Dozens massacred in DR Congo : Àwọn agbébọn pa ọgọ́ta èèyàn ní ibùdó ìfiniwọ̀ ní DR Congo

Oríṣun àwòrán, AFP
Eeyan bi ọgọta to n gbe ni ibudo ifiniwọ fun awọn ti ko nile lori ti ku lasiko ikọlu kan to waye ni Ila oorun Ariwa orilẹ-ede Democratic Republic of Congo.
Ni nkan bi aago meji oru Ọjọru ni awọn ọkunrin agbebọn to tun mu ada dani wọ ibudo Plaine Savo, ti ijọba ṣe fun awọn eeyan to sa kuro nile wọn nitori ogun ẹlẹyamẹya to n waye ni ẹkun Ituri.
olori agbegbe naa sọ pe ọpọlọpọ awn to ku lo jẹ obinrin ati awọn ọmọde. Ada ni wọn fi ge ọrun ọpọlọpọ wọn.
Ẹnikan to n gbe ninu ibudo naa sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe ori ibusun ni oun wa nigba ti oun kọkọ gbọ ariwo. Lẹyin naa ni iro ibọn bẹr si ni dun.
"Mo bẹrẹ si ni salọ. Bẹẹ ni mo n ri ti awọn eeyan n kigbe fun iranlọwọ."
- China sinmi lórí yíyá Nàìjíríà lówó, èyí lè fà ìdádúró lórí iṣẹ́ rélùwé
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
- Ohun tí ó ṣokùnfà ikú Fadlullah Agboluaje, akẹ́kọ̀ọ́ tó kú sí Ukraine ní ọjọ́ kejì tó dé ibẹ̀
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ajọ to n ṣe iranlọwọ fun ibudo naa, Norwegian Refugee Council (NRC) sẹ sọ, eeyan bi ogoji lo tun farapa yatọ si awọn to ku.
Ikọ agbebọn Codeco ni iroyin sọ pe o wa nidi iṣẹlẹ yii.
Ilu Lendu to jẹ ibugbe awọn agbẹ ni awọn jagunjagun Codeco ti wa. O si ti to asiko diẹ ti wọn ti n ba awọn darandaran to wa ni ẹkun Hema ja.
- Ìjọba Tanzania yòó fi òfin gbé òbí tí ọmọ rẹ̀ bá sá nílé ẹ̀kọ́
- Musulumi àti Kristẹni lo ṣe àdúrà níbi ètò ìsìnkú Timothy Adegoke lónìí
- Nkan dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní America nítorí ìjì líle
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
- Àwọn ọmọbìnrin oníwọ́kuwọ́ ló mú kí ń yẹ̀bá nídìí iṣẹ́ tíátà
- Bí ayẹyẹ ìsìnkú Alao Akala yóò ṣe lọ rèé
Ajọ NRC sọ pe eeyan bi aadọrin lo ti padanu ẹmi wọn ni awọn ibudo marun-un miran.
O ni awọn ikọlu to n waye bayii tun timu ki awọn to di alainilelori pọ yanturu, to si fi awọn to wa nilẹ sinu ewu.















