Baba Suwe: December 23 ni àwọn òṣèré yóò ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Omidina

Awọn ẹbi ara ati ọrẹ ti ṣe ẹyẹ ikẹyin pẹlu adura ọjọ mẹjọ fun agbaọjẹ oṣere tiata nni, Babatunde Omidina ti gbogbo eeyan mọ si Baba Suwe.
Adura Fidau yi n waye lẹyin ti wọn ti sinku rẹ saaju lọsẹ to kọja ni agboole Baale, agbegbe Ewu Elepe nilu Ikorodu ipinlẹ Eko.
Ni nkan bii ago meji ọsan ni eto adura naa gbera sọ, ti awọn oṣere bi Bolaji Amusan to jẹ aarẹ ẹgbẹ TAMPAN ati awọn eeyan jankan jankan miran naa peju si lati yẹ Baba Suwe si.
- Ìrìn-àjò Baba Suwe pẹ̀lú àjọ NDLEA lórí bó ṣe ''yàgbẹ́ tì'' ní àtìmọ́lé
- Irọ́ ni pé TAMPAN àtàwọn òṣèré tíátà kò tọ́jú Baba Suwe lásìkò àìsàn, àwọn bẹbẹ ta ṣe rèé - Mr Latin
- Wo ọ̀nà táwọn olólúfẹ́ Baba Suwe ní London àti Manchester fẹ́ gbà ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fun
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Baba Suwe ti kú tipẹ́ ṣaájú kí gbogbo èèyàn tó mọ̀ - Àbúrò olóògbé
- "Èmi ní mo bí àkọ́bí fún Baba Suwe àmọ́ ọmọ mi kò bá bàbá rẹ̀ rìn púpọ̀ ko tó kú"
- Awuyewuye bẹ́ sílẹ̀ lórí ìlànà ìsìnkú Baba Suwe, àwọn Alfa yarí
- Ìdí rèé táa ṣe fi pósí gbe Baba Suwe tó jẹ́ Mùsùlúmì - Aya rẹ̀ àkọ́fẹ́ ṣàlàyé
- Ẹ wo ẹni tó ń jẹ́ Suwebatu nínú ẹbí Baba Suwe àti ohun tó sọ nípa olóògbé
Akọroyin BBC to peju sibi eto adura naa jabọ pe Alhaja Salawa Abẹni akọrin Waka ati Taiwo Hassan taa mọ si Ogogo naa wa nibi isinku yi, to fi mọ awọn osere tiata jankan miran.
Awọn alfa to joko adura yii fi asiko naa ṣe waasi isiti fawọn mọlẹbi Baba Suwe, pe ki wọn fi igbe aye to ṣe mu yangan ṣe iranti ẹni rere to lọ.

Ninu awọn to ba akọroyin wa sọrọ ni Adewale Elesho to jẹ ilumọọka adẹrinposonu salaye nipa ajọsepọ rẹ pẹlu Baba Suwe
O ni iku Baba Suwe fọwọ kan oun lẹmi nitori ọrẹ timọ timọ lawọn mejeeji, ajọsepọ tẹgbọn-taburo to di ọrẹ si ni awọn n se.
Elesho fikun pe ori ibusun kan soso ni awọn mejeeji maa n sun, ti isẹ ba pa awọn pọ, ti awọn si nifẹ ara awọn tọkan tọkan.
O ni bi Baba Suwe ko tilẹ jẹ ọmọ ẹgbẹ ANTP ti oun jẹ asaaju fun, to si jẹ pe inu ẹgbẹ TAMPAN lo wa, sibẹ, ọrẹ oun ni
Osere tiata naa, nigba to n dahun ibeere lori ọna ti wọn yoo gba sọ orukọ Baba Suwe di manigbagbe, o ni ẹgbẹ TAMPAN nikan lo le kede ohun ti wọn fẹ fi se niranti oloogbe naa.
Gbogbo ohun to ba wa ni ikapa mi ni maa fi gba ẹtọ Baba Suwe lọdọ NDLEA
Nigba to n sọrọ lori gbigba ẹtọ Baba Suwe lọdọ ajọ NDLEA, tii se milinu mẹẹdọgbọn naira ti ile ẹjọ ni ki ajọ NDLEA san fun oloogbe naa gẹgẹ bi owo gba ma binu, Elesho ni oun ṣetan lati darapọ pẹlu awọn to ba fẹ seto gbigba owo yii.
''Lootọ baba Suwe kii ṣe ọmọ ẹgbẹ ti awa wa ninu rẹ ṣugbọn bi awọn kan ba gbe eto kalẹ lati ba gba owo yii, mo ṣetan lati kun wọn lọwọ''
Bẹẹ ba gbagbe, Baba Suwe ti gba idajọ owo gba ma binu miliọnu marundinlọgbọn naira lọdọ ile ẹjọ giga ṣugbọn ajọ NDLEA sọ pe awọn ri idajọ gba nile ẹjọ kotẹmilọrun pe ki wọn ma san owo yii fun.
Amọ a ko le sọ pato boya Baba Suwe gba ile ẹjọ to gaju lọ lati gba ẹtọ rẹ yii ti awọn oṣere ẹgbẹ rẹ bi Yomi Fabiyi ba polongo.
Ẹyẹ ikẹyin yoo waye fun Baba Suwe ni 23 December 2021:
Ẹwẹ gbajumọ osere tiata mii, Remi Shitta Bay, toun naa ba BBC Yoruba sọrọ lasiko adura ọjọ kẹjọ naa kede pe ẹgbẹ awọn yoo ṣeto iranti fun Baba Suwe ki ọdun yii to pari.
O ni asa awọn oṣere ni lati ranti awọn to ba lọ laarin awọn ati pe ti Baba Suwe ko ni yatọ, ti awọn ko si fẹ ki ẹyẹ naa di ọdun to n bọ.
O wa kede pe ọjọ kẹtalelogun osu Kejila ọdun 2021 ni ẹyẹ ikẹyin ọhun yoo waye fun Baba Suwe ni Blue Room, to wa ni ikẹja.
Nibi ẹyẹ ikẹyin naa, to pe ni Artistes Nite, ni Shitta-Bay ti salaye pe wọn yoo ti se oniruuru ere Baba Suwe, ti awọn osere kan yoo si se bi oloogbe naa ti maa n se ninu ere nigba aye rẹ.
Agba osere naa fikun pe awọn ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo se kokari ẹyẹ ikẹyin naa fun Baba Suwe.
Lara awọn agbaagba osere ati Amuludun to peju sibi eto adura ọjọ Kẹjọ naa ni Taiwo Hassan Ogogo, Alhaja Salawa Abeni, Bolaji Amusan Mr Latin, Adewale Elesho ati Remi Shitta-Bay.





















