Timothy Adegoke: Ṣé lóòtọ́ ni àbájáde ìwádìí òkú 'autopsy' Timothy Adegoke tí wọ́n pa sílé ìtura Hilton hotel nílé Ife ti jáde?

Oríṣun àwòrán, others
Ṣe ẹ ko gbagbe ọrọ iku Timothy Adegoke, akẹkọọ gboye imọ kun imọ Masters degree ni ileẹ̀kọ́ giga fasiti OAU nilu ile ifẹ ti awọn apanijaye kan pa sile igbafẹ Hilton Hotel nilu Ile ifẹ?
Nigba ti BBC News Yoruba gbiyanju lati fi idi ọrọ yii mulẹ lọdọ awọn ọlọpaa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, ọga ọlọpaa Yẹmisi Ọpalọla ṣalaye pe awọn ko mọ ohunkohun nipa iwadii naa mọ.
- Ramon Adedoyin t'ọ́lọ́pàá mú nítorí ikú Timothy Adegoke gba ilé ẹjọ́ lọ, ohun tílé ẹjọ́ sọ rèé...
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tí wọ́n fẹ̀sùn ikú Demilade, ọmọ ọdún méje tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú 'cooler' lẹ́yìn tó dàwátì ní Ado-Ekiti
- Ìjọba ti iléèwé Ojodu pa, Ó ní àlàyé ohun tó ṣókùnkùn nípa ìjàmbà tírélà tó pa akẹ̀kọ̀ọ́ níbẹ̀ ńbọ̀ láipẹ̀
- Ikú Sylvester Oromoni: Wo kókó òfin ìpínlẹ̀ Eko mẹ́wàá tó tako ẹgbẹ́ òkùnkùn
Gẹgẹ bi ọrọ ti ẹgbọn oloogbe naa, Adegbade Adegoke sọ fun BBC News Yoruba, abajade ayẹwo oku naa ti wa lọdọ awọn ọlọpaa.
Amọsa, o ṣalaye pe wọn ko tii fun ẹbi oloogbe naa ni ẹda rẹ, tabi bun awọn gbọ lori bo ṣe lọ si.
Ṣé lóòtọ́ ni àbájáde ìwádìí òkú 'autopsy' Timothy Adegoke tí wọ́n pa sílé ìtura Hilton hotel nílé Ife ti jáde?
Iroyin ti a n gbọ bayii ni pe iwe ayẹwo oku 'Autopsy' ti awọn akọṣẹmṣẹ iṣegun oyinbo ṣe lori oku Timothy Adegoke ti jade, o si ti wa lọdọ awọn ọlọpaa.

Oríṣun àwòrán, omoluabitv
O ni nitori wọn ti gbe e lọ si ọdọ ikọ amuṣẹya ọga agba ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, awn lo si lee sọ ibi ti nnkan de duro lori rẹ.
O ti to ọjọ mẹta ti BBC Yoruba ti n jabọ lori iṣẹlẹ iku arakunrin Timothy Adegoke, ti wọn rí oku rẹ ninu igbo ni Ile Ife.
Akẹkoo OAU Ife ni Timothy, ile itura Hilton to de si ni wọn ti ri gbẹyin, ko to di pe wọn ba oku rẹ ninu igbo.
Orisirisi alaye lo ti gbòde kan lori bi o ti ṣe ku ṣugbọn ileesẹ ọlọpaa ni eyi tó lè jẹ atọna si isẹlẹ ni ki awọn mọ nkan ti ayẹwo oku, 'autopsy' ba gbe jade.
- Ẹ̀ wo bàbá àgbàlagbà tó lo ayédèrú apá nitorí kò fẹ́ gba abẹrẹ́ àjẹsára Covid-19
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
- A ṣetán láti bá Sanwo-Olu rìnrìn àlàáfíà, ẹ̀yin krìstẹ́nì, ẹ darapọ̀ mọ wa- MURIC
- Omicron: Kíni ìdí tí Nàìjíríà ṣe wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó léwu láti rírínàjò lágbàyé?
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun




















