Baba Suwe: Àkọ́bí Omidina ní òun fẹ́ràn láti máa ń wo bàbá òun lórí Tẹlifísàn ni kékeré láì mọ̀ pé bàbá òun ni

Omobowale, Adenike ati Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Obinrin miran tun ti jade pe oun ni oun bi akọbi ọmọ fun Baba Suwe, ti ọmọ oun si jẹ akọbi ọkunrin.

Orukọ obinrin naa ni Adenike Muibat Omidina, ti o si ni orukọ akọbi ọmọ Baba Suwe ti oun bi fun ni Omobowale.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lọjọ isinku Baba Suwe, Adenike ni ọmọ oun ko ti ba baba rẹ rin pupọ ko to di pe o jade laye.

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

Amọ o ni ọmọ oun nifẹ lati maa wo iran baba rẹ lori tẹlifisan amọ o dun awọn pe asiko ti ọmọ oun ko ba gbadun Baba Suwe bi baba rẹ, ni adẹrinposonu naa dagbere faye.

"O dun mi pupọ pe Baba Suwe ku ni akoko yii mo si wa n gba awọn ọmọ rẹ nimọran pe ki wọn se ara wọn ni ọkan nitori baba kan soso lo bi wọn.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Aya àkọ́fẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí àkókó ìkẹyìn ọkọ́ rẹ̀ ṣe rí

Wọn ko gbọdọ gba esu laaye ninu irinajo aye wọn, ki wọn le gbe orukọ baba wọn ga siwaju si nibi to se isẹ rere de."

Adenike Omidina wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ Baba Suwe si afẹfẹ rere, ko si ma se iku rẹ ni akufa laarin ẹbi.

Mo fẹran lati maa wo Baba Suwe lori tẹlifisan lai mọ pe baba mi ni:

Nigba toun naa n sọrọ nipa baba rẹ, akọbi Baba Suwe Akanbi Sherriff Omobowale Omidina ni oun kan maa n wo Baba Suwe lori mohunmaworan ni lai mọ pe baba oun ni.

O ni oun nifẹ rẹ pupọ, amọ igbakuugba ti oun ba n wo ere Baba Suwe ni iya oun yoo ni ki oun gbe oju opo naa kuro loju mahunmaworan lọ si ibomiran.

O fikun pe nigba ti oun tun lọ si oke okun, oun tun gbọ okiki Baba Suwe sugbọn isẹ ko jẹ ki oun ni akoko lati maa wo, bi oun se maa n wo tẹlẹ.

"Isẹ agbẹmila ati olutọju alaisan ni mo n se, ti wọn ba ti gbe alaisan wa, n ki ni anfaani lati le wo Baba Suwe bo se yẹ.

Amọ mo ri baba mi ko to ku. Mo wa si Naijiria bii ẹẹmẹta amọ mo ri wọn bii ẹẹmeji.

Inu mi dun pe mo se nnkan fun wọn, ki wọn to ku, tori ẹmi yẹn kan sọ si mi lọkan pe ki n ra nnkan ijoko fun wọn.

Ẹni to ba ra nnkan ijoko fun eeyan, ti fun onitọun ni isinmi, bi mo ba tiẹ ni wahala pẹlu wọn tẹlẹ, nnkan ti mo se yẹn gan yoo jẹ ki inu wọn yọ.

Inu mi si dun pe mo bu yeepẹ si wọn lori, ti ki si se ẹyin ti wọn ku tan ni mo mọ wọn."

Akọbi Baba Suwe wa rọ awọn ẹbi lati mase se ounkohun ti yoo ba ẹyin baba oun jẹ, ki gbogbo ọmọ si se ohun to yẹ lati gbe orukọ rẹ ga si lẹyin iku rẹ.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Bi eto isinku Babatunde Omidina se lọ ree