Timothy Adegoke's court case: Kí ló dé tí agbẹjọ́rò mọ́lẹ́bí Timothy Adegoke kò ṣe farahàn nílé ẹjọ́ ní Abuja?

Oríṣun àwòrán, Others
Ki lo de ti agbẹjọro fun mọlebi Timothy Adegoke ko fi ara han nile ẹjọ ni ibeere ti ọpọ n beere bayii.
Arakunrin Gbade Adegoke ti o jẹ ẹgbọn fun oloogbe Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ ti wọn deede ri oku rẹ ni ayika ile itura ti o de si ninu ọṣu kọkanla, ọdun 2021 ti ke gbajare wi pe idile naa nilo awọn agbẹjọro agba ti o le ṣe iranlọwọ fun wọn lati ri idajọ ododo gba.
- Musulumi àti Kristẹni lo ṣe àdúrà níbi ètò ìsìnkú Timothy Adegoke lónìí
- Ramon Adedoyin t'ọ́lọ́pàá mú nítorí ikú Timothy Adegoke gba ilé ẹjọ́ lọ, ohun tílé ẹjọ́ sọ rèé...
- Bí ìsìn alẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ń wáyé fún ìsìnkú Timothy Adegoke, mọ̀lẹ́bí tẹ́wọ́ gba òkú rẹ̀
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun
- Ìyàwó Timothy Adedoge ké gbàjarè lórí èsì àyẹ̀wò ikú tó pa ọkọ rẹ̀
- Kí ló ń dá ọlọ́pàá dúró láti gbé Rahmon Adedoyin àti ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke?
- Ṣé Odunlade Adekola àti Toyin Abraham kò ṣe 'Ambassador' rógo báyìí?
Bawo ni ọrọ ṣe jade?
Ninu fọran kan ti o lu sita lori itakun ayelukara l'Ọjọru ni Gbade ti fi igba ta wi pe igbẹjọ to yẹ ko waye lori awọn afurasi ti ọwọ ijọba tẹ ko kẹsẹjari nitori agbẹjọro to n ṣoju fun mọlẹbi naa ko fi ara han nile ẹjọ.
Arakunrin Gbade Adegoke ni, "Gbogbo iranlọwọ ti ẹ ba le ṣe fun wa, a fẹ agbẹjọro. Agbẹjọrọ agba sini a fẹ.
O le jẹ meji, mẹta, mẹrin tabi ju bẹẹ lọ. Ẹ jọọ ko si ẹni ti mo fẹ lọ fun ni abọ nile mọ. Nnkan ti mo ba sọ nibi ni abẹ ge. Maa sọ fun wọn nile wi pe bayii ni".
Arakunrin Gbade Adegoke kẹsi ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ijọba orilẹede Naijiria lati dide fun iranlọwọ nitori ko ni daa ki ọrọ naa lọ bẹẹ lai si idajọ ododo.
- Ìjọba Kano fẹ̀sùn oníkókó márùn ún kan àwọn afurasí tó pa ọmọ ọdún márùn ún Hanifa
- Àwọn agbébọn pa ọgọ́ta èèyàn ní ibùdó ìfiniwọ̀ ní DR Congo
- Ọdaràn làwọn tó ń pè fún ìdìbò dípò 'Restructuring' tí a n béèrè- Iba Gani Adams OPC
- Mọ̀ sí i nípa Oba Yesufu Asanike, Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Oògùn olóró tó lé ní mílíọ̀nù kan la rí gbà lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ Onitsha sí Kano- Àjọ NDLEA
- 'Wọ́n gba ọ̀kadà mi, fóònù àti owó, wọ́n tún gba ọwọ́ méjèèjì'
Awọn ẹsun wo ni wọn ka kalẹ bayii?
Lara awọn ẹsun ti ẹgbọn oloogbe naa fi kan an ni pe awọn eeyan kan ti n dun kukulaja mọ oun lori ọrọ naa.
