Timothy Adegoke: Àlàyé rèé lórí ìdí tí ẹbí olóògbé ṣẹ́ fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí wáyé ní Osun

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke and Rahmon Adedoyin
Awọn mọlẹbi oloogbe Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo to ku sile itura ni Ile ife tun ti ke gbajare sita fun araye lẹẹkan si.
Awọn mọlẹbi naa lo pariwo sita pe awọn n fẹ ki igbẹjọ gbogbo awọn afurasi ti wọn mu lori iku oloogbe naa waye ni ipinlẹ Osun nibi ti isẹlẹ naa ti waye.
Ibeere yii jẹyọ ninu lẹta kan ti agbẹjọro fun mọlẹbi Timothy, Naim Adekilekun kọ lọjọbọ nilu Osogbo nipinlẹ Osun, eyi to t iwe iroyin Punch lọwọ.
- Timothy Adegoke yóò wọ ilẹ̀ sùn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, bí ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ rèé
- Ramon Adedoyin t'ọ́lọ́pàá mú nítorí ikú Timothy Adegoke gba ilé ẹjọ́ lọ, ohun tílé ẹjọ́ sọ rèé...
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun
- Rahmon Adedoyin ti sọ̀rọ̀ lórí àbájáde ìwádìí òkú ‘autopsy’ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura rẹ̀ nílé Ifẹ̀
- Àwọn ọ̀dọ́ Eruwa ṣe ìwọ́de lórí ikú Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
- Kanpe ni òkú Timothy Adegoke wà, wọn kò gé ẹ̀yà ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá Osun
- Kí ló ń dá ọlọ́pàá dúró láti gbé Rahmon Adedoyin àti ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke?
O salaye ninu iwe ọhun pe awọn mọlẹbi ni niwọn igba to jẹ pe ko si isẹlẹ kankan nipa ọrọ naa to waye nilu Abuja, nitori naa ko si idi ti igbẹjọ fi yẹ ko maa waye nibẹ
Lọwọ lọwọ bayii, ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa lo ti fi ẹsun kan ẹni to ni ile itura naa, Ramon Adedoyin lori iku Timothy naa, ti wọn si gbe lọ siwaju ile ẹjọ giga ilu Abuja.
Bakan naa ni wọn tun ko awọn eeyan mẹfa miran pẹlu rẹ lọ sile ẹjọ, ti wọn si fi ẹsun kan wọn pẹlu Adedoyin pe wọn lọwọ ninu iku akẹkọọ to n gba oye kun oye naa.
Bakan naa ni ẹbi Timothy ni awọn n fẹ ki ibeere awọn wa si imusẹ lọna ati dena awọn igbesẹ yoowu ti agbẹjọro awọn olujẹjọ le fẹ maa gbe lati tu awọn onibara rẹ silẹ.
Alaye ree lori idi ti ẹbi Adegoke se fẹ ki igbẹjọ waye ni Osun:
Ninu alaye rẹ, Adekilekun ni "a n beere pe ki wọn gbe igbẹjọ naa wa sile ẹjọ giga ipinlẹ Osun nitori oun nikan lo ni asẹ lati gbọ ẹjọ naa.
Ko si isẹlẹ kankan nipa ọrọ yii to waye nilu Abuja tii se olu ilu ilẹ wa, bikose ni Ile Ife tii se ipinl Osun, ki wa lo de ti igbẹjọ naa se n waye ni Abuja.
Bakan naa, ko si ohunkohun to wa ninu abala ofin kẹtalelaadọrun, ẹsẹ kinni ati ikeji iwe ofin idajọ fawọn ọdaran tọdun 2015, to ro awọn ọlọpaa lasẹ lati se bẹẹ.
A wa n rọ ileesẹ ọlọpaa lati ri daju pe wọn gbe igbẹjọ naa wa sile ẹjọ giga ipinlẹ Osun, eyi to tọ, to si yẹ lati gbọ ẹjọ naa.
Ki lo ti wayelori isẹlẹ naa tẹlẹ:
Timothy Adegoke ni akẹkọọ to n gboye kun oye ni fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile Ife amọ to ku sile itura Hilton nilu naa lasiko to fẹ lọ se idanwo.
Awọn ẹbi Adegoke lo figbe ta fun ileesẹ ọlọpaa pe awọn ko gburo ọkunrin naa lati igba to ti de si Ile Ife, ti iwadii si bẹrẹ lọgan lati mọ bo se poora.
Awọn osisẹ ile itura Hilton naa, to jẹ ti gbajumọ kan ni Ile Ife, Ọmọọba Rahmon Adedoyin, sẹ fun awọn ọlọpaa pe ọkunrin naa ko wa sile itura ọhun.
Amọ iwadii nipa bo se sanwo ile itura naa lati banki rẹ ni ori foonu rẹ tu asiri pe ile itura naa lo sun si, ti awọn osisẹ si pada jẹ wọ pe o wa sọdọ awọn nile itura ọhun amọ o ti ku.
- Kí ló pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàíjíríà tó kú lọ́jọ́ kejì tó dé ilé ẹ̀kọ́ ní Ukraine?
- Ẹ̀yín àgbà Yorùbá, ẹ dìde yanjú aáwọ̀ òṣèlú láàrin Tinubu àti Osinbajo, bíbẹ̀ẹ́kọ́... - Ajulo
- Deji Akure tó lu aya rẹ̀ lójú títì, tí wọn rọ̀ lóyé, ti jáde láyé
- Michael Jackson, ọkùnrin tó sọ ara rẹ̀ di obìnrin kó sí pańpẹ́ EFCC
Wọn mu awọn ọlọpaa lọ sibi ti wọn sin oku Timothy naa si, ti wọn si ko awọn osisẹ naa ati ẹni to ni ile itura ọhun, Ọmọọba Rahmon Adedoyin.
Bakan naa ni awọn osisẹ ọhun ni ọmọ Raheem, tii se ọmọkunrin Rahmon Adedoyin gan lo lewaju awọn lati sin oloogbe naa, ti onitọun si ti salọ.
Ileesẹ ọlọpaa ti wa kede pe awọn n wa Raheem Adedoyin ọhun, ko le wa sọ ohun to mọ nipa iku Timothy Adegoke.
Isẹlẹ yii ka ọpọ ọmọ Naijiria lara, ti wọn si fẹ mọ ibi ti igi ọrọ naa yoo wo si, eyi si lo mu ki ọga ọlọpaa ilẹ wa kede pe ki wọn maa ko gbogbo awọn afurasi nidi isẹlẹ naa wa si olu ileesẹ ọlọpaa ni Abuja.
Awọn afurasi naa si ti n jẹjọ niwaju ile ẹjọ giga ilu Abuja.





















