Ethiopia Civil War: : Ìyàn ń mú ní agbègbè Tigray torí ogun abẹ́lé, èèyàn 9m kò rí oúnjẹ jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ eto ilera lagbegbe Tigray, ni Ethiopia ti sọ fun BBC pe iyan n mu ni orilẹ-ede naa to bẹẹ, ti awọn dokita ati nọọsi ti di atọrọjẹ.
Awọn oṣiṣẹ eto ilera naa ko ti gba owo oṣu fun oṣu mẹjọ gbako, eyii to mu ki wọn maa wa ọna mii lati bọ ara wọn atawọn mọlẹbi wọn.
Iroyin nipa awọn dokita yii lo n waye lẹyin atẹjade ajọ United Nations kan to sọ pe iyan ti n mu ni Tigray.
- Fathia Balogun kéde aṣọ ẹbí ₦150,000 àti ₦120,000 fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Òǹkọ̀wé kan dèrò àtìmọ́lé torí ó bú Ààrẹ lórí ayélujára
- Àlàyé rèé lórí àìsàn tó ṣe mi fọ́dún mẹ́jọ tí mo fi rù kan eegun - Ogogo
- Tiyín lẹ ṣe o, àwa kò gbà èsì ìdìbò abẹ́nú PDP l‘Ekiti - Segun Oni
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- Sanwo-Olu kède iye tí àwọn aráàlú yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ rà
- Àwùjọ àgbáyé, ẹ ṣèrànwọ́ fún Burkina Faso kó le borí ìṣòro - Olórí ìjọba ológun
- Bí ìsìn alẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ń wáyé fún ìsìnkú Timothy Adegoke, mọ̀lẹ́bí tẹ́wọ́ gba òkú rẹ̀
- Ta ni Abiodun Oyebamiji tí APC dìbò yàn bí olùdíje gómìnà l'Ekiti
Atẹjade ọhun ni nnkan bi 2.2 miliọnu eeyan ni ko ri ounjẹ jẹ.
Bẹẹ naa ni idaji awọn alaboyun atawọn obinrin to n tọ ọmọ lọwọ n sun ninu ebi.
Lapapọ, nnkan bii miliọnu meṣan an eeyan ni iyan ja bayii ni Tigray ati agbege meji mii ti ija ti n waye.
Lati inu oṣu Kọkanla ọdun 2020 ni awọn ọmọ ogun ijọba atawọn ọmọ ogun ọlọtẹ ti n koju ara wọn, ninu eyii ti ẹgbẹgbẹrun eeyan ti padanu ẹmi wọn.
Yatọ si pe o ṣoro lati ko ounjẹ ati oogun lọ si Tigray, wọn tun ti gbe awọn ile ifowopamọsi tipa pẹlu.
Bi awọn araalu ṣe n jiya naa ni awọn oṣiṣẹ eto ilera ko gbẹyin.
Awọn ọmọ ọwọ n ku nitori airi ounjẹ jẹ
Dokita kan sọ pe wọn ti mu adinku ba iye ounjẹ to yẹ ki awọn ọmọ ọwọ maa jẹ.
O ni lawọn ibi kan, iye owo ti wọn n ta ounjẹ wọn ju ohun ti awọn araalu le ra lọ.
Amọ o ṣoro fun ileeṣẹ iroyin BBC lati fidi awọn nnkan mii ti a gbọ mulẹ nitori ija to n waye ni Tigray ti mu ki wọn ge ẹrọ ibaraẹnisọrọ kuro.
A gbọ pe o ṣeeṣe ki ajọ red Cross ko awọn oogun wọ agbegbe Makelle fun igba akọkọ lati oṣu Kẹsan an ọdun to kọja.
Ṣugbọn oṣu Kejila ọdun to kọja ni ajọ UN ti ri aye gbe ounjẹ lọ sagbege ọhun kẹyin.
Ajọ to n ri si ipese ounnjẹ lagbaye, WFP ni wọn nilo lati maa ko ọgọrun ọkọ ajagbe to kun fun ounjẹ lọ sibẹ lojoojumọ ki wọn to le tan iyan to n mu ni Tigray.


















