Badagry: Báwo ni àwọn méje ṣe di òkú sínú ọ̀kọ̀ àyọkẹ́lẹ̀ kan ní Badagry

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Àwọn ọmọ mẹ́jọ kan ni ìròyìn sọ pé wọ́n kú sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ̀ tí wọ́n ti gbékalẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń ṣeré nínú rẹ̀.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Eko, Adekunle Ajisebutu ló fí ọ̀rọ̀ lédè pé wọ́n ti gbé òkú wọ́n lọ sí mọ́súárì ni ilé ìwòsàn gbogbo nìṣè to wà ní ìlú Badagry.
Bákan náà lo fi kun pé, ilé iṣk ọlọ́pàá yóò bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ṣe àyẹ̀wò nǹkan tó pa àwọn ọmọ náà.
- Ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Itunu Babalola kó tó di olóògbé tí wọ́n ń fi òkú rẹ̀ ránṣẹ́ sílé...
- Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí àwọn olólùfẹ́ yìí tí wọ́n bá okú wọn ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn
- Ọgọ́ta èèyàn tí àwọn jàndùkú jí gbé nínú ìjọ Baptist ní Kaduna ti gba ìtúsílẹ̀
- Awọn gbajumọ akọrin ati oṣere tiata obinrin Naijiria sọ nipa idẹyẹsi lọwọ awọn ọkunrin
Ó ní wọ́n ti mu ẹ̀sùn wá si àgọ́ ọlọ́pàá, àti pé, kọmisọ́nà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Eko Hakeem Odumosu ti pe fún ìwàdìí oní kíákía láti mọ nǹkan ti o sokùnfa ikú àwọn ọmọ ọ̀hún
Bákan náà ni kọmísọ̀nnà ọlọ́pàá bá ẹbi àwọn ọmọ to kú náà kẹ́dùn.
Kíní àwọn ará àdúgbò ń sọ?
Ẹ̀wẹ̀, yàtọ̀ sí àlàyé ti àwọn ọlọ́pàá fi síta lórí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ara àdúgbò níbi ti ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀ ṣàlàyé pé àwọn ọmọ mẹ́jọ náà ni wọ́n bá òkú wọn nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ̀ Lexus ni Agunaje ni ìlú Badagry ìpílẹ̀ Eko.
Àwọn ọmọ ọ̀hún ti ọjọ́ orí wọn ko ju ọdún mẹ́rin si mẹ́fà lọ ni wọ́n ni wọ́n wọ inu ọkọ̀ ti wọ́n si ti ara wọn pa mọ sinu mọ́tò náà ni ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ ttó kọjá.
Wọ́n ni ìgbàgbọ́ ni pé oorun lo mú àwọn ọmọ náà pa sínú ọks ọ̀hún.
Ìròyìn tún fi kun pé àwọn ọmọ ẹni to ni ọkọ̀ ti wọ́n gbé si ìwájú ilé ọ̀hún àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn ni wọ́n jọ wọ inu ọkọ láti ṣeré, sùgbọ́n ikú ló já sí fún gbogbo wọn.
Ẹni ti ó sọ̀rọ̀ náà fi kún pé, ó dàbi pé nǹkan ti wọ́n máa ń ṣe sí ọkọ̀ ti ọmọde ko fi le ṣi láti inú ló wà lára ọkọ̀ náà ti àwọn ọmọ ọ̀hún kò fi le ṣi láti inú ilé.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn mííràn nígbàgbọ́ pé, ọ̀rọ̀ míí wà nídí rẹ̀ ti kò ti sí ẹni ti ó yé.
















