Ìjọba Tanzania yòó fi òfin gbé òbí tí ọmọ rẹ̀ bá sá nílé ẹ̀kọ́

Ijọba orilẹ-ede Tanzania ti kede pe oun yoo fi ofin mu obi ti ọmọ rẹ ba kọ lati lọ si ile ẹkọ ni olu ilu orilẹ-ede naa, Dodoma, lọsẹ to n bọ.
Aṣẹ naa waye lati ẹnu Anthony Mtaka to jẹ kọmisanna eto ẹkọ ni ẹkun Dodoma ati awọn agbegbe to yi i ka.
Ikede naa waye lasiko abẹwo to sẹ si ile ẹkọ kan lọjọ Ẹti, lẹyin ọsẹ meji ti eto ẹkọ bẹrẹ fun saa miran.
Nile ẹkọ naa, akẹkọọ mẹtadinlaadọrin lo wa lọjọ naa ninu marundinlaadọsan.
Igbagbọ awọn alaṣẹ ni pe awọn obi kan ma n ni ki awọn ọmọ wọn lọ wa iṣẹ pẹpẹẹpẹ sẹ tabi yọnda wọn lati lọ ṣe iṣẹ ọmọ ọdọ, dipo ki wọn o lọ sile ẹkọ.
- Àwùjọ àgbáyé, ẹ ṣèrànwọ́ fún Burkina Faso kó le borí ìṣòro - Olórí ìjọba ológun
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
- Dókítà àti Nọ́ọ̀sì di atọrọjẹ torí àjẹsílẹ̀ owọ oṣù mẹ́jọ
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
- Ọlọ́pàá Ogun mú ọ̀dọ́ mẹ́ta tí kò tó ọdún 20 níbi tí wọ́n ti n fi ọ̀rẹ́bìnrin ọ̀rẹ́ wọn ṣe òògùn owó
Arakunrin Mtaka sọ pe oun ko ni i fi aaye gba iru iwa bẹẹ.
"Mi o le kọ ile ẹkọ, ko tabili ikọwe sinu yaara ikẹkọ, kẹẹ wa kọ̀ lati mu ọmọ in lọ sile ẹkọ. Ko ṣeeṣe."
O ni oun yoo ri daju pe oun n sẹ ayẹwo ojule si ojule lati owurọ kutu, ki oun le mu awọn obi ti ko ba yọnda ọmọ wọn lati lọ sile ẹkọ.
Nkan ti n dẹnukọlẹ ni Ila oorun orilẹ-ede America, nitori fun igba akọkọ lọdun mẹrin.
Awọn awoye oju ọjọ sọ pe iji lile naa yoo lọ lati Carolinas si Maine, pẹlu ilẹ mimi ni awọn agbegbe to wa leti omi.
Ipinlẹ marun-un nilẹ America lo ti kede nkan o fararọ pẹlu ikilọ pe ki awọn olugbe ibẹ ma jade si ojupopo rara fun aabo ara wọn.















