Baba Suwe: Babatunde Thompson sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó wé ikú Moladun mọ́ Babatunde Omidina lọrun

Baba Suwe ati Moladun

Oríṣun àwòrán, Baba Suwe and Moladun

Gbajumọ osere tiata kan, Babatunde Thompson, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Thompson ti salaye nipa awọn isẹlẹ to sẹlẹ si gbajumọ alawada nni, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe.

Thompson, lasiko to n sọrọ nipa Baba Suwe nibi eto isinku rẹ l'Ọjọbọ kepe pe, aburo Baba Suwe ni oun, ẹbi kan soso ni awọn.

Nigba to n kede iru itọju nla ti Baba Suwe ri gba lasiko to n saisan, osere tiata naa ni awọn ri owo tọju oloogbe naa, amọ o kan wu Ọlọrun lo mu lọ.

"Aarẹ ọtọ, owo ọtọ, ta ba ni owo lo yẹ ko gbe alaarẹ dide ni, kii se owo ni Baba Suwe ko ri na.

Ọmọ rẹ, Junior to si sọrọ pe baba oun ku, oun ko ri ẹbi tabi ara gan ti tọrọ aforijin nipa ohun to sọ.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Aya àkọ́fẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí àkókó ìkẹyìn ọkọ́ rẹ̀ ṣe rí

Ẹ jẹ ki a gba pe Ọlọrun lo pe Baba Suwe sọdọ, asiko ti ti to fun un lati ku ni.

Aisan yẹn kan duro lai san, to si daju pe o wa lati wa mu ẹmi Baba Suwe lọ ni."

Baba Suwe gan ti ku sara tori iku Moladun:

Nigba to n sọrọ lori ahesọ ọrọ kan to ni Baba Suwe lo pa iyawo rẹ, toun naa jẹ osere tiata eyiun Moladun, Johnson ni kii se ẹgbọn oun lo pa Moladun rara.

Ti a ba wa ri ahesọ ọrọ tawọn kan le maa sọ nipa iku Baba Suwe, bi o ṣe wu Ọlọrun niyẹn, a o ri nkan kan ṣe si.

Iku Baba Suwe dun ẹbi gan an nitori ogo ẹbi Omidina ni Baba Suwe jẹ, gẹgẹ bi emi naa.

Ọkunrin kan to n jẹ Ẹgbẹji sọ ahesọ ọrọ pe Baba Suwe lo pa Omoladun ati pe oun naa yoo ku ti ko ba jẹwọ.

Ọkunrin naa kan n wa ọna lati polowo ọja rẹ, tii ṣe egbo igi lasan ni tori Baba Suwe ti ku sara tan ni gbogbo igba yẹn.

Nitori kii ṣe igba ti gbogbo eeyan pe Baba Suwe ku gan an ni o ku, Baba Suwe ti ku sara tipẹ tipẹ nitori iku Moladun

Igba wo ni ẹni to n sọ pe Baba Suwe yoo ku ko, ni pada ku, lẹyin to ti ku sara tẹlẹ."

Babatunde Thompson

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Bakan naa ni Thompson yan pe gbogbo ajo to yẹ ki wọn ṣe ni wọn ṣe lati tọju oloogbe naa, gbogbo ere to yẹ ki wọn sa ni wọn sa, amọ, aisan ti ko gboogun, Ọlọrun Ọba ko ni fi kan wa.

O wa yan pe ahesọ ọrọ pe Baba Suwe lo pa lagbaja, oun lo pa tamẹdo, ko si ọrọ kankan nibẹ rara.

O ni Baba Ẹgbẹji kan n polowo ọja rẹ ni, to si n beere pe nigba ti Egbeji n sọ nipa ẹni to maa ku, ki lo de ti ko le sọ nipa ẹni to maa ni laari?

Bakan naa lo salaye pe Egbeji ko riran lati sọ nipa ẹni to maa lowo lọwọ, o tun sọ pe Iyabo Ojo naa maa ku.

"Ọmọ ọlọmọ ko le ku o, iku bii ti bawo, oriṣiiriṣii ni a n gbọ, eleyii to gbe tiẹ sori ayelujara niyẹn.

Aimọye eeyan to n sọ ti wọn, ti wọn o gbe sori ayelujara, ko si ohun to jọ ohun tawọn eeyan n sọ o."

Babatunde Thompson wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe awọn ẹbi ati ara tọju Baba Suwe, wọn duro ti Baba Suwe ṣugbọn iku lagbara ju ẹda lọ,aisan si lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se.

Àkọlé fídíò, Baba Suwe: Bi eto isinku Babatunde Omidina se lọ ree