Kí ló dé tí agbẹjọ́rò mọ́lẹ́bí Timothy Adegoke kò ṣe farahàn nílé ẹjọ́ ní Abuja?

O ni ọkan ninu awọn eeyan naa ti o lepa oun wa si ilu Eruwa tẹlẹri ni oun tun dede pade nile ejo nilu l'Abuja, ti ẹni naa si ṣe ileri lati fi okun de oun bi oun ba gbiyanju lati sun ilu Abuja mọju.
Bakan naa ni Arakunrin Gbade fi kun ọrọ rẹ pe ninu ewu ni oun wa bayii, bẹẹ sini oun ni ipaya lori aabo ẹmi.
Bawo ni ọrọ ṣe kan Agbejọro?
Iroyin ti o tun tẹlẹ igbe ti ẹgbọn oloogbe fi ta ni pe awọn agbẹjọro to yẹ ki o ṣoju idile wọn ko fi ara han nile ẹjọ ti wọn ti fi oju awọn afurasi han nilu Abuja.
Eyii lo mu ki a kan si ọkan lara awọn agbẹjọro fun mọlẹbi Adegoke, Amofin Naheem Adekilekun ki a le fi idi otitọ mulẹ.
- Orílẹ̀-èdè North Korea ṣe ìfilọ́lẹ̀ àdó olóró tó tóbi jùlọ láti ọdún 2017
- Abdulsalami ní kò sẹ́ni tó pa MKO Abiola, àìsàn ló pa á, ẹbí Abiola yarí
- 'A kò le gba ẹlẹ́wọ̀n kankan wọlé mọ́, kò sí òunjẹ tá a fẹ́ fún wọn'
- Dangote, má ṣe dáwọn ọ̀dọ́ tó ní kó dupò ààrẹ lọ́dún 2023 lóhùn o- Shehu Sani
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
- Nkan dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní America nítorí ìjì líle
- Àbúrò mi dágbéré pé òun fẹ́ dé ibì kan, ìròyìn ikú rẹ̀ ni mo gbọ́
Kini Agbẹjọrọ naa sọ fun BBC Yoruba?
Adekilekun ṣe alaye fun akọroyin wa pe ipinlẹ Ọṣun ti wọn ti ri oku oloogbe Timothy Adegoke lo yẹ ki igbẹjọ ti waye gẹgẹ bi nnkan ti ofin sọ.
O ni igbiyanju lati mu ki wọn gbe ẹjọ naa pada wa si ipinlẹ Ọṣun ni awọn agbẹjọro fun mọlẹbi Adegoke n ba kiri.
Eyii lo si faa ti wọn ko ṣe fi ara han nibi igbẹjọ akọkọ to waye nilu Abuja.
Agbẹjọro naa tẹsiwaju wi pe aifi ara han agbẹjọro fun mọlẹbi Adegoke nile ẹjọ to n bẹ nilu Abuja ko ṣe okunfa idiwọ kankan bo ti n wu ki o mọ.
O ni nitori pe "ọrọ ẹjọ ti o ba ti ni ọwọ ẹsun iwa ọdaran ninu bayẹn, ijọba ati awọn afẹsunkan ni o kan ju. Ohun ti mọlẹbi le ṣe ko ju ki mọlẹbi jẹ bi i ẹlẹri fun ijọba lọ.
Nitori naa, ailọ wa lanaa ko ba nnkan kan jẹ".
Adekilekun fi idi ọrọ mulẹ pe oun ati awọn akẹgbẹ oun ko ti i yọwọ ninu ẹjọ naa, bẹẹ sini ẹni kankan ko dun kukulaja mọ wọn lati jawọ ninu ẹ.
O ni bi ọrọ ṣe ye ẹgbọn oloogbe mọ, lo mu ki o pariwo sita lori itakun ayelukara.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn yoo fi ara han nibi igbẹjọ mii ti yoo waye.

















