Sanwo-Olu: ₦200 sì ₦300 làwọn èèyàn yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí a ṣẹ̀ṣẹ́ rà

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ naa balẹ pe owo perete ni wọn yoo maa wọ ọkọ oju irin ni ipinlẹ naa ti awọn ba ti pari awọn ọna oju irin ti wọn n ṣe lọwọ.
Sanwo-Olu lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels nigba to n ṣalaye ohun ti ijọba rẹ n ṣe lati koju iṣoro funkẹrẹ-fakẹrẹ to nn ba ipinlẹ Eko finra.
O ni "A gbagbọ pe iye owo ti awọn eeyan yoo maa san ko ni pọ rara."
- Àwùjọ àgbáyé, ẹ ṣèrànwọ́ fún Burkina Faso kó le borí ìṣòro - Olórí ìjọba ológun
- Bí ìsìn alẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ń wáyé fún ìsìnkú Timothy Adegoke, mọ̀lẹ́bí tẹ́wọ́ gba òkú rẹ̀
- Fathia Balogun kéde aṣọ ẹbí ₦150,000 àti ₦120,000 fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Tiyín lẹ ṣe o, àwa kò gbà èsì ìdìbò abẹ́nú PDP l‘Ekiti - Segun Oni
- Àlàyé rèé lórí àìsàn tó ṣe mi fọ́dún mẹ́jọ tí mo fi rù kan eegun - Ogogo
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- Ta ni Abiodun Oyebamiji tí APC dìbò yàn bí olùdíje gómìnà l'Ekiti
- Òǹkọ̀wé kan dèrò àtìmọ́lé torí ó bú Ààrẹ lórí ayélujára
"Iye owo naa ko ni to ẹgbẹrun kan... ko ni ju nnkan bii igba naira si ọọdunrun naira lọ."
"Ninu iwoye mi, kii ṣe pe awọn eeyan yoo na owo apo wọn tan lori pe wọn n wọ ọkọ oju irin, owo naa ko ni wọn rara, bẹẹ si ni ọkọ oju irin ọhun yoo wa nilẹ fun gbogbo araalu."

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Sanwo-Olu ni owo ti wọn yoo maa na lori ọkọ oju irin ko ni ju iye owo ti wọn n na lati wọ ọkọ ọlọpọ ero BRT lọ.
Gomina naa sọ pe anfani pupọ lo wa ninu lilo ọkọ oju irin nitori kii gba akoko to pọ bii ọkọ oju popo.
Ọkọ oju irin tuntun niluu Eko
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kinni yii ni ijọba Eko kede pe awọn ti ra ọkọ oju irin ayarabiasa meji lati ilẹ Amẹrika.
Ọjọ naa ni ijọba Eko fẹnuko lori idunadura lori ọkọ oju irin naa pẹlu ileeṣẹ Talgo Incorporated ,niluu Milwaukee nilẹ Amẹrika.
Sanwo-Olu sọ fun awọn to wa nibi ti wọn ti ra ọkọ oju irin ọhun pe ọkọ naa ni yoo maa na ọna oju irin oni kilomita mẹtadinlogoji ti wọ ṣẹṣẹ ṣe.
Ati pe ọkọ oju irin ayara bi aṣa naa ni akọkọ iru rẹ ni iha Iwọ Oorun Afrika.














