tu aṣiri awọn afurasi to n fi ẹya ara eeyan ṣe etutu ọla ninu ile akọku kan ti wọn ṣe awari ẹ nilu naa.
Awọn eeyan kan to n gbe nitosi ile naa to n bẹ ni opopona Ọyọ si Ilọra nijọba ibilẹ Iwọ-oorun Ọyọ, ni wọn bẹrẹ si ni ṣe ofintoto agbegbe naa, nigba ti oorun buruku jade ni ayika naa.
Iroyin fi idiẹ mulẹ pe, ninu igbiyanju wọn lati ṣe awari nnkan ti o n run, ni wọn ti dede kan ẹya ara eeyan ti o ti n jẹra ninu ile akọku naa.
Lẹyin eyii sini wọn fi ọrọ naa to agọ ọlọpaa ijọba ibilẹ naa leti.
- "Ariwo tí Sofiat pa ló fu ará àdúgbò lára, tí ọwọ́ fi tẹ̀ wá"
- Àrídájú pé ìdájọ òdodo yóò wáyé ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fojú hàn ni lórí ikú Adegoke - Agbẹjọ́rò ẹbí olóògbé
- Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe ń wáyé lọ́wọ́ ní Abuja, Femi Falana ń bèèrè pé kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí Osun
- Femi Falana kò gba kọ́bọ̀ fún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke àmọ́ aráàlú ń dáwó jọ - Ẹ̀gbọ́n olóògbé
- A kò fi ẹbí Timothy sílẹ̀, à ń gbiyànjú pé kí wọ́n dá ẹjọ́ náà padà sí Osun dípò Abuja ni- Agbẹjọ́rò Adekilekun
- Àwọn ẹbí Rahmon Adedoyin àti Timothy Adegoke ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn nílé ẹjọ́
Bawo ni awọn ara adugbo se ri oku nile akọpati?
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa ti o pe orukọ ara rẹ ni Lanre, ṣe alaye fun awọn akọroyin l'ọjọ iṣẹgun pe, oun wa nibẹ lasiko ti awọn ọlọpaa ṣe abẹwo si ile naa, ti wọn si nawọ gan awọn afurasi kan.
O ni, "A kọ fẹ ki wọn da ọwọ bo iṣẹlẹ yii rara. Ọpọlọpọ nnkan lo n ṣẹlẹ bayii.
Wọn n da ẹmi awọn eeyan legbodo lati fi ṣe etutu ọla. Ti a ba si ṣe awari iru nnkan bẹẹ, mo gbagbọ o yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa sa gbogbo ipa wọn lati fi oju awọn aṣebi han".

Oríṣun àwòrán, Amotekun Oyo
A ri egungun eniyan ati asọ ile ẹkọ ninu ile naa:
Aladugbo mii ti ko darukọ ara rẹ ṣe alaye wi pe, wọn ri egungun eeyan ati aṣọ ọmọ ile ẹkọ ninu ile naa ti eyii si tumọ si pe o ṣeeṣe ki iwa laabi ti maa waye ninu ile fun ọjọ pipẹ.
O ni, "Awọn to n gbe ni tosi ile naa ni awọn maa n ri arakunrin kan ti o maa n gun alupupu lọ si ile naa. Wọn ni iṣẹ ile ni wọn ro pe arakunrin naa lọ n ṣe nibẹ, lai mọ pe ọdaran ni.
Awọn ọlọpaa wa, wọn si ko awọn nnkan ti wọn ri nibẹ lọ gẹgẹ bi wọn ṣe nawọ gan awọn afurasi kan".
Titi di asiko yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ko ti i fesi lori ọrọ yii. Gbogbo igbiyanju lati kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Adewale Osifeso, lo ja si pabo.
- Akẹ́kọ̀ọ́ fásítì OAU dèrò ọ̀run nígbà tó já sínú kòtò ilé ìgbẹ́ ‘soakaway’
- Ìjọba Oyo àti iléeṣẹ́ amúnáwá wọ̀yá ìjà torí gbèsè tí wọn jẹ ara wọn
- Small Mummy, aláwàdà ọmọ ọdún mẹwàá gba ẹ̀bùn ọkọ̀ olówó iyebíye
- Àìsàn wo ló ń ṣe Opeyemi Ayeola tó tún fi dèrò ilé ìwòsàn?
- "Ẹ̀rù kí Naijiria má ti bodè lo n ba Benin Republic, tó ṣe mú Sunday Igboho mọ́lẹ̀"
- Onímọ̀ ẹ̀yà ara míì kéde okùnfa ikú míràn tó pa Sylvester Oromoni
Ikọ Amotekun ni ipaniyan lati fi se etutu ọla lo waye nile akọku:
Ẹwẹ, alakoso ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn oniroyin nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Ọyọ.
O ni, "Lootọ ni iṣẹlẹ naa waye. Awọn eeyan mi fi to mi leti pe ẹya ara eeyan to ti n jẹra ni wọn ri nibẹ.
Awọn eeyan wa lọ si ibẹ, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa lo nawọ gan awọn afurasi. Awọn nnkan ti a si ri nibẹ lo mu ifura lọwọ pe ipaniyan lati fi ṣe etutu ọla lo n waye ninu ile naa".
Ki lo ti waye sẹyin:
Asa ki awọn ẹda kan maa fi ẹya ara eeyan se etutu ọla ti di isẹlẹ to wọpọ bayii ni orilẹede Naijiria.
Laipẹ kii ni awọn ọdọ mẹrin nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ge ori ọrẹbinrin ọkan lara wọn lati fi se owo.
Bakan naa ni awọn oku ti wọn ti yọ ẹra ara wọn maa n kun oju popo kiri ni ọpọ igba.
Ileesẹ ọlọpaa si maa n fi ikede sita ni ọpọ igba pe o seese ki wọn pa awọn eeyan naa, yọ ẹya ara wọn lati fi se oogun owo.
Ọpọ awọn eeyan miran si ni ọwọ ti tẹ sẹyin, ti wọn ba oku tabi ẹya ara eeyan lọwọ wọn eyi ti wọn fẹ fi se oogun owo tabi ta fun awọn eeyan miran to fẹ lo ẹya ara eeyan.


















