Àwọn òṣèré tíátà Yoruba sọ̀rọ̀ nípa Baba Suwe tó di olóògbé

Àkọlé fídíò, Gbọ́ ohun ti àwọn òṣèré tíátà Yoruba sọ fún BBVC nípa Baba Suwe

Awọn oṣere tiata Yoruba ti sọrọ nipa iha ti wọn kọ si agba oṣere to di oloogbe, Baba Suwe.

Lara awọn oṣere naa to baba BBC Yoruba sọrọ sọ pe iku oloogbe ọhun dun awọn denu, wọn si sọrọ nipa ohun ti awọn ko le gbagbe nipa rẹ.

Bolaji Amusan, ti ọpọ mọ si Mr Latin sọ pe bii ẹgbọn ni Baba Suwe jẹ si oun.

O fi kun pe oloogbe naa tun jẹ ẹni to maa n ko awọn eeyan mọra to si tun maa n ṣe awada pupọ.

Arabinrin Fausat Balogun ṣalaye fun BBC Yoruba pe Baba Suwe lo fun oun lorukọ “Madam Saje” ti ọpọ awọn ololufẹ ere tiata Yoruba mọ oun si lonii.

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ti ni orukọ ṣaaju ki wọn to pade, ṣugbọn oloogbe naa lo jẹ ki oun maa jẹ orukọ naa bẹrẹ lati inu ere “Ẹrin Keke” ti wọn jọjọ ṣe lọdun 1996.

Ni ti Olaniyi Afonja ti ọpọ mọ si Sanyeri, o ni Baba Suwe ki n ṣe ẹni to maa n ta eeyan nu, o si tun maa n ko awọn eeyan mọra.

Yatọ si awọn eeyan wọnyii, Dejo Tunfulu, Kamilu Konpo atawọn oṣere mii naa tun sọrọ nipa irufẹ ẹni ti Baba Suwe jẹ si awọn.

Wo fidio yii fun ékunrẹrẹ.