Sylvester Oromoni: Ìyàwó Gómìnà sọ èrò ọkàn rẹ̀ lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ omo ọdún méjìlá Sylvester Oromoni

Awon eeyan gbe patako alakọle dani

Oríṣun àwòrán, channels tv

Arabinrin Ibijoke Sanwo-Olu iyawo Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sapejuwe iku akẹkọọ ọmọ ọdun mejila nii Sylvester Oromoni gẹgẹ bi ohun to tabuku ijọba Eko.

Sylvester to jẹ akẹkọọ ni Dowen College to wa ni Lekki ni okiki kan latari iku rẹ lẹyin ti mọlẹbi rẹ sọ pe awọn akẹgbẹ rẹ to lu nitori pe ko fẹ dara pọ mọ ẹgbẹ okunkun lo sokunfa iku rẹ.

Lasiko to n se abẹwo sawọn ile ẹkọ kan nipinlẹ Eko ni iyawo Gomina fi ọrọ yi lede lara eto ipolongo lati tako ifiyajẹni to ni se pẹlu ifipabanilopọ tabi boya eeyan jẹ obinrin tabi ọkunrin.

Ninu atẹjade ti igbakeji ọga ẹka ipolongo ni ọfisi iyawo Gomina gbe jade lọrọ yi wa.

Gẹgẹ bo ti se wi, arabinrin Sanwo-Olu juwe ọrọ yi gẹgẹ bi eleyi to buru pupọ ti o si ni iru rẹ ko ni waye mọ nipinlẹ Eko.

O sọ pe, "Mo mọ pe ijọba Eko n sewadi lori ọrọ yi lọwọ nkan ti ko si dun mọ wa ninu ni lododo ati lotitọ.

Abuku nla leleyi jẹ lori ẹka eto ẹkọ,agbegbe tọrọ kan ati ipinlẹ Eko lapapọ''

O tẹsiwaju pe ''Wọn ti n se iwadi ọrọ yi ti mo si n ba awọn obi ati ẹni ti ọrọ naa kan kẹdun lori isẹlẹ yi''

Àkọlé fídíò, A kò tíì dẹ́kun àdúrà pé kí àṣírí àwọn tó jí ọmọ gbé tú - Bisola Alfa Sotitobire

Lọjọru ni iroyin gbode nipa iku Sylvester gbode nigba ti ibatan rẹ Perry Oromoni fẹsun kan awọn akẹgbẹ rẹ kan to ni wọn da bantẹ iya fun nitori pe ko fẹ bawọn se ẹgbẹ okunkun.

Amọ ile ẹkọ Sylvester sọ pe ko si nkan to jọ bẹ ti wọn si ni idi ere bọọlu ni Sylvester ti farapa to si fi ẹsẹ ati itan rẹ sese.

Lọjọ Ẹti ni ijọba ipinlẹ Eko kede pe ki wọn ti ile ẹkọ na pa titi ti iwadii yoo fi pari lori isẹlẹ naa.

Kọmisana ipinlẹ Eko arakunrin Hakeem Odumosu naa ti fi da mọlẹbi loju pe awọn yoo fi abajade iwadii awọn to ara ilu leti.