Sylvester Oromoni death: Kókó mẹwàá nínú òfin ìpínlẹ̀ Eko lórí ẹgbẹ́ òkùnkùn rèé

Oríṣun àwòrán, @Lagos
Oriṣiiriṣii nkan l'awọn eeyan ti n sọ nipa bi ẹgbẹ okunkun ṣe n gbilẹ sii to fi de ile ẹkọ girama bayii, lẹyin iku akẹkọọ ile ẹkọ Dowen, Sylvester Oromoni niluu Eko.
Ọpọ lo ti kepe ijọba ipinlẹ Eko lati ṣe iwadii lori iku Oromoni lẹyin tawọn obi ọmọ naa sọ pe Sylvester darukọ awọn akẹkọọ kan wí pe awọn lo lu oun lalubami ki ẹlẹmi to gbaa.
Ẹwẹ, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti ṣe agbekalẹ ofin to tako ẹgbẹ okunkun loṣu keji ọdun 2021 eleyii ti Gomina Babajide Sanwo-Olu buwọ lu.
- Mẹ́ta lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College tí Sylvester dárúkọ ti wà ní àkàtà ọlọ́pàá - Kọmisanna ọlọpaa Eko
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ awakọ̀ tírélà tó gbá akẹ́kọ̀ọ́ mérìnlá nílùú Eko
- "Kí ló dé tó jẹ́ orúkọ ẹbí Kashamu nìkan lẹ mú bọnu nínú àwon ọmọ Marun ti Oromoni Jnr dárúkọ?"
- Àbùkù ńlá ni ikú Sylvester Oromoni jẹ́ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó- ìyàwó Gómìnà Sanwo-Olu
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
Wọnyi ni koko mẹwaa to wa ninu ofin to tako ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Eko:
1. Ẹwọn ọdun mọkanlelogun ni ijiya fun ẹnikẹni to ba jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun tabi ti a ba n pe eeyan lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Eko.
2. Ẹwọn ọdun mẹẹdogun ni ijiya fun ẹnikẹni ti o ba da ẹgbẹ okunkun silẹ tabi ẹni to ba gba ki wọn ṣe ipade ẹlẹgbẹ okunkun ni ile rẹ.
3. Ẹnikẹni to ba fẹ fi ipa mu eeyan wọ inu ẹgbẹ okunkun yoo fi ẹwọn ọdun mẹẹdogun tabi meedogbọn jura.
4. Ẹlẹgbẹ okunkun ni ẹnikẹni ti wọn ba ti wọn ba ri ami tabi akọsilẹ ẹgbẹ okunkun pẹlu rẹ.
5. Ẹwọn ọdun mẹẹdogun ni ijiya fun ẹlẹgbẹ okunkun ti wọn ba ka ibọn mọ lọwọ ti o si n gbiyanju lati fi ipa mu elomiran wọ inu ẹgbẹ okunkun.
6. Ẹwọn ọdun mọkanlelogun n duro de ẹlẹgbẹ okunkun to ba dana sun eeyan tabi dukia ẹnikẹni tabi da kẹmika asiidi si eeyan lara.
7. Ẹwọn ọdun mọkanlelogun ni ijiya fun ẹlẹgbẹ okunkun to ba bẹ ẹgbẹ rẹ lọwẹ lati gbẹsan tabi ṣe ijamba fun ẹnikẹni nipinlẹ Eko.
8. Akẹkọọ laṣẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ to ba forukọ silẹ pẹlu awọn alaṣẹ ile ẹkọ rẹ nikan.
9. Akẹkọọ to ba darapọ mọ ẹgbẹ kẹgbẹ to lodi sofin yoo fi ẹwọn ọdun meji jura.
10. Ẹnikẹni to ba ṣe iranwọ tabi daabo bo ẹlẹgbẹ okunkun yoo fi ẹwọn ọdun mẹẹdogun jura.

















