Sylvester Oromoni: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko ti kó àwọn ọlọ́pàá kògbéregbè lọ síléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ

Ọkọ ọlọpaa niwaju ileewe Dowen College

Oríṣun àwòrán, Rapid Response/ facebook

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti ko awọn ọkọ ọlọpaa si iwaju ileewe Dowen College to wa ni agbegbe Lekki ni ilu Eko nibiti iroyin ti gbee jade pe akẹkọọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Sylvester ti ko agbako awọn iṣẹlẹ to ran an lọ si ọrun ọsan gangan.

Atẹjade kan ti ikọ kogberegbe RRS ni ipinlẹ Eko fi sita, adari ikọ naa, CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi ṣalaye pe awọn ikọ ọlọpaa naa yoo wa nibẹ titi di igba ti kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ba gbe aṣẹ tuntun jade lori rẹ.

O ni wọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti ileeṣẹ eto ẹkọ ni ipinlẹ Eko gbe ileewe naa ti pa ti kọmiṣọna ọlọpaa si paṣẹ pe ki wọn gbe ikọ ọlọpaa ati ọkọ wọn si iwaju ileewe naa fun amojuto to peye.

Ìdí tí mo fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ mi lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tó dágbére fáyé rèé - Bàbá Sylvester Oromoni

Baba akẹkọọ Dowen College to ku ni ipinlẹ Eko lẹyin ti wọn ni awọn akẹgbẹ rẹ fiya jẹ lọna aitọ, Sylvester Oromoni, ti ṣalaye idi ti ẹbi naa ṣe ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọmọ naa lẹyin ọjọ diẹ to jade laye.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọro, okunrin naa ni oun ti kọkọ ṣeleri fun ọmọ naa pe oun yoo sami si ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ọhun ki iku to mu ẹmi rẹ lọ.

Sylvester Oromoni

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ibaṣepọ to wa laarin oun ati oloogbe naa u ti baba si ọmọ lọ to bẹẹ ti ọdọkunrin naa fi jẹ ọrẹ korikosun oun.

O ni "Ọjọ marun un sẹyin lo jade laye, ṣugbọn ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ti a ṣe yii waye nitori mo ti ṣleri fun un ṣaaju pe n oo ṣe ayẹyẹ ọjọ naa fun."

"Mo fẹ fi ayẹyẹ ọjọ ibi naa ṣe iranti rẹ, koda o ṣeeṣe ki n maa ṣe ayẹyẹ ọhun lọdọọdun."

"Ki ẹlẹmi to gba, ọrẹ korikosun mi ni, kii kan n ṣe ọmọ mi lasan... gbogbo igba lo maa n lẹ mọ mi kiri."

Ọgbẹni Oromoni wa pe fun idajọ ododo lori iku ọmọ rẹ, o tun dupọ lọwọ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa fun akitiyan wọn lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

O ni "Mo n pe fun idajọ ododo lori iku ọmọ mi, ohun ti mo fẹ niyẹn."

Àkọlé fídíò, A kò tíì dẹ́kun àdúrà pé kí àṣírí àwọn tó jí ọmọ gbé tú - Bisola Alfa Sotitobire

"Inu mi dun pe ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria duro ti ẹbi wa, awọn naa si n fẹ idajọ ododo lori ọrọ yii, adura mi ni pe ki Eledumare dabo bo gbogbo awọn to n duro ti wa."

Baba oloogbe naa sọ siwaju si pe lati inu oṣu Kọkanla ti iṣẹlẹ naa ti waye, awọn alaṣẹ ile ẹkọ Dowen College ko fi igba kankan pe aago oun titi ti ọmọ naaa fi dakẹ.

O ṣalaye pe ọga ile ẹkọ ọhun ko pe oun titi di igba ti oun ranṣẹ si wọn pe ọmọ oun ti jade laye.

Nipa bi awọn ẹbi rẹ ṣe n farada akoko idojuko yii, o ni wọn n gbiyanju, amọ iyawo oun ko kii le sun ayafi to ba kọkọ lo oogun orun.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